Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Fílípì 1:1-30

1  Pọ́ọ̀lù àti Tímótì, ẹrú+ Kristi Jésù, sí gbogbo ẹni mímọ́ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, tí wọ́n wà ní ìlú Fílípì,+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn alábòójútó àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́:+  Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa.+  Nígbà gbogbo ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín+  nínú gbogbo ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún gbogbo yín,+ bí mo ti ń ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi pẹ̀lú ìdùnnú,  nítorí ìrànlọ́wọ́ fún ìtìlẹyìn+ tí ẹ ti ṣe fún ìhìn rere láti ọjọ́ àkọ́kọ́ títí di ìṣẹ́jú yìí.  Nítorí mo ní ìgbọ́kànlé nípa ohun yìí gan-an, pé ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín yóò ṣe é dé ìparí+ títí di ọjọ́+ Jésù Kristi.  Ó tọ̀nà pátápátá fún mi láti ronú èyí nípa gbogbo yín, ní tìtorí níní tí mo ní yín nínú ọkàn-àyà+ mi, níwọ̀n bí gbogbo yín ti jẹ́ alájọpín+ pẹ̀lú mi nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí náà, nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n+ mi àti nínú gbígbèjà+ àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin.+  Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi nípa bí mo ti ń ṣàfẹ́rí gbogbo yín nínú irúfẹ́ ìfẹ́ni+ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Kristi Jésù ní.  Èyí sì ni ohun tí mo ń bá a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi+ síwájú àti síwájú pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye+ àti ìfòyemọ̀ kíkún;+ 10  pé kí ẹ lè máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,+ kí ẹ lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n,+ kí ẹ má sì máa mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀+ títí di ọjọ́ Kristi, 11  kí ẹ sì lè kún fún èso òdodo,+ èyí tí í ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.+ 12  Wàyí o, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ẹ̀yin ará, pé àwọn àlámọ̀rí mi ti yọrí sí ìlọsíwájú ìhìn rere+ dípò kí ó jẹ́ òdì-kejì, 13  tí ó fi jẹ́ pé àwọn ìdè+ mi ti di mímọ̀+ fún gbogbo ènìyàn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi láàárín gbogbo Ẹ̀ṣọ́ Ọba àti gbogbo àwọn yòókù;+ 14  púpọ̀ jù lọ lára àwọn ará nínú Olúwa, tí wọ́n ní ìgbọ́kànlé nítorí àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi, sì túbọ̀ ń fi ìgboyà púpọ̀ sí i hàn láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù.+ 15  Lóòótọ́, àwọn kan ń wàásù Kristi ní tìtorí ìlara àti ìbánidíje,+ ṣùgbọ́n àwọn mìíràn pẹ̀lú ní tìtorí ìfẹ́ rere.+ 16  Àwọn ti ìkẹyìn yìí ń kéde Kristi láti inú ìfẹ́, nítorí wọ́n mọ̀ pé a fi mí sí ìhín nítorí ìgbèjà+ ìhìn rere; 17  ṣùgbọ́n àwọn ti ìṣáájú ń ṣe é láti inú ẹ̀mí asọ̀,+ kì í ṣe pẹ̀lú ète mímọ́ gaara, nítorí wọ́n rò pé àwọn lè ru ìpọ́njú+ sókè fún mi nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi. 18  Kí wá ni? Asán, àyàfi pé ní gbogbo ọ̀nà, yálà nínú ìdíbọ́n+ tàbí ní òtítọ́, Kristi ni a ń kéde,+ èmi sì yọ̀ nínú èyí. Ní ti tòótọ́, ṣe ni èmi yóò tún máa bá a nìṣó ní yíyọ̀, 19  nítorí mo mọ̀ pé èyí yóò yọrí sí ìgbàlà mi nípasẹ̀ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀+ yín àti ìpèsè ẹ̀mí Jésù Kristi,+ 20  ní ìbámu pẹ̀lú ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà+ àti ìrètí+ mi pé ojú kì yóò tì mí+ lọ́nà èyíkéyìí, ṣùgbọ́n pé nínú gbogbo òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ,+ Kristi ni a óò gbé ga lọ́lá lọ́nà bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń fi ìgbà gbogbo jẹ́ tẹ́lẹ̀, nípasẹ̀ ara mi,+ yálà nípasẹ̀ ìyè tàbí nípasẹ̀ ikú.+ 21  Nítorí nínú ọ̀ràn mi, láti wà láàyè jẹ́ Kristi,+ àti láti kú,+ èrè. 22  Wàyí o, bí ó bá jẹ́ láti máa wà láàyè lọ nínú ẹran ara, èyí jẹ́ èso iṣẹ́ mi+—síbẹ̀ èyí tí èmi yóò yàn ni èmi kò sì sọ di mímọ̀. 23  Nǹkan méjì wọ̀nyí+ ni ó ń kò ìdààmú bá mi; ṣùgbọ́n ohun tí mo fẹ́ ni ìtúsílẹ̀ àti wíwà pẹ̀lú Kristi,+ nítorí, láìsí àní-àní, èyí sàn púpọ̀púpọ̀ jù.+ 24  Àmọ́ ṣá o, fún mi láti dúró nínú ẹran ara pọndandan jù ní tìtorí yín.+ 25  Nítorí náà, bí mo ti ní ìgbọ́kànlé nípa èyí, mo mọ̀ pé èmi yóò dúró,+ èmi yóò sì bá gbogbo yín gbé fún ìlọsíwájú+ yín àti ìdùnnú tí ó jẹ́ ti ìgbàgbọ́ yín, 26  kí ayọ̀ ńláǹlà yín lè kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú Kristi Jésù nítorí mi nípasẹ̀ wíwà mi lọ́dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí i. 27  Kìkì pé kí ẹ máa hùwà lọ́nà tí ó yẹ+ ìhìn rere nípa Kristi, kí ó lè jẹ́ pé, yálà mo wá wò yín tàbí n kò wá, kí n lè máa gbọ́ nípa àwọn ohun tí ó kàn yín, pé ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú ẹ̀mí kan, pẹ̀lú ọkàn+ kan tí ẹ ń làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ fún ìgbàgbọ́ ìhìn rere, 28  tí àwọn tí ó kọjú ìjà sí yín kò sì kó jìnnìjìnnì bá yín lọ́nàkọnà.+ Ohun yìí gan-an ni ẹ̀rí ìparun fún wọn, ṣùgbọ́n ti ìgbàlà fún yín;+ ìtọ́ka yìí sì wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, 29  nítorí ẹ̀yin ni a fún ní àǹfààní náà nítorí Kristi, kì í ṣe láti ní ìgbàgbọ́+ nínú rẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n láti jìyà+ nítorí rẹ̀ pẹ̀lú. 30  Nítorí ẹ̀yin ní irú ìjàkadì kan náà tí ẹ rí nínú ọ̀ràn+ mi, tí ẹ sì ń gbọ́ nísinsìnyí nípa rẹ̀ nínú ọ̀ràn+ mi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé