Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Fílípì 4:1-23

4  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, tí mo sì ń yánhànhàn fún, ìdùnnú àti adé+ mi, ẹ dúró gbọn-in gbọn-in+ ní ọ̀nà yìí nínú Olúwa, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n.  Yúódíà ni mo gbà níyànjú, Síńtíkè ni mo sì gbà níyànjú láti ní èrò inú+ kan náà nínú Olúwa.  Bẹ́ẹ̀ ni, mo béèrè lọ́wọ́ rẹ pẹ̀lú, ojúlówó alájọru àjàgà,+ láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn obìnrin wọ̀nyí tí wọ́n ti làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú mi+ nínú ìhìn rere pa pọ̀ pẹ̀lú Kílẹ́mẹ́ǹtì àti àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀+ mi yòókù, àwọn tí orúkọ+ wọ́n wà nínú ìwé ìyè.+  Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa.+ Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀!+  Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò+ yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn. Olúwa ń bẹ nítòsí.+  Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun,+ ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀+ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run;+  àlàáfíà+ Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà+ yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.  Lákòótán, ẹ̀yin ará, ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà,+ ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.+  Àwọn ohun tí ẹ kẹ́kọ̀ọ́, tí ẹ tẹ́wọ́ gbà, tí ẹ gbọ́, tí ẹ sì rí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi, ẹ máa fi ìwọ̀nyí ṣe ìwà hù;+ Ọlọ́run àlàáfíà+ yóò sì wà pẹ̀lú yín. 10  Lóòótọ́, mo yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé nísinsìnyí nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ẹ ti mú ìrònú yín fún mi sọ jí,+ èyí tí ẹ ń ronú lé lórí tẹ́lẹ̀ ní ti gidi, ṣùgbọ́n àyè kò ṣí sílẹ̀ fún yín. 11  Kì í ṣe pé mo ń sọ̀rọ̀ nípa wíwà nínú àìní, nítorí mo ti kẹ́kọ̀ọ́, nínú àwọn ipò yòówù tí mo bá wà, láti máa ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi.+ 12  Ní tòótọ́, mo mọ bí a ṣe ń wà pẹ̀lú àwọn ìpèsè bín-ín-tín,+ ní tòótọ́ mo mọ bí a ṣe ń ní ọ̀pọ̀ yanturu. Nínú ohun gbogbo àti nínú ipò gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní.+ 13  Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.+ 14  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ṣe dáadáa ní dídi alájọpín+ pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú mi.+ 15  Ní ti tòótọ́, ẹ̀yin ará Fílípì mọ̀ pẹ̀lú pé ní ìbẹ̀rẹ̀ pípolongo ìhìn rere, nígbà tí mo kúrò ní Makedóníà, kò sí ìjọ kan tí ó ṣe àjọpín pẹ̀lú mi nínú ọ̀ràn fífúnni àti gbígbà, àyàfi ẹ̀yin nìkan;+ 16  nítorí, ní Tẹsalóníkà pàápàá, ẹ fi nǹkan ránṣẹ́ sí mi lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kejì fún àìní mi. 17  Kì í ṣe pé mo ń fi taratara wá ẹ̀bùn+ náà, ṣùgbọ́n pé mo ń fi taratara wá èso+ tí ń mú èrè púpọ̀ sí i wá sínú àkọsílẹ̀ yín. 18  Bí ó ti wù kí ó rí, mo ní ohun gbogbo ní kíkún, mo sì ní ọ̀pọ̀ yanturu. Mo ti ní tẹ́rùn, nísinsìnyí tí mo ti gba àwọn ohun tí ó wá láti ọ̀dọ̀ yín lọ́wọ́ Ẹpafíródítù,+ òórùn tí ń run dídùn,+ ẹbọ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà,+ tí ó wu Ọlọ́run gidigidi. 19  Ẹ̀wẹ̀, Ọlọ́run+ mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní+ yín dé ìwọ̀n ọrọ̀+ rẹ̀ nínú ògo nípasẹ̀ Kristi Jésù. 20  Wàyí o, Ọlọ́run wa àti Baba ni kí ògo wà fún títí láé àti láéláé.+ Àmín. 21  Ẹ bá mi kí+ olúkúlùkù ẹni mímọ́ tí ń bẹ ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Kristi Jésù. Àwọn ará tí ń bẹ pẹ̀lú mi kí yín. 22  Gbogbo ẹni mímọ́, ṣùgbọ́n ní pàtàkì àwọn tí ó jẹ́ ti agbo ilé Késárì, kí+ yín. 23  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ fi hàn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé