Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 5:1-33

5  Mósè sì ń bá a lọ láti pe gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì wí fún wọn pé: “Ísírẹ́lì,+ ẹ gbọ́ àwọn ìlànà àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ tí mo ń sọ ní etí yín lónìí, kí ẹ sì kọ́ wọn, kí ẹ sì kíyè sára láti pa wọ́n mọ́.+  Jèhófà Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú kan ní Hórébù.+  Kì  í ṣe àwọn baba ńlá wa ni Jèhófà bá dá májẹ̀mú yìí, bí kò ṣe àwa, gbogbo àwa tí a wà láàyè níhìn-ín lónìí.  Ojúkojú ni Jèhófà bá yín sọ̀rọ̀ ní òkè ńlá náà láti àárín iná wá.+  Mo dúró láàárín Jèhófà àti ẹ̀yin ní àkókò yẹn gan-an+ láti sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún yín, (nítorí àyà ń fò yín ní tìtorí iná náà, ẹ kò sì gòkè lọ sórí òkè ńlá náà,)+ pé,  “‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ tí ó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé àwọn ẹrú.+  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run mìíràn níṣojú mi láé.+  “‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́+ fún ara rẹ, ìrísí èyíkéyìí+ tí ó dà bí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ọ̀run lókè tàbí tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀ tàbí tí ń bẹ nínú omi nísàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a mú ọ sìn wọ́n,+ nítorí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe+ ni mí, tí ń mú ìyà nítorí ìṣìnà àwọn baba wá sórí àwọn ọmọ àti sórí ìran kẹta àti sórí ìran kẹrin, ní ti àwọn tí ó kórìíra mi;+ 10  ṣùgbọ́n tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ìran ẹgbẹ̀rún ní ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ mi tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.+ 11  “‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò ní láárí,+ nítorí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tí ó lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò ní láárí.+ 12  “‘Ní pípa ọjọ́ sábáàtì mọ́, láti kà á sí ọlọ́wọ̀, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún ọ gan-an,+ 13  ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ ìsìn, ìwọ yóò sì ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ ní ọjọ́ mẹ́fà.+ 14  Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí,+ ìwọ tàbí ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin rẹ tàbí ẹrúkùnrin rẹ tàbí ẹrúbìnrin rẹ tàbí akọ màlúù rẹ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ tàbí ẹran agbéléjẹ̀ èyíkéyìí tí ó jẹ́ tìrẹ tàbí àtìpó rẹ tí ó wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ,+ kí ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ bàa lè sinmi bí ìwọ náà.+ 15  Kí ìwọ sì rántí pé o di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì tẹ̀ síwájú láti fi ọwọ́ líle àti apá nínà mú ọ jáde+ kúrò níbẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi pàṣẹ fún ọ láti máa bá a lọ ní pípa ọjọ́ sábáàtì mọ́.+ 16  “‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ,+ gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún ọ gan-an; kí àwọn ọjọ́ rẹ bàa lè gùn, kí nǹkan sì lè máa lọ dáadáa fún ọ+ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ. 17  “‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn.+ 18  “‘Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.+ 19  “‘Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.+ 20  “‘Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnìkejì  rẹ.+ 21  “‘Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ojú rẹ wọ aya ọmọnìkejì  rẹ.+ Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi ìmọtara-ẹni-nìkan ní ìfàsí-ọkàn sí ilé ọmọnìkejì  rẹ, pápá rẹ̀ tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì  rẹ.’+ 22  “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni Jèhófà sọ fún gbogbo ìjọ yín ní òkè ńlá náà láti àárín iná,+ àwọsánmà àti ìṣúdùdù nínípọn, pẹ̀lú ohùn rara, kò sì fi nǹkan kan kún un; lẹ́yìn èyí, ó wá kọ wọ́n sórí wàláà òkúta méjì , ó sì fi wọ́n fún mi.+ 23  “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ní gbàrà tí ẹ gbọ́ ohùn náà láti àárín òkùnkùn wá, nígbà tí iná ń jó ní òkè ńlá náà,+ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ mi, gbogbo olórí ẹ̀yà yín àti àwọn àgbà ọkùnrin yín. 24  Nígbà náà ni ẹ wí pé, ‘Kíyè sí i, Jèhófà Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ àti títóbi rẹ̀ hàn wá, àwa sì ti gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárín iná wá.+ Àwa ti rí i lónìí yìí pé Ọlọ́run lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀, kí ó sì máa wà láàyè nìṣó,+ ní ti tòótọ́. 25  Wàyí o, èé ṣe tí a ó fi kú, nítorí pé iná ńlá yìí lè jó wa run?+ Bí àwa bá tún ń gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa síwájú sí i, ó dájú pé àwa yóò kú.+ 26  Nítorí ta ni ó wà nínú gbogbo ẹran ara tí ó tíì gbọ́ ohùn Ọlọ́run alààyè+ tí ń sọ̀rọ̀ ní àárín iná gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ ọ, síbẹ̀ kí ó sì máa wà láàyè nìṣó? 27  Ìwọ fúnra rẹ, sún mọ́ ọn, kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa yóò sọ; ìwọ sì ni ẹni tí yóò sọ fún wa nípa gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa yóò sọ fún ọ,+ dájúdájú, àwa yóò sì fetí sílẹ̀, a ó sì ṣe é.’ 28  “Nítorí náà, Jèhófà gbọ́ ohùn ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ bá mi sọ̀rọ̀, Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé, ‘Mo ti gbọ́ ohùn ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn yìí, èyí tí wọ́n sọ fún ọ. Wọ́n ṣe dáadáa nínú gbogbo ohun tí wọ́n sọ.+ 29  Kì kì bí wọn yóò bá mú ọkàn-àyà wọn yìí dàgbà láti bẹ̀rù mi+ àti láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́+ nígbà gbogbo, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin!+ 30  Lọ sọ fún wọn pé: “Ẹ padà sí ilé, sínú àwọn àgọ́ yín.” 31  Kí ìwọ sì dúró sí ìhín pẹ̀lú mi, sì jẹ́ kí n sọ gbogbo àṣẹ àti àwọn ìlànà àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ tí ìwọ yóò fi kọ́ wọn+ àti èyí tí wọn yóò pa mọ́ ní ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún wọn láti gbà.’ 32  Kí ẹ sì kíyè sí àtiṣe gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún yín gan-an.+ Ẹ kò gbọ́dọ̀ yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+ 33  Gbogbo ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ rìn,+ kí ẹ bàa lè wà láàyè, kí ó sì lè dára fún yín,+ kí ẹ sì lè mú àwọn ọjọ́ yín gùn ní tòótọ́ ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin yóò gbà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé