Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Gálátíà 4:1-31

4  Wàyí o, mo wí pé níwọ̀n ìgbà tí ajogún náà bá ṣì jẹ́ ìkókó, kò yàtọ̀ rárá sí ẹrú,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ olúwa ohun gbogbo,  ṣùgbọ́n ó wà lábẹ́ àwọn ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó+ àti lábẹ́ àwọn ìríjú títí di ọjọ́ tí baba rẹ̀ ti yàn tẹ́lẹ̀.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa pẹ̀lú, nígbà tí a jẹ́ ìkókó, a ń bá a lọ nínú ìsọdẹrú lọ́wọ́ àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀+ tí ó jẹ́ ti ayé.  Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkókò dé,+ Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ jáde,+ ẹni tí ó ti ara obìnrin jáde wá,+ tí ó sì wá wà lábẹ́ òfin,+  kí ó lè tú àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin+ sílẹ̀ nípa rírà,+ kí àwa, ẹ̀wẹ̀, lè rí ìsọdọmọ gbà.+  Wàyí o, nítorí pé ẹ jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run ti rán ẹ̀mí+ Ọmọ rẹ̀ jáde sínú ọkàn-àyà wa, ó sì ń ké jáde pé: “Ábà, Baba!”+  Nítorí bẹ́ẹ̀, ìwọ kì í ṣe ẹrú mọ́ bí kò ṣe ọmọ; bí o bá sì jẹ́ ọmọ, ìwọ jẹ́ ajogún pẹ̀lú nípasẹ̀ Ọlọ́run.+  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọ́run,+ nígbà náà ni ẹ ń sìnrú fún àwọn tí wọn kì í ṣe ọlọ́run lọ́nà ti ẹ̀dá.+  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí ẹ ti wá mọ Ọlọ́run,+ tàbí kí a kúkú sọ pé nísinsìnyí tí ẹ ti wá di mímọ̀ fún Ọlọ́run, èé ti rí tí ẹ tún ń padà sẹ́yìn sí àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ aláìlera+ àti akúrẹtẹ̀,+ tí ẹ sì ń fẹ́ láti tún padà sìnrú fún wọn?+ 10  Ẹ ń pa àwọn ọjọ́+ àti oṣù+ àti àsìkò àti ọdún mọ́ fínnífínní. 11  Ẹ̀rù ń bà mí nítorí yín, pé lọ́nà kan ṣáá mo ti ṣe làálàá lásán+ lórí yín. 12  Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín, Ẹ dà bí èmi,+ nítorí nígbà kan, èmi náà rí gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí.+ Ẹ kò ṣe àìtọ́ kankan sí mi.+ 13  Ṣùgbọ́n ẹ mọ̀ pé nínú àìsàn ara mi ni èmi polongo ìhìn rere fún yín ní ìgbà àkọ́kọ́.+ 14  Ohun tí ó sì jẹ́ àdánwò fún yín nínú ara mi, ni ẹ kò fojú tín-ín-rín tàbí fi ìríra tutọ́ sí; ṣùgbọ́n ẹ gbà mí bí áńgẹ́lì+ Ọlọ́run, bí Kristi Jésù.+ 15  Ibo wá ni ayọ̀ tí ẹ ní tẹ́lẹ̀ yẹn wà?+ Nítorí mo jẹ́rìí yín pé, bí ó bá ti ṣeé ṣe ni, ẹ̀yin ì bá yọ ojú yín jáde, kí ẹ sì kó wọn fún mi.+ 16  Tóò, nígbà náà, mo ha ti di ọ̀tá yín+ nítorí pé mo sọ òtítọ́ fún yín bí?+ 17  Wọ́n ń fi tìtara-tìtara wá yín,+ kì í ṣe lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fẹ́ sé yín mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi ni, kí ẹ lè máa fi tìtara-tìtara wá wọn.+ 18  Bí ó ti wù kí ó rí, ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láti máa fi tìtara-tìtara wá yín fún ìdí tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀+ ní gbogbo ìgbà, kì í sì í ṣe kìkì nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín nìkan,+ 19  ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké,+ tí mo tún wà nínú ìrora ìbímọ fún títí a ó fi ṣẹ̀dá Kristi nínú yín.+ 20  Ṣùgbọ́n ì bá wù mí kí n wà lọ́dọ̀ yín nísinsìnyí gan-an,+ kí n sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó yàtọ̀, nítorí ọkàn mi dà rú+ nítorí yín. 21  Ẹ sọ fún mi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ wà ní abẹ́ òfin,+ Ṣé ẹ kò gbọ́ Òfin ni?+ 22  Fún àpẹẹrẹ, a kọ̀wé rẹ̀ pé Ábúráhámù ní ọmọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́bìnrin+ àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin;+ 23  ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́bìnrin ni a bí ní ti gidi lọ́nà ti ara,+ èyí ìkejì tí ó jẹ́ láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin jẹ́ nípasẹ̀ ìlérí.+ 24  Nǹkan wọ̀nyí dúró gẹ́gẹ́ bí àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìṣàpẹẹrẹ;+ nítorí àwọn obìnrin wọ̀nyí túmọ̀ sí májẹ̀mú méjì,+ èyí tí ó wá láti Òkè Ńlá Sínáì,+ tí ń bí àwọn ọmọ fún ìsìnrú, èyí tí ó sì jẹ́ Hágárì. 25  Wàyí o, Hágárì yìí túmọ̀ sí Sínáì,+ òkè ńlá kan ní Arébíà, ó sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú Jerúsálẹ́mù ti òní, nítorí ó wà nínú ìsìnrú+ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. 26  Ṣùgbọ́n Jerúsálẹ́mù+ ti òkè jẹ́ òmìnira, òun sì ni ìyá wa.+ 27  Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: “Máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ; bú jáde, kí o sì ké sókè, ìwọ obìnrin tí kò ní ìrora ìbímọ; nítorí àwọn ọmọ obìnrin tí a sọ di ahoro pọ̀ níye ju ti obìnrin tí ó ní ọkọ lọ.”+ 28  Wàyí o, ẹ̀yin ará, àwa jẹ́ ọmọ ìlérí gẹ́gẹ́ bí Ísákì ti jẹ́.+ 29  Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èyí tí a bí lọ́nà ti ara nígbà yẹn ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe inúnibíni+ sí èyí tí a bí lọ́nà ti ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ náà ni nísinsìnyí.+ 30  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí ni Ìwé Mímọ́ wí? “Lé ìránṣẹ́bìnrin náà àti ọmọkùnrin rẹ̀ jáde, nítorí ọmọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin náà kì yóò jẹ́ ajogún lọ́nàkọnà pẹ̀lú ọmọkùnrin ti òmìnira obìnrin.”+ 31  Nítorí náà, ẹ̀yin ará, àwa kì í ṣe ọmọ ìránṣẹ́bìnrin,+ bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé