Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 32:1-52

32  “Fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run, sì jẹ́ kí n sọ̀rọ̀; Kí ilẹ̀ ayé sì gbọ́ àwọn àsọjáde ẹnu+ mi.  Ìtọ́ni mi yóò máa wẹ bí òjò,+ Àsọjáde mi yóò máa sẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bí ìrì,+ Bí òjò winniwinni sára koríko+ Àti bí ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò sára ewéko.+  Nítorí èmi yóò polongo orúkọ Jèhófà.+ Ẹ gbé ìtóbi fún Ọlọ́run wa ní ti gidi!+  Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀,+ Nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.+ Ọlọ́run ìṣòtítọ́,+ ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀;+ Olódodo àti adúróṣánṣán ni.+  Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun níhà ọ̀dọ̀ àwọn fúnra wọn;+ Wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀, àbùkù náà jẹ́ tiwọn.+ Ìran kan tí ó jẹ́ oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó!+  Ṣé Jèhófà ni ẹ̀yin ń ṣe báyìí sí,+ Ìwọ arìndìn ènìyàn tí kò gbọ́n?+ Òun ha kọ́ ni Baba rẹ tí ó mú ọ jáde,+ Ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ, tí ó sì mú ọ dúró gbọn-in gbọn-in?+  Rántí àwọn ọjọ́ láéláé,+ Ẹ ronú nípa àwọn ọdún tí ó ti kọjá láti ìran dé ìran; Béèrè lọ́wọ́ baba rẹ, ó sì lè sọ fún ọ;+ Àwọn àgbà rẹ, wọ́n sì lè sọ ọ́ fún ọ.+  Nígbà tí Ẹni Gíga Jù Lọ fún àwọn orílẹ̀-èdè ní ogún,+ Nígbà tí ó ya àwọn ọmọ Ádámù síra kúrò lọ́dọ̀ ara wọ́n lẹ́nì kìíní-kejì ,+ Ó bẹ̀rẹ̀ sí pa ààlà àwọn ènìyàn+ Pẹ̀lú àfiyèsí sí iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+  Nítorí ìpín Jèhófà ni àwọn ènìyàn rẹ̀;+ Jékọ́bù ni ìwọ̀n ìpín tí ó jogún.+ 10  Ó rí i ní ilẹ̀ aginjù,+ Àti nínú aṣálẹ̀ tí ó ṣófo, tí ń hu.+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí yí i ká,+ láti tọ́jú rẹ̀,+ Láti fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ bí ọmọlójú ojú rẹ̀.+ 11  Gan-an gẹ́gẹ́ bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ sókè, Ti í rà bàbà lókè àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀gúnyẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀,+ Ti í na àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀ jáde, ti í mú wọn, Ti í gbé wọn lọ lórí àwọn ìyẹ́ àfifò rẹ̀,+ 12  Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ń ṣamọ̀nà rẹ̀ nìṣó,+ Kò sì sí ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè kankan pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.+ 13  Ó ń mú kí ó gun orí àwọn ibi gíga ilẹ̀ ayé,+ Tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ń jẹ àwọn àmújáde pápá.+ Ó sì ń mú kí ó máa fa oyin mu láti inú àpáta gàǹgà,+ Àti òróró láti inú akọ àpáta;+ 14  Bọ́tà ọ̀wọ́ ẹran àti wàrà agbo ẹran+ Pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rá àwọn àgbò, Àti àwọn akọ àgùntàn, ẹ̀yà ti Báṣánì, àti àwọn òbúkọ+ Pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rá kíndìnrín àlìkámà;+ Àti ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà ni ìwọ ń mu ṣáá bí wáìnì.+ 15  Nígbà tí Jéṣúrúnì+ bẹ̀rẹ̀ sí sanra, ó wá ń tàpá.+ Ìwọ sanra, o ki, o wá kún pọ́pọ́.+ Nítorí náà, ó ṣá Ọlọ́run tí ó ṣe é tì,+ Ó sì tẹ́ńbẹ́lú Àpáta+ ìgbàlà rẹ̀. 16  Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn àjèjì  ọlọ́run+ ru ú lọ́kàn sókè sí owú;+ Àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ni wọ́n fi ń bà á nínú jẹ́ ṣáá.+ 17  Wọ́n ń bá a lọ láti máa rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe sí Ọlọ́run,+ Àwọn ọlọ́run tí wọn kò mọ̀,+ Àwọn tí ó jẹ́ tuntun, tí wọ́n wọlé lẹ́nu àìpẹ́ yìí,+ Àwọn tí kì í ṣe ojúlùmọ̀ àwọn baba ńlá yín. 18  Àpáta tí ó bí ọ ni ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàgbé,+ O sì bẹ̀rẹ̀ sí mú Ọlọ́run kúrò nínú ìrántí, Ẹni tí ó fi ìrora ìbímọ bí ọ.+ 19  Nígbà tí Jèhófà rí i, nígbà náà ni ó wá ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn,+ Nítorí ìbìnújẹ́ tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ fà. 20  Nítorí náà, ó wí pé, ‘Jẹ́ kí n fi ojú mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ Kí n rí ohun tí òpin wọn yóò jẹ́ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Nítorí wọ́n jẹ́ ìran àyídáyidà,+ Àwọn ọmọ tí kò sí ìṣòtítọ́ kankan nínú wọn.+ 21  Àwọn, ní tiwọn, ti fi ohun tí kì í ṣe ọlọ́run rárá ru mí lọ́kàn sókè sí owú;+ Wọ́n ti fi àwọn òrìṣà asán wọn mú mi bínú;+ Àti pé èmi, ní tèmi, yóò fi àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan rárá ru wọ́n lọ́kàn sókè sí owú;+ Orílẹ̀-èdè arìndìn ni èmi yóò fi mú wọ́n bínú.+ 22  Nítorí iná kan ni a ti mú ràn nínú ìbínú mi+ Yóò sì jó títí dé Ṣìọ́ọ̀lù, ibi ìsàlẹ̀ pátápátá,+ Yóò sì jó ilẹ̀ ayé àti èso rẹ̀+ Yóò sì ti iná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.+ 23  Èmi yóò mú àwọn ìyọnu àjálù pọ̀ sí i lórí wọn;+ Àwọn ọfà mi ni èmi yóò lò tán sí wọn lára.+ 24  Ebi yóò tán wọn lókun,+ ibà amáragbóná fòfò yóò sì jẹ wọ́n tán+ Àti ìparun kíkorò.+ Àti eyín àwọn ẹranko ni èmi yóò rán sára wọn,+ Pẹ̀lú oró ẹranko afàyàfà inú ekuru.+ 25  Ní òde, idà yóò mú kí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ wọ́n,+ Àti nínú ilé, jì nnìjì nnì,+ Àti ọ̀dọ́kùnrin àti wúńdíá pa pọ̀,+ Ọmọ ẹnu ọmú pa pọ̀ pẹ̀lú ènìyàn tí ó ti hewú.+ 26  Èmi ì bá ti wí pé: “Èmi yóò fọ́n wọn ká,+ Ṣe ni èmi yóò mú kí mímẹ́nu kàn wọ́n kásẹ̀ nílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ẹni kíkú,”+ 27  Bí kì í bá ṣe pé mo ń fòyà ìbìnújẹ́ láti ọ̀dọ̀ ọ̀tá,+ Pé àwọn elénìní wọn lè ṣì í túmọ̀,+ Pé wọ́n lè wí pé: “Ọwọ́ wa ti mókè,+ Kì  í sì í ṣe Jèhófà ni ó ṣe gbogbo èyí.”+ 28  Nítorí orílẹ̀-èdè kan tí ìmọ̀ràn ń ṣègbé lé lórí ni wọ́n,+ Kò sì sí òye kankan láàárín wọn.+ 29  Ì bá ṣe pé wọ́n gbọ́n!+ Nígbà náà, wọn ì bá fẹ̀sọ̀ ronú lórí èyí.+ Wọn ì bá ronú nípa òpin wọn ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.+ 30  Báwo ni ẹnì kan ṣe lè lépa ẹgbẹ̀rún, Kí ẹni méjì  sì mú kí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá fẹsẹ̀ fẹ?+ Kò lè rí bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe pé Àpáta wọn tà wọ́n+ Kí Jèhófà sì fi wọ́n léni lọ́wọ́. 31  Nítorí àpáta wọn kò dà bí Àpáta wa,+ Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀tá wa ni yóò pinnu.+ 32  Nítorí àjàrà wọn jẹ́ láti inú àjàrà Sódómù Àti láti inú ilẹ̀ onípele títẹ́jú ti Gòmórà.+ Àwọn èso àjàrà wọn jẹ́ ti èso àjàrà májèlé, Àwọn òṣùṣù wọn korò.+ 33  Wáìnì wọn jẹ́ oró àwọn ejò ńlá Àti májèlé olóró ti ṣèbé.+ 34  A kò ha tò ó jọ pa mọ́ sọ́dọ̀ mi, Ti òun ti èdìdì tí a fi sí i nínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ mi?+ 35  Tèmi ni ẹ̀san, àti ẹ̀san iṣẹ́.+ Ní àkókò tí a yàn kalẹ̀, ẹsẹ̀ wọn yóò rìn tàgétàgé,+ Nítorí ọjọ́ àjálù wọn sún mọ́lé,+ Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní ìmúrasílẹ̀ fún wọn sì ṣe kánkán ní ti gidi.’+ 36  Nítorí Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀+ Òun yóò sì kẹ́dùn nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,+ Nítorí òun yóò rí i pé ìtìlẹyìn ti dàwátì Kì kì aláìní olùrànlọ́wọ́ àti ẹni tí kò ní láárí ni ó sì wà. 37  Dájúdájú, òun yóò sì wí pé, ‘Ibo ni àwọn ọlọ́run wọn wà,+ Àpáta tí wọ́n wá ibi ìsádi lọ́dọ̀ rẹ̀,+ 38  Tí ó máa ń jẹ ọ̀rá ẹbọ wọn,+ Tí ó ń mu wáìnì ọrẹ ẹbọ ohun mímu wọn?+ Kí wọ́n dìde, kí wọ́n sì ràn yín lọ́wọ́.+ Kí wọ́n di ibi ìlùmọ́ fún yín.+ 39  Ẹ wò ó nísinsìnyí pé èmi—èmi ni ẹni náà+ Kò sì sí àwọn ọlọ́run kankan pa pọ̀ pẹ̀lú mi.+ Èmi ń fi ikú pani, mo sì ń sọni di ààyè.+ Mo ti dá ọgbẹ́ síni lára yánnayànna,+ èmi—èmi yóò sì múni lára dá,+ Kò sì sí ẹnì kankan tí ń já nǹkan gbà kúrò lọ́wọ́ mi.+ 40  Nítorí pé mo gbé ọwọ́ mi sókè sí ọ̀run ní ìbúra,+ Mo sì wí pé: “Bí mo ti ń bẹ láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin,”+ 41  Ní ti gidi, bí èmi bá pọ́n idà mi tí ń dán yinrinyinrin,+ Tí mo sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,+ Ṣe ni èmi yóò san ẹ̀san padà fún àwọn elénìní mi+ Èmi yóò sì san èrè iṣẹ́ fún àwọn tí wọ́n kórìíra mi lọ́nà gbígbóná janjan.+ 42  Èmi yóò mú kí ọfà mi mu ẹ̀jẹ̀ yó,+ Nígbà tí ó jẹ́ pé idà mi yóò jẹ ẹran,+ Pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa àti àwọn òǹdè, Pẹ̀lú orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.’+ 43  Ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀,+ Nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,+ Òun yóò sì san ẹ̀san padà fún àwọn elénìní rẹ̀+ Yóò sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ ní tòótọ́.” 44  Nípa báyìí, Mósè wá, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí ní etí-ìgbọ́ àwọn ènìyàn náà,+ òun àti Hóṣéà ọmọkùnrin Núnì.+ 45  Lẹ́yìn tí Mósè parí sísọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún gbogbo Ísírẹ́lì, 46  ó ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ láti fi kìlọ̀ fún yín lónìí,+ kí ẹ̀yin lè máa pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti máa kíyè sí pípa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin+ yìí mọ́. 47  Nítorí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí fún yín,+ ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí ìwàláàyè yín,+ àti pé nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni ẹ̀yin yóò mú ọjọ́ yín gùn lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń sọdá Jọ́dánì láti gbà.”+ 48  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún Mósè ní ọjọ́ yìí kan náà pé: 49  “Gun òkè ńlá Ábárímù+ yìí lọ, Òkè Ńlá Nébò,+ tí ó wà ní ilẹ̀ Móábù, tí ó dojú kọ Jẹ́ríkò, kí o sì wo ilẹ̀ Kénáánì, tí èmi yóò fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.+ 50  Lẹ́yìn náà, kí o kú sórí òkè ńlá tí ìwọ ń gùn lọ, kí a sì kó ọ jọpọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Áárónì arákùnrin rẹ ti kú sórí Òkè Ńlá Hóórì,+ tí a sì kó o jọpọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀; 51  fún ìdí náà pé ẹ̀yin hùwà sí mi+ lọ́nà àìfinipè láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níbi omi Mẹ́ríbà+ ti Kádéṣì ní aginjù Síínì; fún ìdí náà pé ẹ̀yin kò sọ mi di mímọ́ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 52  Nítorí láti òkèèrè ni ìwọ yóò ti rí ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lọ sí ibẹ̀, sórí ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé