Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 33:1-29

33  Wàyí o, èyí ni ìre+ tí Mósè ènìyàn Ọlọ́run+ tòótọ́ sú fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣáájú ikú rẹ̀.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Jèhófà—Sínáì ni ó ti wá,+ Ó sì kọ mànà láti Séírì sára wọn.+ Ó tàn yanran wá láti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Páránì,+ Àwọn ẹgbẹẹgbàárùn-ún+ mímọ́ sì wà pẹ̀lú rẹ̀, Ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àwọn jagunjagun tí wọ́n jẹ́ tiwọn.+  Òun sì ń ṣìkẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀;+ Gbogbo ẹni mímọ́ wọn wà ní ọwọ́ rẹ.+ Àti àwọn—wọ́n rọ̀gbọ̀kú sí ẹsẹ̀ rẹ;+ Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbà lára àwọn ọ̀rọ̀ rẹ.+  (Mósè gbé òfin kan kà wá lórí gẹ́gẹ́ bí àṣẹ,+ Ohun ìní kan tí ó jẹ́ ti ìjọ Jékọ́bù.)+  Ó sì wá jẹ́ ọba ní Jéṣúrúnì,+ Nígbà tí àwọn olórí àwọn ènìyàn náà kó ara wọn jọ,+ Gbogbo iye àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì pátá.+  Kí Rúbẹ́nì yè, kí ó má sì kú run,+ Kí àwọn ọkùnrin rẹ̀ má sì di èyí tí ó kéré níye.”+  Èyí sì ni ìre ti Júdà,+ bí ó ti ń bá a lọ pé: “Ìwọ Jèhófà, gbọ́ ohùn Júdà,+ Kí o sì mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀.+ Apá rẹ̀ ti báni fà á nítorí ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀; Kí o sì fi ara rẹ hàn ní olùrànlọ́wọ́ fún un kúrò lọ́wọ́ àwọn elénìní rẹ̀.”  Àti ní ti Léfì, ó wí pé:+ “Túmímù rẹ àti Úrímù+ rẹ jẹ́ ti ọkùnrin tí ó jẹ́ adúróṣinṣin tì ọ́,+ Ẹni tí o dán wò ní Másà.+ O bẹ̀rẹ̀ sí bá a fà á lẹ́bàá omi Mẹ́ríbà,+  Ọkùnrin tí ó wí fún baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ pé, ‘Èmi kò rí i.’ Àní àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá ni òun kò kà sí,+ Kò sì mọ àwọn ọmọ rẹ̀. Nítorí wọ́n pa àsọjáde rẹ mọ́,+ Májẹ̀mú rẹ ni wọ́n sì ń bá a lọ láti máa pa mọ́.+ 10  Jẹ́ kí wọ́n fún Jékọ́bù ní ìtọ́ni nínú àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ+ Àti Ísírẹ́lì nínú òfin rẹ.+ Jẹ́ kí wọ́n sun tùràrí níwájú imú rẹ+ Àti odindi ọrẹ ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.+ 11  Bù kún ìmí rẹ̀, Jèhófà,+ Kí o sì fi ìdùnnú hàn sí ìgbòkègbodò ọwọ́ rẹ̀.+ Dá ọgbẹ́ yánnayànna sí ìgbáròkó àwọn ti ń dìde sí i,+ Àti sí àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀ lọ́nà gbígbóná janjan, kí wọ́n má bàa dìde.”+ 12  Ní ti Bẹ́ńjámínì, ó wí pé:+ “Kí olùfẹ́ ọ̀wọ́n+ Jèhófà máa gbé nínú ààbò lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ Bí ó tí pèsè ibi ààbò fún un ní ọjọ́ kan gbáko,+ Òun yóò sì máa gbé láàárín àwọn èjì ká rẹ̀.”+ 13  Àti ní ti Jósẹ́fù, ó wí pé:+ “Kí a máa bù kún ilẹ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo láti ọ̀dọ̀ Jèhófà+ Pẹ̀lú àwọn ohun ààyò ọ̀run, pẹ̀lú ìrì,+ Àti pẹ̀lú ibú omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ lábẹ́lẹ̀,+ 14  Àti pẹ̀lú àwọn ohun ààyò, àwọn ohun tí oòrùn mú jáde,+ Àti pẹ̀lú àwọn ohun ààyò, èso àwọn oṣù òṣùpá,+ 15  Àti pẹ̀lú àwọn ààyò jù lọ láti inú àwọn òkè ńlá ìlà-oòrùn,+ Àti pẹ̀lú àwọn ohun ààyò òkè kéékèèké tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin, 16  Àti pẹ̀lú àwọn ohun ààyò ilẹ̀ ayé àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀,+ Àti pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà Ẹni tí ń gbé nínú igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún.+ Kí wọ́n wá sí orí Jósẹ́fù+ Àti sí àtàrí ẹni tí a yọ sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn arákùnrin rẹ̀.+ 17  Bí àkọ́bí akọ màlúù ni ọlá ńlá rẹ̀ rí,+ Àwọn ìwo rẹ̀ sì jẹ́ àwọn ìwo akọ màlúù ìgbẹ́.+ Àwọn ni òun yóò fi taari àwọn ènìyàn+ Gbogbo wọn lápapọ̀ sí àwọn ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé, Àwọn sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá Éfúráímù,+ Àwọn sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè.” 18  Àti ní ti Sébúlúnì, ó wí pé:+ “Ìwọ Sébúlúnì, máa yọ̀ nínú jíjáde lọ rẹ,+ Àti, Ísákárì, nínú àwọn àgọ́ rẹ.+ 19  Wọn yóò máa pe àwọn ènìyàn lọ sórí òkè ńlá. Ibẹ̀ ni wọn yóò ti máa rú àwọn ẹbọ òdodo.+ Nítorí wọn yóò máa fa ọ̀pọ̀ jaburata ọlà àwọn òkun mu+ Àti àwọn àkójọ àlùmọ́ọ́nì tí ó fara sin nínú iyanrìn.” 20  Àti ní ti Gádì, ó wí pé:+ “Ìbùkún ni fún ẹni tí ń mú àwọn ibodè Gádì gbòòrò sí i.+ Bí kìnnìún ni kí ó máa gbé,+ Kí ó sì máa fa apá ya, bẹ́ẹ̀ ni, àtàrí.+ 21  Òun yóò sì mú apá àkọ́kọ́ fún ara rẹ̀,+ Nítorí ibẹ̀ ni a fi ìwọ̀n ìpín olùfúnni ní ìlànà àgbékalẹ̀ pa mọ́ sí.+ Àwọn olórí àwọn ènìyàn náà yóò sì kó ara wọn jọpọ̀. Òdodo Jèhófà ni òun yóò mú ṣẹ ní kíkún Àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì.” 22  Àti ní ti Dánì, ó wí pé:+ “Ọmọ kìnnìún ni Dánì.+ Òun yóò bẹ́ jáde láti Báṣánì.”+ 23  Àti ní ti Náfútálì, ó wí pé:+ “Náfútálì ni ìtẹ́wọ́gbà náà tẹ́ lọ́rùn Ó sì kún fún ìbùkún Jèhófà. Gba ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù ní ti gidi.”+ 24  Àti ní ti Áṣérì, ó wí pé:+ “A fi àwọn ọmọ bù kún Áṣérì.+ Kí ó di ẹni tí àwọn arákùnrin rẹ̀ tẹ́wọ́ gbà,+ Àti ẹni tí ń ti ẹsẹ̀ bọ inú òróró.+ 25  Irin àti bàbà ni àwọn àgádágodo ẹnubodè rẹ,+ Àti ní ìwọ̀n bí àwọn ọjọ́ rẹ ti tó ni ìrìn rẹ dẹrùn pẹ̀sẹ̀ tó. 26  Kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí Ọlọ́run+ tòótọ́ ti Jéṣúrúnì,+ Tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ+ Àti sánmà ṣíṣú dẹ̀dẹ̀ nínú ọlá ògo rẹ̀.+ 27  Ibi ìfarapamọ́ ni Ọlọ́run àtayébáyé náà,+ Àti nísàlẹ̀ ni àwọn apá tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin wà.+ Òun yóò sì lé ọ̀tá lọ kúrò níwájú rẹ,+ Òun yóò sì wí pé, ‘Pa wọ́n rẹ́ ráúráú!’+ 28  Ísírẹ́lì yóò sì máa gbé nínú ààbò,+ Ojúsun Jékọ́bù ní òun nìkan ṣoṣo,+ Lórí ilẹ̀ ọkà àti wáìnì tuntun.+ Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀run rẹ̀ yóò mú kí ìrì máa sẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ sílẹ̀.+ 29  Aláyọ̀ ni ìwọ, Ísírẹ́lì!+ Ta ni ó wà bí ìwọ,+ Àwọn ènìyàn tí ń gbádùn ìgbàlà nínú Jèhófà,+ Apata ìrànlọ́wọ́ rẹ,+ Àti Ẹni tí ó jẹ́ idà ọlọ́lá ògo rẹ?+ Nítorí náà, àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi ìwárìrì tẹrí ba níwájú rẹ,+ Àti ìwọ—orí àwọn ibi gíga wọn ni ìwọ yóò tẹ̀ mọ́lẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé