Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Diutarónómì 6:1-25

6  “Wàyí ó, ìwọ̀nyí ni àṣẹ náà, ìlànà àti ìpinnu ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ láti fi kọ́ yín,+ kí ẹ lè pa wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ tí ẹ ń ré kọjá sí láti gbà;  kí o lè bẹ̀rù+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti pa gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ àti àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, èyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ, ìwọ àti ọmọ rẹ àti ọmọ-ọmọ rẹ,+ ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ, àti kí ọjọ́ rẹ lè di gígùn.+  Kí o sì fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì, kí o sì kíyè sára láti pa wọ́n mọ́,+ kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ+ àti kí ẹ lè di púpọ̀ gidigidi, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ ti ṣèlérí fún ọ+ gan-an, ní ti ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.  “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.+  Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ+ àti gbogbo ọkàn rẹ+ àti gbogbo okunra rẹ+ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.  Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ;+  kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ,+ kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀+ àti nígbà tí o bá dìde.  Kí ìwọ sì so wọ́n gẹ́gẹ́ bí àmì mọ́ ọwọ́ rẹ,+ kí wọ́n sì jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀já ìgbàjú láàárín ojú rẹ;+  kí ìwọ sì kọ wọ́n sára àwọn òpó ilẹ̀kùn ilé rẹ àti sára àwọn ẹnubodè rẹ.+ 10  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ní ìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ wá sínú ilẹ̀ tí ó búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù láti fi fún ọ,+ àwọn ìlú ńlá títóbi, tí wọ́n sì dára ní ìrísí, tí ìwọ kò tẹ̀ dó,+ 11  àti àwọn ilé tí ó kún fún àwọn ohun rere gbogbo, tí ìwọ kò sì fi nǹkan kún, àti àwọn ìkùdu tí a ti gbẹ́, tí ìwọ kò gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà àti igi ólífì tí ìwọ kò gbìn, ni ìwọ yóò sì jẹ ní àjẹtẹ́rùn,+ 12  ṣọ́ ara rẹ, kí o má bàa gbàgbé+ Jèhófà, ẹni tí ó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, jáde kúrò ní ilé àwọn ẹrú. 13  Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o bẹ̀rù,+ òun sì ni kí o máa sìn,+ orúkọ rẹ̀ sì ni kí o máa fi búra.+ 14  Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ rìn tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, èyíkéyìí nínú àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní gbogbo àyíká yín,+ 15  (nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí ó wà láàárín rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe,)+ kí ìbínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ má bàa ru sí ọ,+ òun yóò sì pa ọ́ rẹ́ ráúráú kúrò lórí ilẹ̀.+ 16  “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run yín wò,+ bí ẹ ti dán an wò ní Másà.+ 17  Kí ẹ rí i dájú pé ẹ pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín mọ́+ àti àwọn gbólóhùn ẹ̀rí+ rẹ̀ àti àwọn ìlànà+ rẹ̀, tí ó ti pa láṣẹ fún ọ.+ 18  Kí o sì ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó dára ní ojú Jèhófà, kí nǹkan bàa lè máa lọ dáadáa fún ọ,+ kí o sì lè wọ ibẹ̀ ní tòótọ́, kí o sì gba ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ+ nípa rẹ̀, 19  nípa títi gbogbo ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ṣèlérí.+ 20  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọmọ rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ ní ọjọ́ iwájú+ pé, ‘Kí ni àwọn gbólóhùn ẹ̀rí àti àwọn ìlànà àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run wa pa láṣẹ fún yín túmọ̀ sí?’ 21  nígbà náà ni kí o wí fún ọmọ rẹ pé, ‘A di ẹrú fún Fáráò ní Íjíbítì, ṣùgbọ́n Jèhófà tẹ̀ síwájú láti fi ọwọ́ líle mú wa jáde kúrò ní Íjíbítì.+ 22  Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà ń bá a nìṣó láti mú àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu+ títóbi, tí ó sì kún fún ìyọnu àjálù, wá sórí Íjíbítì, sórí Fáráò àti sórí gbogbo agbo ilé rẹ̀ ní ojú wa.+ 23  Ó sì mú wa jáde kúrò níbẹ̀, kí ó bàa lè mú wa wá síhìn-ín láti fún wa ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá wa+ nípa rẹ̀. 24  Nítorí náà, Jèhófà pàṣẹ fún wa, láti máa pa gbogbo ìlànà wọ̀nyí mọ́,+ láti bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run wa, fún ire wa nígbà gbogbo,+ kí a lè máa wà láàyè nìṣó gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí.+ 25  Yóò sì túmọ̀ sí òdodo fún wa,+ pé àwa kíyè sára láti pa gbogbo àṣẹ yìí mọ́ níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa gan-an.’+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé