Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Fílípì 3:1-21

3  Lákòótán, ẹ̀yin ará mi, ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀ nínú Olúwa.+ Láti máa kọ̀wé àwọn ohun kan náà sí yín kò fa ìdààmú fún mi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ kí ó má bàa sí ewu fún yín.  Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn ajá,+ ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn oníṣẹ́ èṣe, ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn tí ń gé apá kan ẹran ara jùnù.+  Nítorí àwa ni a ní ìdádọ̀dọ́ tòótọ́,+ tí a ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run,+ tí a sì ní ìṣògo wa nínú Kristi Jésù,+ tí a kò sì ní ìgbọ́kànlé wa nínú ẹran ara,+  bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ẹnikẹ́ni bá ní àwọn ìdí fún ìgbọ́kànlé nínú ẹran ara, èmi pẹ̀lú ní. Bí ènìyàn èyíkéyìí mìíràn bá rò pé òun ní àwọn ìdí fún ìgbọ́kànlé nínú ẹran ara, tèmi tún jù bẹ́ẹ̀:+  ẹni tí ó dádọ̀dọ́ ní ọjọ́ kẹjọ,+ láti inú ìlà ìran ìdílé Ísírẹ́lì, láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ Hébérù tí a bí láti inú àwọn Hébérù;+ ní ti òfin, Farisí;+  ní ti ìtara, mo ń ṣe inúnibíni sí ìjọ;+ ní ti òdodo tí ó jẹ́ nípasẹ̀ òfin, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi.  Síbẹ̀, àwọn ohun tí ó jẹ́ èrè fún mi, ìwọ̀nyí ni mo ti kà sí àdánù ní tìtorí Kristi.+  Họ́wù, ní ti èyíinì, ní tòótọ́ mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi.+ Ní tìtorí rẹ̀, èmi ti gba àdánù ohun gbogbo, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí,+ kí n lè jèrè Kristi,  kí a sì rí mi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí n má ṣe ní òdodo ti ara mi, èyí tí ń jẹyọ láti inú òfin,+ bí kò ṣe èyíinì tí ó jẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́+ nínú Kristi, òdodo tí ń jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nítorí ìgbàgbọ́,+ 10  láti lè mọ òun àti agbára àjíǹde rẹ̀+ àti àjọpín nínú àwọn ìjìyà rẹ̀,+ ní jíjọ̀wọ́ ara mi fún ikú tí ó dàbí tirẹ̀,+ 11  láti rí i bí ọwọ́ mi lọ́nàkọnà bá lè tẹ àjíǹde+ àkọ́kọ́ kúrò nínú òkú. 12  Kì í ṣe pé mo ti rí i gbà ná tàbí pé a ti sọ mí di pípé ná,+ ṣùgbọ́n mo ń lépa+ láti rí i bí èmi pẹ̀lú bá lè gbá èyíinì mú,+ èyí tí Kristi Jésù pẹ̀lú tìtorí rẹ̀ gbá mi mú.+ 13  Ẹ̀yin ará, èmi kò tíì ka ara mi sí ẹni tí ó ti gbá a mú nísinsìnyí; ṣùgbọ́n ohun kan wà nípa rẹ̀: Ní gbígbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn+ àti nínàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú,+ 14  mo ń lépa góńgó+ náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje+ ti ìpè Ọlọ́run sí òkè+ nípasẹ̀ Kristi Jésù. 15  Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí iye àwa tí a ti dàgbà dénú+ ní ẹ̀mí ìrònú yìí;+ bí ẹ bá sì ní èrò orí tí ó tẹ̀ sí ibòmíràn lọ́nà èyíkéyìí, Ọlọ́run yóò ṣí ẹ̀mí ìrònú tí ó wà lókè yìí payá fún yín. 16  Bí ó ti wù kí ó rí, dé àyè tí a ti tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní rírìn létòletò+ nínú ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan náà yìí. 17  Ẹ di aláfarawé+ mi ní ìsopọ̀ṣọ̀kan, ẹ̀yin ará, kí ẹ sì tẹ ojú yín mọ́ àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà tí ó bá àpẹẹrẹ tí ẹ rí nínú wa mu.+ 18  Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bẹ, mo ti máa ń mẹ́nu kàn wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n nísinsìnyí mo tún ń mẹ́nu kàn wọ́n pẹ̀lú ẹkún sísun, àwọn ẹni tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá òpó igi oró Kristi,+ 19  ìparun+ sì ni òpin wọn, ikùn+ wọn sì ni ọlọ́run wọn, ògo wọn sì wà nínú ìtìjú+ wọn, wọ́n sì gbé èrò inú wọn lé àwọn nǹkan orí ilẹ̀ ayé.+ 20  Ní tiwa, ẹ̀tọ́ wa gẹ́gẹ́ bí aráàlú+ ń bẹ ní ọ̀run,+ láti ibi tí a ti ń fi ìháragàgà dúró+ de olùgbàlà pẹ̀lú, Jésù Kristi Olúwa,+ 21  ẹni tí yóò ṣàtúndá ara+ wa tí a ti tẹ́ lógo, kí ó lè bá ara+ ológo tirẹ̀ ṣe déédéé gẹ́gẹ́ bí ìṣiṣẹ́+ agbára tí ó ní, àní láti fi ohun gbogbo sábẹ́+ ara rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé