Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Gálátíà 2:1-21

2  Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, mo tún wá gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù+ pẹ̀lú Bánábà,+ bákan náà, mo mú Títù lọ pẹ̀lú mi.  Ṣùgbọ́n mo gòkè lọ nítorí ìṣípayá kan.+ Mo sì gbé ìhìn rere tí mo ń wàásù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kalẹ̀ níwájú wọn,+ bí ó ti wù kí ó rí, níkọ̀kọ̀ ni, níwájú àwọn tí ó jẹ́ ẹni títayọ, kí ó má bàa jẹ́ pé lọ́nà kan ṣáá mo ń sáré+ tàbí mo ti sáré lásán.+  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Títù+ pàápàá, tí ó wà pẹ̀lú mi, ni a kò sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún láti dádọ̀dọ́,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Gíríìkì ni.  Ṣùgbọ́n nítorí àwọn èké arákùnrin+ tí a yọ́ mú wọlé,+ àwọn tí ó pá kọ́lọ́ wọlé láti ṣe amí òmìnira+ wa tí a ní ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, kí wọ́n lè sọ wá di ẹrú pátápátá+  àwọn wọ̀nyí ni àwa kò juwọ́ sílẹ̀ fún ní ìtẹríba,+ rárá o, kì í tilẹ̀ ṣe fún wákàtí kan, kí òtítọ́+ ìhìn rere lè máa bá a lọ ní wíwà pẹ̀lú yín.  Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dà bí ẹni pé wọ́n jámọ́ ohun kan+—irú ẹnì yòówù kí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀ rí kò mú ìyàtọ̀ kankan wá fún mi+—Ọlọ́run kò fi ìrísí òde ènìyàn kankan ṣèdájọ́+—ní ti tòótọ́, ní tèmi, àwọn ẹni títayọ wọnnì kò fi ohunkóhun tí ó jẹ́ tuntun fúnni.  Ṣùgbọ́n, dípò èyí, nígbà tí wọ́n rí i pé a ti fi ìhìn rere àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìdádọ̀dọ́+ sí ìkáwọ́ mi,+ gẹ́gẹ́ bí a ti fi ti àwọn tí ó dádọ̀dọ́ sí ìkáwọ́ Pétérù+  nítorí Ẹni tí ó fún Pétérù ní àwọn agbára tí ó pọndandan fún iṣẹ́ àpọ́sítélì fún àwọn tí ó dádọ̀dọ́, fún èmi pẹ̀lú ní àwọn agbára+ fún àwọn tí í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè;  bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí wọ́n wá mọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ tí a fi fún mi,+ Jákọ́bù+ àti Kéfà àti Jòhánù, àwọn tí wọ́n dà bí ọwọ̀n,+ fún èmi àti Bánábà+ ní ọwọ́ ọ̀tún ìṣàjọpín,+ pé kí a lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kí àwọn lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó dádọ̀dọ́. 10  Kìkì pé kí a fi àwọn òtòṣì sọ́kàn.+ Ohun yìí gan-an ni èmi pẹ̀lú ti fi taratara sakun láti ṣe.+ 11  Àmọ́ ṣá o, nígbà tí Kéfà+ wá sí Áńtíókù,+ mo takò ó lójúkojú, nítorí ó yẹ fún ìdálẹ́bi.+ 12  Nítorí ṣáájú dídé àwọn ènìyàn kan láti ọ̀dọ̀ Jákọ́bù,+ ó máa ń bá àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè jẹun;+ ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó wá ń fà sẹ́yìn, ó sì ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, ní ìbẹ̀rù+ ẹgbẹ́ àwọn tí ó dádọ̀dọ́.+ 13  Àwọn Júù yòókù pẹ̀lú dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ìdíbọ́n yìí,+ tó bẹ́ẹ̀ tí a fa Bánábà+ pàápàá lọ sínú ìdíbọ́n wọn. 14  Ṣùgbọ́n nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn lọ́nà títọ́ gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìhìn rere,+ mo sọ fún Kéfà níwájú gbogbo wọn pé:+ “Bí ìwọ, tí o tilẹ̀ jẹ́ Júù, bá ń gbé ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè ti máa ń ṣe, tí kì í sì í ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn Júù ti máa ń ṣe, èé ti rí tí o fi sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè láti máa gbé gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn Júù?”+ 15  Àwa tí a jẹ́ Júù lọ́nà ti ẹ̀dá,+ tí a kì í sì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀+ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè, 16  gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ ní tòótọ́ pé a kì í polongo ènìyàn ní olódodo+ nítorí àwọn iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe kìkì nípasẹ̀ ìgbàgbọ́+ nínú Kristi Jésù, àní àwa ti ní ìgbàgbọ́ wa nínú Kristi Jésù, kí a lè polongo wa ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́ nínú Kristi,+ kì í sì í ṣe nítorí àwọn iṣẹ́ òfin, nítorí pé nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin, kò sí ẹran ara tí a ó polongo ní olódodo.+ 17  Wàyí o, bí ó bá jẹ́ pé, ní wíwá ọ̀nà tí a ó fi polongo wa ní olódodo nípasẹ̀ Kristi,+ a tún rí àwa fúnra wa ní ẹlẹ́ṣẹ̀,+ Kristi ní ti gidi ha jẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí?+ Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! 18  Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn ohun náà gan-an tí mo wó palẹ̀ rí ni mo tún ń gbé ró,+ mo ń fi ara mi hàn gbangba pé olùrélànàkọjá ni mí.+ 19  Ní tèmi, mo kú sí òfin nípasẹ̀ òfin,+ kí n lè di alààyè sí Ọlọ́run.+ 20  A kàn mí mọ́gi pa pọ̀ pẹ̀lú Kristi.+ Kì í ṣe èmi ni mo tún wà láàyè mọ́,+ bí kò ṣe Kristi ni ó wà láàyè ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi.+ Ní tòótọ́, ìgbésí ayé tí mo ń gbé nínú ara nísinsìnyí ni mo ń gbé+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi, tí ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.+ 21  Èmi kò rọ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan;+ nítorí bí òdodo bá jẹ́ nípasẹ̀ òfin,+ a jẹ́ pé Kristi ní ti gidi kú lásán.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé