Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Fílémónì 1:1-25

1  Pọ́ọ̀lù, ẹlẹ́wọ̀n+ nítorí Kristi Jésù, àti Tímótì,+ arákùnrin wa, sí Fílémónì, olùfẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀,+  àti sí Áfíà, arábìnrin wa, àti sí Ákípọ́sì,+ ọmọ ogun ẹlẹgbẹ́ wa,+ àti sí ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ:+  Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa.+  Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi nígbà tí mo bá ń dárúkọ rẹ nínú àwọn àdúrà mi,+  bí mo ti ń gbọ́ ṣáá nípa ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ rẹ, tí ìwọ ní sí Jésù Olúwa àti sí gbogbo ẹni mímọ́;+  kí ṣíṣe àjọpín ìgbàgbọ́ rẹ+ bàa lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nípa jíjẹ́wọ́ tí o bá ń jẹ́wọ́ mímọ gbogbo ohun tí ó dára láàárín wa bí ó ti ní í ṣe pẹ̀lú Kristi.  Nítorí mo ní ìdùnnú àti ìtùnú nípa ìfẹ́ rẹ,+ nítorí pé ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àwọn ẹni mímọ́ ni a ti sọ dọ̀tun+ nípasẹ̀ rẹ, arákùnrin.  Fún ìdí yìí gan-an, bí mo tilẹ̀ ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi láti pa àṣẹ+ fún ọ láti ṣe ohun tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,  kàkà bẹ́ẹ̀, mo ń gbà ọ́ níyànjú nítorí ìfẹ́,+ ní rírí i pé mo jẹ́ irú ẹni tí mo jẹ́, Pọ́ọ̀lù àgbàlagbà, bẹ́ẹ̀ ni, nísinsìnyí ẹlẹ́wọ̀n+ pẹ̀lú nítorí Kristi Jésù; 10  mo ń gbà ọ́ níyànjú nípa ọmọ mi,+ Ónẹ́símù,+ ẹni tí mo di baba+ fún nígbà tí mo wà nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi, 11  tẹ́lẹ̀ rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó wúlò fún ìwọ àti fún èmi.+ 12  Ẹni yìí gan-an ni mo ń rán padà wá bá ọ, bẹ́ẹ̀ ni, òun, èyíinì ni, ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tèmi.+ 13  Èmi ì bá fẹ́ láti dá a dúró fún ara mi pé ní ipò rẹ+ kí ó lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣe ìránṣẹ́ fún mi nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n+ tí mo ń mú mọ́ra nítorí ìhìn rere. 14  Ṣùgbọ́n láìsí ìfohùnṣọ̀kan rẹ, èmi kò fẹ́ láti ṣe ohunkóhun, kí ìṣe rẹ dídára má bàa jẹ́ bí ẹni pé lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe láti inú ìfẹ́ àtinúwá ti ìwọ fúnra rẹ.+ 15  Ní ti gidi, bóyá ní tìtorí èyí ni ó fi sá kúrò fún wákàtí kan, kí ìwọ lè gbà á padà títí láé, 16  kì í tún ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú+ mọ́ ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ju ẹrú lọ,+ gẹ́gẹ́ bí arákùnrin olùfẹ́ ọ̀wọ́n,+ ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì fún mi, síbẹ̀ mélòómélòó ni ó fi túbọ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ọ nínú ìbátan nípa ti ara àti nínú Olúwa. 17  Nítorí náà, bí o bá kà mí sí alájọpín,+ fi inú rere gbà á+ bí ìwọ yóò ti gbà mí. 18  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ó bá ti ṣe àìtọ́ èyíkéyìí sí ọ tàbí tí ó jẹ ọ́ ní gbèsè ohunkóhun, ka èyí sí mi lọ́rùn. 19  Èmi Pọ́ọ̀lù ni mo ń fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé:+ Èmi yóò san án padà—láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ fún ọ pé, yàtọ̀ sí èyíinì, ìwọ jẹ mí ní gbèsè ara rẹ pàápàá. 20  Bẹ́ẹ̀ ni, arákùnrin, kí n rí èrè láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa: sọ ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ mi dọ̀tun+ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi. 21  Ní gbígbẹ́kẹ̀lé ìfohùnṣọ̀kan rẹ, mo ń kọ̀wé sí ọ, ní mímọ̀ pé ìwọ yóò tilẹ̀ ṣe ju àwọn ohun tí mo wí.+ 22  Ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú èyíinì, pèsè ibùwọ̀+ sílẹ̀ fún mi pẹ̀lú, nítorí mo ní ìrètí pé nípasẹ̀ àwọn àdúrà yín,+ a óò dá mi sílẹ̀ lómìnira+ fún yín. 23  Epafírásì+ òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù kí yín, 24  bákan náà ni Máàkù, Àrísítákọ́sì,+ Démà,+ Lúùkù, àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi. 25  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ fi hàn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé