Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 8:1-20

8  “Gbogbo àṣẹ tí mo ń pa fún ọ lónìí ni kí ẹ kíyè sára láti pa mọ́,+ kí ẹ bàa lè máa bá a lọ ní wíwà láàyè,+ kí ẹ sì di púpọ̀ sí i ní tòótọ́, kí ẹ sì wọlé lọ gba ilẹ̀ tí Jèhófà búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá yín.+  Kí o sì máa rántí gbogbo ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ mú ọ rìn ní aginjù+ fún ogójì ọdún wọ̀nyí, kí ó lè rẹ̀ ọ́ sílẹ̀,+ láti dán ọ wò,+ kí ó lè mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn-àyà+ rẹ, ní ti bóyá ìwọ yóò pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.  Nítorí náà, ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, ó sì jẹ́ kí ebi pa ọ́,+ ó sì fi mánà+ bọ́ ọ, èyí tí ìwọ kò mọ̀, tí àwọn baba rẹ kò sì mọ̀; kí a lè mú ọ mọ̀ pé ènìyàn kì í tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà ni ènìyàn fi ń wà láàyè.+  Aṣọ àlàbora rẹ kò gbó mọ́ ọ lára, bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ rẹ kò wú ní ogójì ọdún+ wọ̀nyí.  O sì mọ̀ dáadáa nínú ọkàn-àyà ìwọ fúnra rẹ pé, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti í tọ́ ọmọ rẹ̀ sọ́nà ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń tọ́ ọ sọ́nà.+  “Kí o sì pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, nípa rírìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀+ àti nípa bíbẹ̀rù rẹ̀.+  Nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ lọ sí ilẹ̀+ tí ó dára, ilẹ̀ tí ó ní àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá tí ó ní omi, tí àwọn ìsun àti àwọn ibú omi ń jáde wá láti inú pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì + àti láti inú ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá,  ilẹ̀ àlìkámà àti ọkà bálì àti àjàrà àti ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì,+ ilẹ̀ òróró ólífì àti oyin,+  ilẹ̀ tí ìwọ kò ti ní jẹ oúnjẹ ní àìrító, nínú èyí tí ìwọ kò ní ṣaláìní nǹkan kan, ilẹ̀ tí àwọn òkúta rẹ̀ jẹ́ irin àti láti inú àwọn òkè ńlá rẹ̀ ni ìwọ yóò ti máa wa bàbà. 10  “Nígbà tí ìwọ bá jẹun yó+ tán, kí o fi ìbùkún+ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ nítorí ilẹ̀ tí ó dára tí ó fi fún ọ.+ 11  Ṣọ́ra rẹ, kí o má bàa gbàgbé+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, láti ṣàìpa àwọn àṣẹ rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ mọ́, tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí;+ 12  kí o má bàa jẹun yó ní ti tòótọ́, kí o sì kọ́ àwọn ilé dáradára, kí o sì máa gbé inú wọn+ ní ti tòótọ́, 13  kí ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti agbo ẹran rẹ sì pọ̀ sí i, kí fàdákà àti wúrà sì pọ̀ sí i fún ọ, kí gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ sì pọ̀ sí i; 14  kí ọkàn-àyà rẹ sì gbé sókè+ ní tòótọ́, kí o sì gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní tòótọ́, ẹni tí ó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, jáde kúrò ní ilé àwọn ẹrú;+ 15  ẹni tí ó mú ọ rìn gba inú aginjù+ ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù, tí ó ní àwọn ejò+ olóró àti àwọn àkekèé àti pẹ̀lú ìyàngbẹ ilẹ̀ tí kò ní omi kankan; ẹni tí ó mú omi jáde wá fún ọ láti inú akọ àpáta;+ 16  ẹni tí ó fi mánà+ bọ́ ọ nínú aginjù, èyí tí àwọn baba rẹ kò mọ̀, kí ó bàa lè rẹ̀ ọ́+ sílẹ̀ àti kí ó bàa lè dán ọ wò, kí ó sì lè ṣe rere fún ọ lẹ́yìnwá ọ̀la+ rẹ; 17  tí o sì wí nínú ọkàn-àyà rẹ pé, ‘Agbára tèmi fúnra mi àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá ọwọ́ tèmi fúnra mi ni ó ṣe ọlà yìí fún mi.’+ 18  Ìwọ sì gbọ́dọ̀ rántí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nítorí òun ni ẹni tí ó fi agbára fún ọ láti ní ọlà;+ kí ó bàa lè mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ, èyí tí ó búra fún àwọn baba ńlá rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí.+ 19  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ìwọ bá gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ́nrẹ́n, tí ìwọ sì rìn tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn ní ti tòótọ́, tí o sì sìn wọ́n, tí o sì tẹrí ba fún wọn, mo jẹ́rìí lòdì sí yín lónìí pé ẹ̀yin yóò ṣègbé+ pátápátá. 20  Bí ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà yóò pa run kúrò níwájú yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ṣe ṣègbé, nítorí pé ẹ̀yin kò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé