Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Gálátíà 6:1-18

6  Ẹ̀yin ará, bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé+ kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ tóótun nípa tẹ̀mí+ gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù,+ bí olúkúlùkù yín ti ń ṣọ́ ara rẹ̀ lójú méjèèjì,+ kí a má bàa dẹ ìwọ náà wò.+  Ẹ máa bá a lọ ní ríru àwọn ẹrù ìnira+ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì tipa báyìí mú òfin Kristi ṣẹ.+  Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan,+ ó ń tan èrò inú ara rẹ̀ jẹ.  Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́,+ nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra+ pẹ̀lú ẹlòmíràn.  Nítorí olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí ẹnikẹ́ni tí a ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu+ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ náà máa ṣàjọpín+ àwọn ohun rere gbogbo pẹ̀lú ẹni tí ń fúnni ní irúfẹ́ ẹ̀kọ́ ọlọ́rọ̀ ẹnu bẹ́ẹ̀.+  Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà:+ Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà.+ Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú;+  nítorí ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹran ara rẹ̀ lọ́kàn yóò ká ìdíbàjẹ́ láti inú ẹran ara rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn+ yóò ká ìyè àìnípẹ̀kun láti inú ẹ̀mí.+  Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,+ nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.+ 10  Ní ti gidi, nígbà náà, níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un,+ ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.+ 11  Ẹ wo àwọn lẹ́tà gàdàgbà-gàdàgbà tí mo fi kọ̀wé sí yín ní ọwọ́ ara mi.+ 12  Gbogbo àwọn tí ń fẹ́ láti ní ìrísí wíwuni nínú ẹran ara ni àwọn tí ń gbìyànjú láti sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún yín láti dádọ̀dọ́,+ kìkì kí a má bàa ṣe inúnibíni sí wọn nítorí òpó igi oró Kristi,+ Jésù. 13  Nítorí àwọn tí ń dádọ̀dọ́ pàápàá ni àwọn alára kò pa Òfin mọ́,+ ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ kí ẹ dádọ̀dọ́ kí wọ́n lè ní ìdí fún ṣíṣògo nínú ẹran ara yín. 14  Kí ó má ṣẹlẹ̀ láé pé èmi yóò ṣògo, àyàfi nínú òpó igi oró+ Olúwa wa Jésù Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí a kan ayé mọ́gi lójú tèmi+ àti èmi lójú ti ayé. 15  Nítorí ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́ kò jámọ́ ohunkóhun,+ ṣùgbọ́n ìṣẹ̀dá tuntun+ ni ó jámọ́ nǹkan kan. 16  Gbogbo àwọn tí yóò sì máa rìn létòletò nípasẹ̀ ìlànà àfilélẹ̀ fún ìwà híhù yìí, kí àlàáfíà àti àánú wà lórí wọn, àní lórí Ísírẹ́lì Ọlọ́run.+ 17  Láti ìsinsìnyí lọ, kí ẹnì kankan má ṣe máa dà mí láàmú mọ́, nítorí èmi ń ru àwọn àpá àmì+ ti ẹrú Jésù ní ara mi.+ 18  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú ẹ̀mí+ tí ẹ ń fi hàn, ẹ̀yin ará. Àmín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé