Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Gálátíà 5:1-26

5  Fún irúfẹ́ òmìnira bẹ́ẹ̀ ni Kristi dá wa sílẹ̀ lómìnira.+ Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin,+ ẹ má sì jẹ́ kí a tún há yín mọ́ inú àjàgà ìsìnrú.+  Ẹ wò ó! Èmi, Pọ́ọ̀lù, ń sọ fún yín pé bí ẹ bá dádọ̀dọ́,+ Kristi kì yóò ṣàǹfààní kankan fún yín.  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, mo tún jẹ́rìí sí olúkúlùkù ènìyàn tí ń dádọ̀dọ́ pé ó wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti pa gbogbo Òfin mọ́.+  A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹnì yòówù kí ẹ jẹ́, tí ẹ bá gbìyànjú láti di ẹni tí a polongo ní olódodo nípasẹ̀ òfin;+ ẹ ti yẹsẹ̀ kúrò nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.+  Ní tiwa, nípa ẹ̀mí ni a ń fi ìháragàgà dúró de òdodo tí a ń retí nítorí ìgbàgbọ́.+  Nítorí ní ti Kristi Jésù, ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́ kò ní ìníyelórí kankan,+ bí kò ṣe ìgbàgbọ́+ tí ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ìfẹ́.+  Ẹ̀yin ti ń sáré dáadáa tẹ́lẹ̀.+ Ta ní dí yín lọ́wọ́ nínú bíbá a nìṣó ní ṣíṣègbọràn sí òtítọ́?+  Irú ìyíniléròpadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ẹni tí ń pè yín wá.+  Ìwúkàrà díẹ̀ ní ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ di wíwú.+ 10  Mo ní ìgbọ́kànlé+ nípa ẹ̀yin tí ẹ wà ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Olúwa pé ẹ kì yóò ronú lọ́nà mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó ìdààmú+ bá yín yóò ru ìdájọ́ rẹ̀,+ ẹnì yòówù tí ì báà jẹ́. 11  Ní tèmi, ẹ̀yin ará, bí mo bá ṣì ń wàásù ìdádọ̀dọ́, èé ṣe tí a fi ń ṣe inúnibíni sí mi síbẹ̀? Nígbà náà, ohun ìkọ̀sẹ̀+ òpó igi oró+ náà ni a ti fi òpin sí ní tòótọ́.+ 12  Ì bá wù mí kí àwọn ọkùnrin tí ń gbìyànjú láti dojú yín dé+ tilẹ̀ tẹ ara wọn lọ́dàá.+ 13  Dájúdájú, òmìnira ni a pè yín fún,+ ẹ̀yin ará; kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yìí gẹ́gẹ́ bí ìsúnniṣe fún ẹran ara,+ ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìfẹ́, ẹ máa sìnrú fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.+ 14  Nítorí gbogbo Òfin pátá di èyí tí a mú ṣẹ+ nínú àsọjáde kan ṣoṣo, èyíinì ni: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”+ 15  Bí ó ti wù kí ó rí, bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní bíbu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín ní àjẹrun,+ ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa pa ara yín rẹ́ ráúráú lẹ́nì kìíní-kejì.+ 16  Ṣùgbọ́n èmi wí pé, Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí,+ ẹ kì yóò sì ṣe ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara rárá.+ 17  Nítorí ẹran ara lòdì sí ẹ̀mí+ nínú ìfẹ́-ọkàn rẹ̀, ẹ̀mí sì lòdì sí ẹran ara; nítorí àwọn wọ̀nyí kọjú ìjà sí ara wọn, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ohun náà tí ẹ óò fẹ́ láti ṣe ni ẹ kò ṣe.+ 18  Síwájú sí i, bí ẹ̀mí bá ń ṣamọ̀nà yín,+ ẹ kò sí lábẹ́ òfin.+ 19  Wàyí o, àwọn iṣẹ́ ti ara fara hàn kedere,+ àwọn sì ni àgbèrè,+ ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu,+ 20  ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò,+ ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, 21  ìlara, mímu+ àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí. Ní ti nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń kìlọ̀ ṣáájú fún yín, lọ́nà kan náà gẹ́gẹ́ bí mo ti kìlọ̀ ṣáájú fún yín, pé àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù+ kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.+ 22  Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, èso+ ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere,+ ìgbàgbọ́, 23  ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.+ Kò sí òfin kankan lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí.+ 24  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi Jésù kan ẹran ara mọ́gi pa pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ onígbòónára àti ìfẹ́-ọkàn rẹ̀.+ 25  Bí a bá wà láàyè nípa ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòletò nípa ẹ̀mí pẹ̀lú.+ 26  Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di olùgbéra-ẹni-lárugẹ, ní ríru ìdíje+ sókè pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé