Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Fílípì 2:1-30

2  Nígbà náà, bí ìṣírí èyíkéyìí bá wà nínú Kristi,+ bí ìtùnú onífẹ̀ẹ́ èyíkéyìí bá wà, bí àjọpín ẹ̀mí+ èyíkéyìí bá wà, bí àwọn ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́+ àti àwọn ìyọ́nú èyíkéyìí bá wà,  ẹ mú ìdùnnú mi kún ní ti pé ẹ ní èrò inú+ kan náà, ẹ sì ní ìfẹ́ kan náà, bí a ti so yín pọ̀ nínú ọkàn, kí ẹ ní ìrònú kan ṣoṣo nínú èrò inú+ yín,  láìṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀+ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ,+ ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù+ yín lọ,  kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn+ ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn+ pẹ̀lú.  Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù+ pẹ̀lú,  ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run,+ kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba.+  Ó tì o, ṣùgbọ́n ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú+ wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn.+  Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn,+ ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú,+ bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.+  Fún ìdí yìí gan-an pẹ̀lú ni Ọlọ́run fi gbé e sí ipò gíga,+ tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn,+ 10  kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀,+ 11  kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba+ pé Jésù Kristi ni Olúwa+ fún ògo Ọlọ́run Baba.+ 12  Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, lọ́nà tí ẹ ń gbà ṣègbọràn+ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n nísinsìnyí pẹ̀lú ìmúratán púpọ̀ sí i nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù+ àti ìwárìrì; 13  nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín,+ nítorí ti ìdùnnú rere rẹ̀, kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.+ 14  Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú+ àti ìjiyàn,+ 15  kí ẹ lè wá jẹ́ aláìlẹ́bi+ àti ọlọ́wọ́-mímọ́, àwọn ọmọ+ Ọlọ́run láìní àbààwọ́n láàárín ìran oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó,+ láàárín àwọn tí ẹ̀yin ń tàn bí atànmọ́lẹ̀ nínú ayé,+ 16  kí ẹ máa di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin,+ kí n lè ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ọjọ́ Kristi,+ pé n kò sáré lásán tàbí ṣiṣẹ́ kára lásán.+ 17  Láìka èyíinì sí, bí a bá tilẹ̀ ń tú mi jáde bí ọrẹ ẹbọ+ ohun mímu sórí ẹbọ+ àti iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn èyí tí ìgbàgbọ́ ti ṣamọ̀nà yín+ sí, mo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, mo sì bá gbogbo yín yọ̀.+ 18  Wàyí o, lọ́nà kan náà, ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀.+ 19  Ní tèmi, mo ní ìrètí nínú Jésù Olúwa láti rán Tímótì sí yín láìpẹ́, kí n lè jẹ́ ọkàn tí a mú lórí yá gágá+ nígbà tí mo bá mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín. 20  Nítorí èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀ tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó+ àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín. 21  Nítorí gbogbo àwọn yòókù ń wá ire ara wọn,+ kì í ṣe ti Kristi Jésù. 22  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ ẹ̀rí tí ó fúnni nípa ara rẹ̀, pé bí ọmọ+ lọ́dọ̀ baba ni ó sìnrú pẹ̀lú mi fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere. 23  Nítorí náà, èyí ni ọkùnrin tí mo ní ìrètí láti rán ní gbàrà tí mo bá ti rí bí àwọn nǹkan ṣe rí nípa mi. 24  Ní tòótọ́, mo ní ìgbọ́kànlé nínú Olúwa pé èmi fúnra mi yóò wá láìpẹ́.+ 25  Bí ó ti wù kí ó rí, mo kà á sí ohun tí ó pọndandan láti rán Ẹpafíródítù+ sí yín, arákùnrin mi àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀+ àti ọmọ ogun ẹlẹgbẹ́ mi,+ ṣùgbọ́n aṣojú yín àti ìránṣẹ́ ara ẹni fún àìní mi, 26  níwọ̀n bí aáyun ti ń yun ún láti rí gbogbo yín, ó sì soríkọ́ nítorí ẹ gbọ́ pé ó ti dùbúlẹ̀ àìsàn. 27  Bẹ́ẹ̀ ni, ní tòótọ́, ó dùbúlẹ̀ àìsàn títí ó fi fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ojú ikú; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣàánú+ fún un, ní ti tòótọ́, kì í ṣe fún òun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi pẹ̀lú, kí n má bàa ní ẹ̀dùn-ọkàn lórí ẹ̀dùn-ọkàn. 28  Nítorí náà, pẹ̀lú ìṣekánkán ńláǹlà ni mo ń rán an, kí ẹ lè yọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i nígbà tí ẹ bá rí i, kí èmi sì lè túbọ̀ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀dùn-ọkàn. 29  Nítorí náà, ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà á+ gẹ́gẹ́ bí àṣà nínú Olúwa pẹ̀lú ìdùnnú gbogbo; ẹ sì máa ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n,+ 30  nítorí pé ní tìtorí iṣẹ́ Olúwa ni ó fi sún mọ́ bèbè ikú, ó fi ọkàn rẹ̀ wewu,+ kí òun ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lè dí àlàfo àìsí níhìn-ín yín láti ṣe iṣẹ́ ìsìn ti ara ẹni fún mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé