Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Diutarónómì 7:1-26

7  “Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín, nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tí o ń lọ, kí o lè gbà á,+ òun yóò sì mú àwọn orílẹ̀-èdè elénìyàn púpọ̀ kúrò níwájú rẹ,+ àwọn ọmọ Hétì+ àti àwọn Gẹ́gáṣì+ àti àwọn Ámórì+ àti àwọn ọmọ Kénáánì+ àti àwọn Pérísì+ àti àwọn Hífì+ àti àwọn ará Jébúsì,+ àwọn orílẹ̀-èdè méje tí wọ́n jẹ́ elénìyàn púpọ̀ àti alágbára ńlá jù ọ́ lọ.+  Dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì jọ̀wọ́ wọn fún ọ, ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn.+ Kí o má ṣe kùnà láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun.+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ bá wọn dá májẹ̀mú tàbí kí o fi ojú rere kankan hàn sí wọn.+  Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ bá wọn dána. Ọmọbìnrin rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi fún ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ sì ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú fún ọmọkùnrin rẹ.+  Nítorí òun yóò yí ọmọ rẹ padà láti má ṣe tọ̀ mí lẹ́yìn, dájúdájú, wọn yóò sì máa sin àwọn ọlọ́run mìíràn;+ ní tòótọ́, ìbínú Jèhófà yóò sì ru sí yín, dájúdájú, òun yóò sì pa ọ́ rẹ́ ráúráú ní wéréwéré.+  “Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, èyí ni ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe sí wọn: Kí ẹ bi àwọn pẹpẹ wọn wó,+ kí ẹ sì wó àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ wọn lulẹ̀,+ kí ẹ sì ké àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ wọn lulẹ̀,+ kí ẹ sì fi iná sun àwọn ère fífín wọn.+  Nítorí ènìyàn mímọ́ ni ìwọ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ Ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti yàn láti di ènìyàn rẹ̀, àkànṣe dúkìá, nínú gbogbo ènìyàn tí wọ́n wà lórí ilẹ̀.+  “Kì  í ṣe nítorí pé ẹ jẹ́ àwọn tí ó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo ènìyàn ni Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ni hàn sí yín, tí ó fi yàn yín,+ nítorí ẹ̀yin ni ẹ kéré jù lọ nínú gbogbo ènìyàn.+  Ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí níní tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín,+ àti nítorí pípa tí ó pa gbólóhùn ìbúra tí ó búra fún àwọn baba ńlá yín mọ́,+ ni Jèhófà fi fi ọwọ́ líle mú yín jáde,+ kí ó bàa lè tún ọ rà padà kúrò ní ilé àwọn ẹrú,+ kúrò ní ọwọ́ Fáráò ọba Íjíbítì.  Ìwọ sì mọ̀ dáadáa pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run tòótọ́,+ Ọlọ́run aṣeégbíyèlé,+ tí ń pa májẹ̀mú+ àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ ní ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ títí dé ẹgbẹ̀rún ìran,+ 10  ṣùgbọ́n tí ó ń san án padà ní ojú ẹni tí ó kórìíra rẹ̀ nípa pípa á run.+ Òun kì yóò lọ́ tìkọ̀ sí ẹni tí ó kórìíra rẹ̀; yóò san án padà fún un ní ojú rẹ̀. 11  Kí o sì pa àṣẹ àti àwọn ìlànà àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ tí èmi ń pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́ nípa títẹ̀lé wọn.+ 12  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nítorí pé ẹ ń bá a lọ ní fífetí sí ìpinnu ìdájọ́ wọ̀nyí, tí ẹ sì ń pa wọ́n mọ́, tí ẹ sì ń mú wọn ṣẹ,+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò máa pa májẹ̀mú+ àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ sí ọ, èyí tí ó búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá rẹ.+ 13  Dájúdájú, òun yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ, yóò sì bù kún+ ọ, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀,+ yóò sì bù kún èso ikùn+ rẹ àti èso ilẹ̀+ rẹ, ọkà rẹ àti wáìnì rẹ tuntun àti òróró rẹ, ọmọ àwọn abo màlúù rẹ àti àtọmọdọ́mọ agbo ẹran+ rẹ, lórí ilẹ̀ tí ó búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fi fún ọ.+ 14  Ìwọ yóò di alábùkún jù lọ nínú gbogbo ènìyàn.+ Kì yóò sí akọ kan tàbí abo kan nínú rẹ tí kì yóò ní ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí láàárín àwọn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ.+ 15  Dájúdájú, Jèhófà yóò sì mú àìsàn gbogbo kúrò lára rẹ; àti ní ti gbogbo òkùnrùn búburú ti Íjíbítì, tí o ti mọ̀,+ òun kì yóò mú wọ́n bá ọ, ní tòótọ́, yóò sì mú wọ́n bá gbogbo àwọn tí ó kórìíra rẹ. 16  Kí o sì run gbogbo ènìyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ+ tán. Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ káàánú fún wọn;+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ sin àwọn ọlọ́run wọn,+ nítorí pé ìyẹn yóò jẹ́ ìdẹkùn fún ọ.+ 17  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o wí nínú ọkàn-àyà rẹ pé, ‘Àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ elénìyàn púpọ̀ jù fún mi. Báwo ni ó ṣe lè ṣeé ṣe fún mi láti lé wọn lọ?’+ 18  ìwọ kò gbọ́dọ̀ fòyà wọn.+ Lọ́nàkọnà, kí o rántí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe sí Fáráò àti gbogbo ènìyàn Íjíbítì,+ 19  àwọn ìfihàn ẹ̀rí ìdánilójú títóbi tí ojú rẹ rí,+ àti àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu+ àti ọwọ́ líle+ àti apá nínà jáde+ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi mú ọ jáde.+ Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò ṣe ṣe sí gbogbo ènìyàn tí ń bẹ níwájú rẹ nìyẹn, àwọn tí ìwọ ń fòyà wọn.+ 20  Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì rán ẹ̀mí ìrẹ̀wẹ̀sì+ sí wọn pẹ̀lú, títí àwọn tí ó ṣẹ́ kù+ àti àwọn tí ń fi ara wọn pa mọ́ kúrò níwájú rẹ yóò fi ṣègbé. 21  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbọ̀n rìrì nítorí wọn, nítorí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà ní àárín rẹ,+ Ọlọ́run títóbi àti amúnikún-fún-ẹ̀rù.+ 22  “Dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì ti àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí kúrò níwájú rẹ díẹ̀díẹ̀.+ A kì yóò yọ̀ǹda fún ọ láti pa wọ́n rẹ́ kúrò kíákíá, kí àwọn ẹranko ẹhànnà pápá má bàa di púpọ̀ lòdì sí ọ. 23  Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì jọ̀wọ́ wọn fún ọ, ní tòótọ́, yóò sì fi ìlésá kìjokìjo ńláǹlà lé wọn sá kìjokìjo, títí a ó fi pa wọ́n rẹ́ ráúráú.+ 24  Dájúdájú, yóò sì fi àwọn ọba wọn lé ọ lọ́wọ́,+ kí o sì pa orúkọ wọn run kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ Ẹnikẹ́ni kì yóò mú ìdúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí ọ,+ títí ìwọ yóò fi pa wọ́n run pátápátá.+ 25  Ère fífín àwọn ọlọ́run wọn ni kí ẹ fi iná sun.+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ojú rẹ wọ fàdákà àti wúrà tí ó wà lára wọn,+ bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe mú un fún ara rẹ,+ kí ó má bàa di pé a dẹkùn mú ọ ní tòótọ́ nípasẹ̀ rẹ̀;+ nítorí ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ ni ó jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ. 26  Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ mú ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wá sínú ilé rẹ, kí ìwọ ní ti tòótọ́ sì wá di ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun bí rẹ̀. Kí o kórìíra rẹ̀ tẹ̀gbintẹ̀gbin, kí o sì ṣe họ́ọ̀ sí i pátápátá,+ nítorí tí ó jẹ́ ohun kan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé