Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 9:1-29

9  “Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, ìwọ ń sọdá Jọ́dánì+ lónìí, láti wọlé lọ, láti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi jù ọ́,+ tí wọ́n sì lágbára ńlá jù ọ́ lọ kúrò, àwọn ìlú ńlá tí ó tóbi, tí a sì mọdi wọn kan ọ̀run,+  àwọn ènìyàn títóbi, tí wọ́n sì ga, àwọn ọmọ Ánákímù,+ àwọn ẹni tí ìwọ fúnra rẹ ti mọ̀, tí ìwọ fúnra rẹ sì ti gbọ́, tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ta ní lè mú ìdúró gbọn-in gbọn-in níwájú àwọn ọmọ Ánákì?’  O sì mọ̀ dáadáa lónìí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń sọdá níwájú rẹ.+ Iná tí ń jóni run ni.+ Òun yóò pa wọ́n rẹ́ ráúráú,+ òun fúnra rẹ̀ yóò sì tẹ̀ wọ́n lórí ba níwájú rẹ; kí ìwọ sì lé wọn kúrò, kí o sì fi ìyára kánkán pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún ọ gan-an.+  “Má ṣe sọ nínú ọkàn-àyà rẹ, nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá tì wọ́n kúrò níwájú rẹ pé, ‘Ní tìtorí òdodo tèmi fúnra mi ni Jèhófà fi mú mi wá láti gba ilẹ̀+ yìí,’ nígbà tí ó jẹ́ pé ní tìtorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Jèhófà yòó ṣe lé wọn kúrò níwájú rẹ.+  Kì  í ṣe ní tìtorí òdodo+ rẹ tàbí ní tìtorí ìdúróṣánṣán ọkàn-àyà+ rẹ ni ìwọ yóò fi wọlé lọ láti gba ilẹ̀ wọn; ní ti tòótọ́, ní tìtorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi lé wọn kúrò níwájú rẹ,+ àti kí a lè mú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá yín, Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Jékọ́bù+ ṣẹ.  Kí o sì mọ̀ pé kì í ṣe ní tìtorí òdodo rẹ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ ní ilẹ̀ dáradára yìí láti gbà á; nítorí ènìyàn ọlọ́rùn líle+ ni ọ́.  “Rántí: Má gbàgbé bí o ti tán Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní sùúrù ní aginjù.+ Láti ọjọ́ tí o ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì títí di ìgbà tí ẹ dé ibí yìí ni ẹ ti jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ nínú ìwà híhù yín sí Jèhófà.+  Àní ní Hórébù pàápàá, ẹ sún Jèhófà bínú tó bẹ́ẹ̀ tí ìbínú Jèhófà fi ru sókè sí yín títí dé orí pípa yín rẹ́ ráúráú.+  Nígbà tí mo gòkè lọ sórí òkè ńlá láti lọ gba àwọn wàláà òkúta,+ àwọn wàláà májẹ̀mú tí Jèhófà bá yín dá,+ tí mo sì ń bá a nìṣó láti gbé ní òkè ńlá náà fún ogójì  ọ̀sán àti ogójì  òru,+ (èmi kò jẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu omi,) 10  lẹ́yìn náà, Jèhófà fún mi ní àwọn wàláà òkúta méjì  tí a fi ìka+ Ọlọ́run kọ̀wé sí; ara wọn sì ni gbogbo ọ̀rọ̀ náà wà, èyí tí Jèhófà bá yín sọ ní òkè ńlá náà, láti àárín iná wá, ní ọjọ́ ìpéjọ.+ 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ní òpin ogójì  ọ̀sán àti ogójì  òru náà, Jèhófà fún mi ní wàláà òkúta méjì , àwọn wàláà májẹ̀mú+ náà; 12  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún mi pé, ‘Dìde, tètè sọ̀ kalẹ̀ kúrò níhìn-ín, nítorí àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde kúrò ní Íjíbítì ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun.+ Wọ́n ti yà kúrò kíákíá ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn. Wọ́n ti ṣe ère dídà+ fún ara wọn.’ 13  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ èyí fún mi pé, ‘Mo ti rí àwọn ènìyàn yìí, sì wò ó! ọlọ́rùn líle ènìyàn+ ni wọ́n. 14  Jọ̀wọ́ mí jẹ́ẹ́, kí n lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú,+ kí n sì nu orúkọ wọn kúrò lábẹ́ ọ̀run,+ sì jẹ́ kí n ṣe ọ́ ní orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ alágbára ńlá àti elénìyàn púpọ̀ jù wọ́n lọ.’+ 15  “Lẹ́yìn náà, mo yí padà, mo sì sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè ńlá náà, nígbà tí iná+ ń jó òkè ńlá náà; àwọn wàláà méjì  ti májẹ̀mú náà sì wà ní ọwọ́+ mi méjèèjì . 16  Nígbà náà ni mo wò, sì kíyè sí i, ẹ ti ṣẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run yín! Ẹ ti ṣe ọmọ màlúù dídà+ fún ara yín. Ẹ ti yà kúrò kíákíá ní ọ̀nà tí Jèhófà pa láṣẹ fún yín.+ 17  Látàrí èyí, mo di wàláà méjèèjì  mú, mo sì fi ọwọ́ mi méjèèjì  là wọ́n mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn túútúú lójú yín.+ 18  Èmi fúnra mi sì bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀ níwájú Jèhófà, bí ti àkọ́kọ́, ní ogójì  ọ̀sán àti ogójì  òru. Èmi kò jẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu omi,+ nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín tí ẹ dá, ní ṣíṣe ibi ní ojú Jèhófà, kí ẹ bàa lè mú un bínú.+ 19  Nítorí àyà fò mí ní tìtorí ìbínú gbígbóná tí Jèhófà fi mú ìkannú ru sí yín títí dé orí pípa yín rẹ́ ráúráú.+ Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà fetí sí mi ní àkókò+ yẹn pẹ̀lú. 20  “Áárónì, pẹ̀lú, ni ìbínú Jèhófà ru sókè sí gidigidi títí dé orí pípa á+ rẹ́ ráúráú; ṣùgbọ́n mo tún rawọ́ ẹ̀bẹ̀+ ní tìtorí Áárónì ní àkókò yẹn gan-an. 21  Ẹ̀ṣẹ̀ yín tí ẹ sì ṣẹ̀, ọmọ màlúù+ náà, ni mo mú, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sun ún nínú iná, tí mo sì fọ́ ọ túútúú, ní lílọ̀ ọ́ kúnnákúnná títí ó fi di lẹ́búlẹ́bú bí ekuru; lẹ́yìn èyí tí mo da ekuru rẹ̀ sínú ọ̀gbàrá tí ń ṣàn wálẹ̀ láti orí òkè ńlá+ náà. 22  “Síwájú sí i, ní Tábérà+ àti ní Másà+ àti ní Kiburoti-hátááfà,+ ẹ fi ara yín hàn ní olùtán Jèhófà ní sùúrù dé orí ìbínú.+ 23  Nígbà tí Jèhófà sì rán yín jáde kúrò ní Kadeṣi-bánéà+ pé, ‘Ẹ gòkè lọ láti gba ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún yín dájúdájú!’ nígbà náà ni ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà Ọlọ́run+ yín, ẹ kò sì lo ìgbàgbọ́+ nínú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò fetí sí ohùn+ rẹ̀. 24  Ẹ ti fi ara yín hàn ní ọlọ̀tẹ̀ nínú ìwà híhù sí Jèhófà,+ láti ọjọ́ tí mo ti mọ̀ yín. 25  “Èmi fúnra mi ń bá a nìṣó ní wíwólẹ̀ níwájú Jèhófà fún ogójì  ọ̀sán àti ogójì  òru,+ mo wólẹ̀ lọ́nà yìí nítorí tí Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa pípa yín rẹ́ ráúráú.+ 26  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rawọ́ ẹ̀bẹ̀+ sí Jèhófà, mo sì wí pé, ‘Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, má ṣe run àwọn ènìyàn rẹ, àní dúkìá+ àdáni rẹ, àwọn ẹni tí o fi títóbi rẹ tún rà padà, àwọn ẹni tí o fi ọwọ́ líle+ mú jáde kúrò ní Íjíbítì.+ 27  Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.+ Má ṣe yí ojú rẹ sí líle tí àwọn ènìyàn yìí lé àti ìwà burúkú wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn,+ 28  kí ilẹ̀+ tí o ti mú wa jáde má bàa wí pé: “Nítorí tí Jèhófà kò lè mú wọn dé ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn, àti nítorí tí ó kórìíra wọn, ni ó ṣe mú wọn jáde láti fi ikú pa wọ́n nínú aginjù.”+ 29  Àwọn, pẹ̀lú, jẹ́ ènìyàn rẹ àti dúkìá+ àdáni rẹ tí o fi agbára rẹ títóbi àti apá rẹ nínà jáde+ mú jáde.’

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé