Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hágáì 2:1-23

2  Ní oṣù keje,+ ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà wá nípasẹ̀ Hágáì+ wòlíì, pé:  “Jọ̀wọ́, sọ fún Serubábélì+ ọmọkùnrin Ṣéálítíẹ́lì,+ gómìnà Júdà,+ àti fún Jóṣúà+ ọmọkùnrin Jèhósádákì,+ àlùfáà àgbà, àti fún àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ènìyàn náà, pé,  ‘Ta ni ó ṣẹ́ kù láàárín yín tí ó rí ilé yìí nínú ògo rẹ̀ àtijọ́?+ Báwo sì ni ẹ ti rí i sí nísinsìnyí? Kò ha dà bí asán ní ojú yín ní ìfiwéra pẹ̀lú ìyẹn bí?’+  “‘Ṣùgbọ́n nísinsìnyí jẹ́ alágbára, ìwọ Serubábélì,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘sì jẹ́ alágbára,+ ìwọ Jóṣúà ọmọkùnrin Jèhósádákì, àlùfáà àgbà.’ “‘Kí ẹ sì jẹ́ alágbára, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́.’+ “‘Nítorí mo wà pẹ̀lú yín,’+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.  ‘Ẹ rántí ohun tí mo bá yín dá ní májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde wá láti Íjíbítì,+ nígbà tí ẹ̀mí+ mi sì dúró sáàárín yín. Ẹ má fòyà.’”+  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Lẹ́ẹ̀kan sí i—láìpẹ́+—èmi yóò sì mi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ jìgìjìgì.’+  “‘Dájúdájú, èmi yóò sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá;+ èmi yóò sì fi ògo+ kún ilé yìí,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.  “‘Tèmi ni fàdákà, tèmi+ sì ni wúrà,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.  “‘Ògo ilé ìkẹyìn yìí yóò pọ̀ ju ti àtijọ́,’+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí. “‘Èmi yóò sì fúnni ní àlàáfíà+ ní ibí yìí,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” 10  Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn-án, ní ọdún kejì Dáríúsì, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Hágáì+ wòlíì wá, pé: 11  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Jọ̀wọ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà nípa òfin,+ pé: 12  “Bí ènìyàn bá fi etí gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ̀ gbé ẹran mímọ́, ní ti tòótọ́, tí ó sì fi etí gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ̀ kan búrẹ́dì tàbí ọbẹ̀ tàbí wáìnì tàbí òróró tàbí irú oúnjẹ èyíkéyìí, yóò ha di mímọ́ bí?”’”+ Àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́!” 13  Hágáì sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Bí ẹnì kan tí ó di aláìmọ́ nípasẹ̀ ọkàn tí ó ti di olóògbé bá fọwọ́ kan èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí, yóò ha di àìmọ́ bí?”+ Ẹ̀wẹ̀, àwọn àlùfáà dáhùn, wọ́n sì wí pé: “Yóò di àìmọ́.” 14  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Hágáì dáhùn, ó sì wí pé: “‘Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn yìí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n rí, àti ohun yòówù tí wọ́n bá mú wá síbẹ̀. Ó jẹ́ aláìmọ́.’+ 15  “‘Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ọkàn-àyà+ yín sí èyí láti òní lọ, kí a tó fi òkúta sórí òkúta nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà,+ 16  láti ìgbà tí nǹkan wọnnì ti ṣẹlẹ̀—ẹnì kan wá síbi òkìtì ogún òṣùwọ̀n, ó sì jẹ́ mẹ́wàá; ẹnì kan wá síbi ẹkù ìfúntí láti fa àádọ́ta òṣùwọ̀n nínú ọpọ́n wáìnì, ó sì jẹ́ ogún;+ 17  mo fi ìjógbẹ+ àti èbíbu+ àti yìnyín+ kọlù yín, àní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín,+ kò sì sí ẹnì kankan lára yín tí ó yí padà sọ́dọ̀ mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà— 18  “‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ọkàn-àyà+ yín sí èyí láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn-án, láti ọjọ́ tí a ti fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀;+ ẹ fi ọkàn-àyà yín sí èyí: 19  Ṣé irúgbìn ṣì wà nínú kòtò ọkà?+ Àti pé síbẹ̀, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi pómégíránétì àti igi ólífì—kò tíì so, àbí ó ti so? Láti òní lọ, èmi yóò máa súre.’”+ 20  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì tọ Hágáì+ wá nígbà kejì ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù+ náà, pé: 21  “Sọ fún Serubábélì gómìnà Júdà+ pé, ‘Èmi yóò mi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé jìgìjìgì.+ 22  Dájúdájú, èmi yóò sì bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, èmi yóò sì pa okun ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè rẹ́ ráúráú;+ èmi yóò sì bi kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn tí ó gùn ún ṣubú, àwọn ẹṣin àti àwọn tí ó gùn wọ́n yóò sì wá sílẹ̀+ dájúdájú, olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.’”+ 23  “‘Ní ọjọ́ yẹn,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘Èmi yóò mú ọ, ìwọ Serubábélì+ ọmọkùnrin Ṣéálítíẹ́lì,+ ìránṣẹ́ mi,’ ni àsọjáde Jèhófà; ‘dájúdájú, èmi yóò sì gbé ọ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òrùka èdìdì,+ nítorí pé ìwọ ni mo yàn,’+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé