Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Hábákúkù 2:1-20

2  Ibi ìṣọ́ mi ni èmi yóò dúró sí, èmi yóò sì mú ìdúró+ mi lórí odi ààbò; èmi yóò sì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́,+ láti rí ohun tí yóò sọ nípasẹ̀ mi,+ àti ohun tí èmi yóò fi fèsì nígbà tí a bá fi ìbáwí tọ́ mi sọ́nà.+  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lóhùn, ó sì wí pé: “Kọ ìran náà sílẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere sára àwọn wàláà,+ kí ẹni tí ń kà á sókè lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí ó já geere.+  Nítorí ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀,+ ó sì ń sáré lọ ní mímí hẹlẹhẹlẹ sí òpin, kì yóò sì purọ́. Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà.+ Kì yóò pẹ́.  “Wò ó! Ọkàn rẹ̀ ti gbé fùkẹ̀;+ kò dúró ṣánṣán nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ti olódodo, òun yóò máa wà láàyè nìṣó+ nípa ìṣòtítọ́ rẹ̀.  Ní tòótọ́, nítorí tí wáìnì ń ṣe àdàkàdekè,+ abarapá ọkùnrin jẹ́ ajọra-ẹni-lójú;+ òun kì yóò sì lé góńgó+ rẹ̀ bá, ẹni tí ó mú kí ọkàn rẹ̀ ní àyè gbígbòòrò bí Ṣìọ́ọ̀lù, tí ó sì dà bí ikú, tí a kò sì lè tẹ́ lọ́rùn.+ Ó sì ń bá a nìṣó ní kíkó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì ń kó gbogbo ènìyàn jọpọ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀.+  Àwọn wọ̀nyí gan-an, gbogbo wọn, kì yóò ha gbé ọ̀rọ̀ òwe+ àti ìpàṣamọ̀, àwọn ẹ̀dà ọ̀rọ̀ sókè sí i bí? Ẹnì kan yóò sì wí pé, “‘Ègbé ni fún ẹni tí ń sọ ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ di púpọ̀+—yóò ti pẹ́ tó!+—tí ó sì ń mú gbèsè wúwo sí ara rẹ̀ lọ́rùn!  Àwọn tí ń gba èlé lọ́wọ́ rẹ kì yóò ha dìde lójijì, àwọn tí ń mì ọ́ lọ́nà lílenípá kì yóò ha sì jí, dájúdájú, tí ìwọ yóò sì di ohun kíkó ní ìkógun fún wọn?+  Nítorí tí ìwọ alára fi àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ ṣe ìjẹ,+ gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ènìyàn yóò fi ọ́ ṣe ìjẹ, nítorí títa ẹ̀jẹ̀ aráyé sílẹ̀ àti ìwà ipá sí ilẹ̀ ayé, ìlú náà àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.+  “‘Ègbé ní fún ẹni tí ń jèrè ibi fún ilé+ ara rẹ̀, kí ó bàa lè gbé ìtẹ́ rẹ̀ ka ibi gíga, kí a bàa lè dá a nídè kúrò lọ́wọ́ ìgbámú ohun tí ó kún fún ìyọnu àjálù!+ 10  O ti pète ohun tí ń tini lójú sí ilé rẹ, ìkékúrò ọ̀pọ̀ ènìyàn;+ ọkàn rẹ sì ń dẹ́ṣẹ̀.+ 11  Nítorí òkúta yóò fi ohùn arò ké jáde láti inú ògiri, igi ìrólé yóò sì dá a lóhùn+ láti inú iṣẹ́ àfigiṣe. 12  “‘Ègbé ni fún ẹni tí ń fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ tẹ ìlú ńlá dó, tí ó sì ti fi àìṣòdodo+ fìdí ìlú múlẹ̀ gbọn-in! 13  Wò ó! Kì í ha ṣe láti ọ̀dọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni àwọn ènìyàn yóò ti máa ṣe làálàá kìkì fún iná, tí àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kó àárẹ̀ bá ara wọn kìkì fún asán?+ 14  Nítorí ilẹ̀ ayé yóò kún fún mímọ ògo Jèhófà bí omi ti bo òkun.+ 15  “‘Ègbé ni fún ẹni tí ń fún alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní nǹkan mu, ní síso ìhónú àti ìbínú rẹ mọ́ ọn, kí o bàa lè mú kí wọ́n mu àmupara,+ fún ète wíwo àwọn apá ìtìjú+ wọn. 16  Dájúdájú, a ó fi àbùkù bọ́ ìwọ yó dípò ògo.+ Mu pẹ̀lú, ìwọ fúnra rẹ,+ kí a sì kà ọ́ sí aláìdádọ̀dọ́.+ Ife ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà yóò wá sọ́dọ̀ rẹ,+ ojútì yóò sì dé bá ògo rẹ; 17  nítorí pé ìwà ipá tí a hù sí Lẹ́bánónì+ ni ohun tí yóò bò ọ́, àti ìwà fífi ipá kó àwọn ẹranko tí ń dáyà já wọn ní ìkógun, nítorí títa ẹ̀jẹ̀ aráyé sílẹ̀ àti ìwà ipá tí a hù sí ilẹ̀ ayé,+ ìlú náà àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.+ 18  Àǹfààní wo ni ère gbígbẹ́ jẹ́,+ nígbà tí ẹni tí ó ṣe é ti gbẹ́ ẹ, ère dídà, àti olùkọ́ni ní èké?+ nígbà tí ẹni tí ó ṣe é bí ó ṣe rí ti gbẹ́kẹ̀ lé e,+ dé ìwọ̀n ṣíṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí, tí kò lè sọ̀rọ̀?+ 19  “‘Ègbé ni fún ẹni tí ń wí fún igi pé: “Jí!” fún òkúta tí ó yadi pé: “Jí! Òun fúnra rẹ̀ yóò fúnni ní ìtọ́ni”!+ Wò ó! Wúrà àti fàdákà+ ni a fi bò ó yí ká, kò sì sí èémí kankan rárá ní inú rẹ̀.+ 20  Ṣùgbọ́n Jèhófà ń bẹ nínú tẹ́ńpìlì+ mímọ́ rẹ̀. Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú rẹ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé!’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé