Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Hábákúkù 3:1-19

3  Àdúrà tí Hábákúkù wòlíì fi orin arò gbà:  Jèhófà, mo ti gbọ́ ìròyìn nípa rẹ.+ Jèhófà, mo ti fòyà ìgbòkègbodò+ rẹ. Ní àárín àwọn ọdún, mú un wá sì ìyè! Ní àárín àwọn ọdún, kí o sọ ọ́ di mímọ̀. Nígbà ṣìbáṣìbo, kí o rántí+ láti fi àánú hàn.  Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń bọ̀ láti Témánì, àní Ẹni Mímọ́ láti Òkè Ńlá Páránì.+ Sélà.+ Iyì rẹ̀ bo ọ̀run;+ ilẹ̀ ayé sì kún+ fún ìyìn rẹ̀.  Ní ti ìtànyòò rẹ̀, ó wá dà bí ìmọ́lẹ̀.+ Ó ní ìtànṣán méjì tí ń jáde láti ọwọ́ rẹ̀, ibẹ̀ sì ni ibi ìpamọ́ okun rẹ̀ wà.+  Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀,+ ibà amáragbóná fòfò a sì máa jáde lọ ní ẹsẹ̀+ rẹ̀.  Ó dúró jẹ́ẹ́, kí ó bàa lè gbọn ilẹ̀ ayé+ jìgìjìgì. Ó wò, ó sì wá mú kí àwọn orílẹ̀-èdè fò sókè.+ Àwọn òkè ńlá ayérayé sì wá fọ́ túútúú;+ àwọn òkè kéékèèké tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tẹrí ba.+ Àwọn ìrìn àtọjọ́mọ́jọ́ jẹ́ tirẹ̀.  Mo rí àwọn àgọ́ Kúṣánì lábẹ́ ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́. Ṣìbáṣìbo+ sì bẹ̀rẹ̀ sí bá aṣọ àgọ́ ilẹ̀ Mídíánì.+  Ṣé àwọn odò ni, Jèhófà, ṣé àwọn odò ni ìbínú rẹ wá gbóná+ sí, tàbí òkun+ ha ni ìbínú kíkan rẹ wà lòdì sí? Nítorí tí ìwọ gun àwọn ẹṣin+ rẹ; àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ jẹ́ ìgbàlà.+  Ọrun rẹ di títú síta ní ìhòòhò+ rẹ̀. Ìbúra tí àwọn ẹ̀yà ṣe ni ohun tí a wí.+ Sélà. O tẹ̀ síwájú láti fi àwọn odò pín ilẹ̀ ayé+ níyà. 10  Àwọn òkè ńlá rí ọ; wọ́n wá wà nínú ìrora+ mímúná. Ìjì ààrá ti omi kọjá lọ. Ibú omi mú ìró+ rẹ̀ jáde. Ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ibi gíga lókè. 11  Oòrùn—òṣùpá—dúró jẹ́ẹ́,+ ní ibùjókòó gíga fíofío lọ́hùn-ún.+ Bí ìmọ́lẹ̀ ni àwọn ọfà rẹ ń lọ ṣáá.+ Mànàmáná ọ̀kọ̀ rẹ ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìtànyòò.+ 12  Ìdálẹ́bi ni o fi la ilẹ̀ ayé kọjá. Tìbínú-tìbínú ni o fi pa àwọn orílẹ̀-èdè bí ọkà.+ 13  O sì jáde lọ fún ìgbàlà àwọn ènìyàn+ rẹ, láti gba ẹni àmì òróró rẹ là. O fọ́ olórí sí wẹ́wẹ́ kúrò ní ilé ẹni burúkú.+ A tú ìpìlẹ̀ sí borokoto, títí dé ọrùn.+ Sélà. 14  O fi àwọn ọ̀pá tirẹ̀ gún+ orí àwọn jagunjagun rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbéra bí ìjì líle láti tú mi ká.+ Ayọ̀ pọ̀rọ́ wọ́n dà bí ti àwọn tí ó ti pinnu tán láti jẹ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ run ní ibi ìlùmọ́.+ 15  O fi àwọn ẹṣin rẹ rin òkun já, la òkìtì alagbalúgbú omi.+ 16  Mo gbọ́, ṣìbáṣìbo sì bá ikùn mi; ètè mí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ sí ìró náà; ìjẹrà bẹ̀rẹ̀ sí wọnú egungun+ mi; ṣìbáṣìbo sì bá mi nínú ipò mi, kí n lè fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ dúró de ọjọ́ wàhálà,+ de gígòkè wá rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn,+ kí ó lè gbé sùnmọ̀mí lọ bá wọn. 17  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè má yọ ìtànná,+ àjàrà sì lè má mú èso jáde; iṣẹ́ igi ólífì lè yọrí sí ìkùnà ní ti tòótọ́, àwọn ilẹ̀ onípele títẹ́jú sì lè má mú oúnjẹ wá ní ti tòótọ́;+ a lè ya agbo ẹran nípa kúrò nínú ọgbà ẹran ní ti tòótọ́, ọ̀wọ́ ẹran sì lè má sí nínú àwọn gbàgede;+ 18  Síbẹ̀, ní tèmi, dájúdájú, èmi yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà;+ èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run ìgbàlà+ mi. 19  Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni ìmí+ mi; yóò sì ṣe ẹsẹ̀ mi bí ti àwọn egbin,+ yóò sì mú kí n rìn+ ní àwọn ibi gíga mi. Sí olùdarí àwọn ohun èlò ìkọrin mi olókùn tín-ín-rín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé