Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Gálátíà 1:1-24

1  Pọ́ọ̀lù,+ àpọ́sítélì kan,+ kì í ṣe láti ọwọ́ àwọn ènìyàn tàbí nípasẹ̀ ènìyàn kan, bí kò ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi+ àti Ọlọ́run Baba,+ ẹni tí ó gbé e dìde kúrò nínú òkú,+ 2  àti gbogbo àwọn ará tí ń bẹ pẹ̀lú mi,+ sí àwọn ìjọ Gálátíà:+  Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà+ láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa.  Ó fi ara rẹ̀ fúnni nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ kí ó lè dá wa nídè kúrò nínú ètò àwọn nǹkan burúkú ìsinsìnyí+ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́+ Ọlọ́run àti Baba wa,  ẹni tí ògo wà fún títí láé àti láéláé.+ Àmín.  Ẹnu yà mí pé ní kíákíá bẹ́ẹ̀ ni a fẹ́ mú yín kúrò lọ́dọ̀ Ẹni+ tí ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ Kristi pè yín, lọ sínú oríṣi ìhìn rere mìíràn.+  Ṣùgbọ́n kì í ṣe òmíràn; kìkì pé àwọn kan wà tí wọ́n ń kó ìdààmú bá yín,+ tí wọ́n sì ń fẹ́ láti yí ìhìn rere nípa Kristi po.+  Àmọ́ ṣá o, àní bí àwa tàbí áńgẹ́lì kan láti ọ̀run bá polongo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere ohun tí ó ré kọjá nǹkan tí a ti polongo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere, kí ó di ẹni ègún.+  Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ lókè, mo tún ń sọ nísinsìnyí pẹ̀lú pé, Ẹnì yòówù tí ì báà jẹ́, tí ń polongo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere ohun tí ó ré kọjá nǹkan tí ẹ ti tẹ́wọ́ gbà,+ kí ó di ẹni ègún. 10  Ní ti tòótọ́, ṣé àwọn ènìyàn ni mo ń gbìyànjú láti yí lérò padà nísinsìnyí ni tàbí Ọlọ́run? Tàbí mo ha ń wá ọ̀nà láti wu àwọn ènìyàn?+ Bí mo bá ṣì ń wu àwọn ènìyàn,+ èmi kì yóò jẹ́ ẹrú Kristi.+ 11  Nítorí mo pè é wá sí àfiyèsí yín, ẹ̀yin ará, pé ìhìn rere tí èmi polongo gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere kì í ṣe ohun tí ó jẹ́ ti ẹ̀dá ènìyàn;+ 12  nítorí èmi kò gbà á láti ọwọ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, àyàfi nípasẹ̀ ìṣípayá láti ọwọ́ Jésù Kristi.+ 13  Dájúdájú, ẹ gbọ́ nípa ìwà mi tẹ́lẹ̀ rí nínú Ìsìn Àwọn Júù,+ pé títí dé àyè tí ó pọ̀ lápọ̀jù ni mo ń ṣe inúnibíni+ sí ìjọ Ọlọ́run, tí mo sì ń pa á run,+ 14  mo sì ń ní ìtẹ̀síwájú púpọ̀ nínú Ìsìn Àwọn Júù ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn ojúgbà mi nínú ẹ̀yà mi,+ níwọ̀n bí mo ti jẹ́ onítara+ púpọ̀púpọ̀ jù fún àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́+ àwọn baba mi. 15  Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọlọ́run, ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ láti inú ilé ọlẹ̀ ìyá mi, tí ó sì pè+ mí nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ rẹ̀, ronú pé ó dára 16  láti ṣí Ọmọ rẹ̀ payá fún mi,+ kí n lè polongo ìhìn rere nípa rẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè,+ èmi kò lọ bá ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀+ ṣe àpérò ní kíá. 17  Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù sọ́dọ̀ àwọn tí ó jẹ́ àpọ́sítélì ṣáájú mi,+ ṣùgbọ́n mo lọ sí Arébíà, mo sì tún padà wá sí Damásíkù.+ 18  Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, mo gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù+ láti ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ Kéfà,+ mo sì dúró lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. 19  Ṣùgbọ́n èmi kò rí ẹnikẹ́ni mìíràn nínú àwọn àpọ́sítélì, àyàfi Jákọ́bù+ arákùnrin+ Olúwa. 20  Wàyí o, ní ti àwọn ohun tí mo ń kọ̀wé sí yín, wò ó! níwájú Ọlọ́run, èmi kò purọ́.+ 21  Lẹ́yìn èyíinì, mo lọ+ sí àwọn ẹkùn ilẹ̀ Síríà àti ti Sìlíṣíà. 22  Ṣùgbọ́n àwọn ìjọ Jùdíà tí ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi+ kò mọ̀ mí sójú; 23  kìkì pé wọ́n ti máa ń gbọ́ pé: “Ọkùnrin tí ó ṣe inúnibíni+ sí wa tẹ́lẹ̀ rí ti ń polongo ìhìn rere nísinsìnyí nípa ìgbàgbọ́ náà tí ó pa run tẹ́lẹ̀ rí.”+ 24  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yin Ọlọ́run lógo+ nítorí mi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé