Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hébérù 10:1-39

10  Nítorí níwọ̀n bí Òfin ti ní òjìji+ àwọn ohun rere tí ń bọ̀, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe kókó inú àwọn ohun náà gan-an, àwọn ènìyàn kò lè fi àwọn ẹbọ kan náà tí wọ́n ń rú nígbà gbogbo láti ọdún dé ọdún sọ àwọn tí ń wá di pípé.+  Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a kì yóò ha ti dẹ́kun rírú àwọn ẹbọ náà, nítorí àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ tí a ti wẹ̀ mọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún wọn wẹ̀ mọ́ láé, kì yóò ní ìmọ̀lára ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́?+  Ní òdì-kejì sí èyí, nípasẹ̀ ẹbọ wọ̀nyí, ìránnilétí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wà láti ọdún dé ọdún,+  nítorí kò ṣeé ṣe fún ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ láti mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.+  Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó wá sí ayé, ó wí pé: “‘Ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,+ ṣùgbọ́n ìwọ ti pèsè ara kan fún mi.+  Ìwọ kò tẹ́wọ́ gba àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.’+  Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Wò ó! Mo dé (nínú àkájọ ìwé ni a ti kọ ọ́ nípa mi)+ láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’”+  Lẹ́yìn kíkọ́kọ́ sọ pé: “Ìwọ kò fẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tẹ́wọ́ gba àwọn ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ àti àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀”+—àwọn ẹbọ tí a ń rú ní ìbámu pẹ̀lú Òfin+  nígbà náà ni ó sọ ní ti gidi pé: “Wò ó! Mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.”+ Ó fi òpin sí èyí tí ó jẹ́ ti àkọ́kọ́ kí ó lè fìdí èyí tí ó jẹ́ èkejì múlẹ̀.+ 10  Nípasẹ̀ “ìfẹ́”+ tí a sọ náà, a ti sọ wá di mímọ́+ nípasẹ̀ ìfirúbọ+ ara Jésù Kristi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo+ láìtún tún un ṣe mọ́ láé. 11  Pẹ̀lúpẹ̀lù, olúkúlùkù àlùfáà a máa mú ìdúró rẹ̀+ láti ọjọ́ dé ọjọ́+ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn àti láti rú àwọn ẹbọ kan náà lọ́pọ̀ ìgbà, níwọ̀n bí ìwọ̀nyí kò ti lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá+ ní àkókò kankan. 12  Ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí rú ẹbọ kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ títí lọ fáàbàdà,+ ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ 13  láti ìgbà náà lọ, ó ń dúró títí a ó fi fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 14  Nítorí nípa ọrẹ ẹbọ ìrúbọ+ kan ṣoṣo ni òun fi sọ àwọn tí a ń sọ di mímọ́ di pípé+ títí lọ fáàbàdà. 15  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀mí mímọ́+ pẹ̀lú ń jẹ́rìí fún wa, nítorí lẹ́yìn tí ó ti wí pé: 16  “‘Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò fi bá wọn dá májẹ̀mú lẹ́yìn ọjọ́ wọnnì,’ ni Jèhófà wí. ‘Ṣe ni èmi yóò fi àwọn òfin mi sínú ọkàn-àyà wọn, inú èrò inú wọn sì ni èmi yóò kọ wọ́n sí,’”+ 17  ó sọ lẹ́yìn ìgbà náà pé: “Lọ́nàkọnà, èmi kì yóò rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àwọn ìṣe àìlófin wọn mọ́.”+ 18  Wàyí o, níbi tí ìdáríjì+ ìwọ̀nyí bá wà, kò tún sí ọrẹ ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.+ 19  Nítorí náà, ẹ̀yin ará, níwọ̀n bí a ti ní àìṣojo fún ọ̀nà ìwọlé+ sínú ibi mímọ́+ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù, 20  èyí tí ó ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tuntun àti ọ̀nà ààyè la aṣọ ìkélé+ kọjá, èyíinì ni, ẹran ara rẹ̀,+ 21  àti níwọ̀n bí a ti ní àlùfáà ńlá lórí ilé Ọlọ́run,+ 22  ẹ jẹ́ kí a wá pẹ̀lú ọkàn-àyà tòótọ́ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ti ìgbàgbọ́, níwọ̀n bí a ti wẹ ọkàn-àyà wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí-ọkàn+ burúkú, tí a sì ti fi omi+ tí ó mọ́ wẹ ara wa. 23  Ẹ jẹ́ kí a di ìpolongo ìrètí+ wa ní gbangba mú ṣinṣin láìmikàn,+ nítorí olùṣòtítọ́+ ni ẹni tí ó ṣèlérí. 24  Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè+ sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà,+ 25  kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀,+ bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí+ lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.+ 26  Nítorí bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà+ lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà,+ kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́,+ 27  bí kò ṣe ìfojúsọ́nà fún ìdájọ́+ akúnfẹ́rù, owú amú-bí-iná sì wà tí yóò jó àwọn tí ń ṣàtakò run.+ 28  Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ṣàìka òfin Mósè sí ń kú láìsí ìyọ́nú, lórí gbólóhùn ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta.+ 29  Irú ìyà tí ó múná púpọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ wo,+ ni ẹ̀yin rò, pé a ó ka ẹni náà yẹ fún, ẹni tí ó ti tẹ Ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀,+ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú+ tí a fi sọ ọ́ di mímọ́ sí ohun yẹpẹrẹ, ẹni tí ó sì ti fi ìfojú-tín-ín-rín mú ẹ̀mí+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí bínú? 30  Nítorí a mọ ẹni tí ó wí pé: “Tèmi ni ẹ̀san; èmi yóò san èrè iṣẹ́”;+ àti pẹ̀lú: “Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.”+ 31  Ó jẹ́ ohun akúnfẹ́rù láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.+ 32  Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ máa bá a nìṣó ní rírántí àwọn ọjọ́ àtijọ́ nínú èyí tí, lẹ́yìn tí a ti là yín lóye,+ ẹ fara da ìdíje ńláǹlà lábẹ́ àwọn ìjìyà,+ 33  nígbà mìíràn bí a ti ń gbé yín síta bí ẹni pé nínú gbọ̀ngàn ìwòran+ fún ẹ̀gàn àti ìpọ́njú, àti nígbà mìíràn bí ẹ ti di alájọpín pẹ̀lú àwọn tí ń ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀.+ 34  Nítorí ẹ fi ìbánikẹ́dùn hàn fún àwọn tí ń bẹ nínú ẹ̀wọ̀n, ẹ sì fi ìdùnnú gba pípiyẹ́+ àwọn nǹkan ìní yín, ní mímọ̀ pé ẹ̀yin fúnra yín ní ohun ìní dídárajù àti èyí tí ó wà lọ títí.+ 35  Nítorí náà, ẹ má ṣe gbé òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ+ yín sọnù, èyí tí ó ní ẹ̀san+ ńláǹlà tí a ó san fún un. 36  Nítorí ẹ nílò ìfaradà,+ kí ó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run+ tán, kí ẹ lè rí ìmúṣẹ ìlérí+ náà gbà. 37  Nítorí ní “ìgbà díẹ̀ kíún”+ sí i, àti pé “ẹni tí ń bọ̀ yóò dé, kì yóò sì pẹ́.”+ 38  “Ṣùgbọ́n olódodo mi yóò yè nítorí ìgbàgbọ́,”+ àti pé, “bí ó bá fà sẹ́yìn, ọkàn mi kò ní ìdùnnú nínú rẹ̀.”+ 39  Wàyí o, àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun,+ ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé