Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 34:1-12

34  Nígbà náà ni Mósè bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ láti àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù sí Òkè Ńlá Nébò,+ sí orí Písígà,+ tí ó dojú kọ ìhà Jẹ́ríkò.+ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi gbogbo ilẹ̀ náà hàn án, Gílíádì títí dé Dánì,+  àti gbogbo Náfútálì àti ilẹ̀ Éfúráímù àti Mánásè àti gbogbo ilẹ̀ Júdà títí dé òkun ìwọ̀-oòrùn,+  àti Négébù+ àti Àgbègbè,+ pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì Jẹ́ríkò, ìlú ńlá àwọn igi ọ̀pẹ,+ títí dé Sóárì.+  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “Èyí ni ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé, ‘Irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi í fún.’+ Mo ti jẹ́ kí ìwọ fi ojú ara rẹ rí i, níwọ̀n bí ìwọ kì yóò ti sọdá sí ibẹ̀.”+  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà+ kú níbẹ̀ ní ilẹ̀ Móábù nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà.+  Ó sì tẹ̀ síwájú láti sin ín sínú àfonífojì ní ilẹ̀ Móábù ní iwájú Bẹti-péórù,+ kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ sàréè rẹ̀ títí di òní+ yìí.  Mósè sì jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà ikú rẹ̀.+ Ojú rẹ̀ kò di bàìbàì,+ okun agbẹ́mìíró rẹ̀ kò sì pòórá.+  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún Mósè ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù fún ọgbọ̀n ọjọ́.+ Níkẹyìn, sáà àwọn ọjọ́ ẹkún ìṣọ̀fọ̀ fún Mósè parí.  Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì sì kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n,+ nítorí Mósè ti gbé ọwọ́ lé e lórí;+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí fetí sí i, wọ́n sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ gan-an fún Mósè.+ 10  Ṣùgbọ́n kò tíì sí wòlíì kan rí, tí ó tíì dìde ní Ísírẹ́lì bí Mósè,+ ẹni tí Jèhófà mọ̀ lójúkojú,+ 11  ní ti gbogbo iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà fi rán an láti ṣe ní ilẹ̀ Íjíbítì sí Fáráò àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀+ rẹ̀, 12  àti ní ti gbogbo ọwọ́ líle àti gbogbo ìṣe oníbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ títóbi tí Mósè fi hàn lójú gbogbo Ísírẹ́lì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé