Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hébérù 1:1-14

1  Ọlọ́run, ẹni tí ó tipasẹ̀ àwọn wòlíì+ bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn lọ́pọ̀ ìgbà+ àti lọ́pọ̀ ọ̀nà,  ti tipasẹ̀ Ọmọ+ kan bá wa sọ̀rọ̀ ní òpin ọjọ́ wọ̀nyí,+ ẹni tí òun yàn ṣe ajogún ohun gbogbo,+ àti nípasẹ̀ ẹni tí òun dá+ àwọn ètò àwọn nǹkan.  Òun ni àgbéyọ ògo+ rẹ̀ àti àwòrán náà gẹ́lẹ́ ti wíwà rẹ̀ gan-an,+ ó sì gbé ohun gbogbo ró nípa ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀;+ lẹ́yìn tí ó sì ti ṣe ìwẹ̀mọ́gaara fún ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún+ Ọba Ọlọ́lá ní àwọn ibi gíga fíofío.+  Nítorí náà, ó ti di ẹni tí ó sàn ju àwọn áńgẹ́lì+ lọ, débi pé ó ti jogún orúkọ+ tí ó ta tiwọn yọ.  Fún àpẹẹrẹ, èwo nínú àwọn áńgẹ́lì ni òun tíì sọ fún pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; òní ni èmi, àní èmi, di baba rẹ”?+ Àti pẹ̀lú: “Èmi fúnra mi yóò di baba rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì di ọmọ mi”?+  Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tún mú Àkọ́bí+ rẹ̀ wá sí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, ó wí pé: “Kí gbogbo áńgẹ́lì+ Ọlọ́run sì wárí fún un.”+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó sọ nípa àwọn áńgẹ́lì pé: “Ó sì ṣe àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mí, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ènìyàn ní ọwọ́ iná.”+  Ṣùgbọ́n nípa Ọmọ, ó wí pé: “Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ títí láé àti láéláé,+ ọ̀pá aládé ìjọba+ rẹ sì jẹ́ ọ̀pá aládé ìdúróṣánṣán.+  Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà àìlófin. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró+ ayọ̀ ńláǹlà yàn ọ́ ju àwọn alájọṣe rẹ.”+ 10  Àti: “Ìwọ, Olúwa, ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ti fi àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.+ 11  Àwọn fúnra wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ yóò máa wà títí lọ; àti gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù àwọ̀lékè,+ gbogbo wọn yóò gbó, 12  ìwọ yóò sì ká wọn jọ gẹ́gẹ́ bí aṣọ ìlékè,+ bí ẹ̀wù àwọ̀lékè; a ó sì pààrọ̀ wọn, ṣùgbọ́n bákan náà ni ìwọ wà, àwọn ọdún rẹ kì yóò sì pin láé.”+ 13  Ṣùgbọ́n èwo nínú àwọn áńgẹ́lì ni òun sọ nípa rẹ̀ rí pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ”?+ 14  Gbogbo wọn kì í ha ṣe ẹ̀mí+ fún iṣẹ́ ìsìn gbogbo ènìyàn,+ tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún+ ìgbàlà?

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé