Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Hágáì 1:1-15

1  Ní ọdún kejì Dáríúsì Ọba,+ ní oṣù kẹfà, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà wá nípasẹ̀ Hágáì+ wòlíì sọ́dọ̀ Serubábélì+ ọmọkùnrin Ṣéálítíẹ́lì,+ gómìnà Júdà,+ àti sọ́dọ̀ Jóṣúà+ ọmọkùnrin Jèhósádákì,+ àlùfáà àgbà, pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ wí, ‘Ní ti àwọn ènìyàn yìí, wọ́n sọ pé: “Àkókò kò tíì tó, àkókò tí a óò kọ́ ilé Jèhófà.”’”+  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti wá nípasẹ̀ Hágáì wòlíì, pé:  “Àkókò ha nìyí fún ẹ̀yin láti máa gbé nínú àwọn ilé+ yín tí a fi igi pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí, nígbà tí ilé yìí wà ní ipò ahoro?+  Wàyí o, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí àwọn ọ̀nà yín.+  Ẹ ti fún irúgbìn púpọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni ẹ ń mú wọlé.+ Ẹ ń jẹun, ṣùgbọ́n kì í ṣe ní àjẹyó.+ Ẹ ń mutí, ṣùgbọ́n kì í ṣe dórí mímu àmuyó. Ẹ ń wọṣọ, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí ó móoru; ẹni tí ó sì ń fi ara rẹ̀ háyà ń fi ara rẹ̀ háyà fún àpò tí ó ní àwọn ihò.’”+  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí àwọn ọ̀nà yín.’+  “‘Ẹ gun orí òkè ńlá lọ, kí ẹ sì gbé igi gẹdú+ wá. Kí ẹ sì kọ́ ilé+ náà, kí n lè ní ìdùnnú nínú rẹ̀,+ kí a sì lè yìn mí lógo,’+ ni Jèhófà wí.”  “‘Ẹ ń wá ọ̀pọ̀ kiri, ṣùgbọ́n kíyè sí i, kìkì díẹ̀+ ni ó wà; ẹ sì ti mú un wá sínú ilé, mo sì fẹ́ atẹ́gùn sí i+—fún ìdí wo?’+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. ‘Nítorí ilé mi tí ó wà ní ipò ahoro, nígbà tí ẹ ń sá kiri, olúkúlùkù nítorí ilé tirẹ̀.+ 10  Nítorí náà, ọ̀run fawọ́ ìrì wọn sẹ́yìn kúrò lórí yín, ilẹ̀ ayé sì fawọ́ èso rẹ̀ sẹ́yìn.+ 11  Mo sì ń pe ọ̀dá wá sórí ilẹ̀ ayé, àti sórí àwọn òkè ńlá, àti sórí ọkà, àti sórí wáìnì tuntun,+ àti sórí òróró, àti sórí ohun tí ilẹ̀ bá mú jáde, àti sórí ará ayé, àti sórí ẹran agbéléjẹ̀, àti sórí gbogbo làálàá tí ọwọ́ ń ṣe.’”+ 12  Serubábélì+ ọmọkùnrin Ṣéálítíẹ́lì, àti Jóṣúà ọmọkùnrin Jèhósádákì,+ àlùfáà àgbà, àti gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run+ wọn, àti sí àwọn ọ̀rọ̀ Hágáì+ wòlíì, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run wọn ti rán an; àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù nítorí Jèhófà.+ 13  Hágáì ońṣẹ́+ Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn ní ìbámú pẹ̀lú iṣẹ́ tí a rán ońṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ pé: “‘Èmi wà pẹ̀lú yín,’+ ni àsọjáde Jèhófà.” 14  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti ru ẹ̀mí+ Serubábélì ọmọkùnrin Ṣéálítíẹ́lì, gómìnà Júdà sókè, àti ẹ̀mí Jóṣúà+ ọmọkùnrin Jèhósádákì, àlùfáà àgbà, àti ẹ̀mí gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ènìyàn náà; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wọlé, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ilé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run+ wọn. 15  Èyí jẹ́ ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì Dáríúsì+ Ọba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé