Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 31:1-30

31  Lẹ́yìn náà, Mósè lọ sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún gbogbo Ísírẹ́lì  ó sì wí fún wọn pé: “Ẹni ọgọ́fà ọdún ni mí lónìí.+ A kì yóò tún gbà mí láyè mọ́ láti máa jáde àti láti máa wọlé,+ níwọ̀n bí Jèhófà ti wí fún mi pé, ‘Ìwọ kì yóò sọdá Jọ́dánì+ yìí.’  Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ẹni tí ń sọdá níwájú rẹ.+ Òun fúnra rẹ̀ yóò pa àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí rẹ́ ráúráú kúrò níwájú rẹ, ìwọ yóò sì lé wọn lọ.+ Jóṣúà ni ẹni tí yóò sọdá níwájú rẹ,+ gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ gan-an.  Dájúdájú, Jèhófà yóò sì ṣe sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Síhónì+ àti sí Ógù,+ àwọn ọba Ámórì, àti sí ilẹ̀ wọn, nígbà tí ó pa wọ́n rẹ́ ráúráú.+  Jèhófà sì ti jọ̀wọ́ wọn fún yín,+ kí ẹ̀yin sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí gbogbo àṣẹ tí mo ti pa fún yín.+  Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára.+ Má fòyà tàbí kí o gbọ̀n rìrì níwájú wọn,+ nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ẹni tí ń bá ọ lọ. Òun kì yóò kọ̀ ọ́ tì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá.”+  Mósè sì tẹ̀ síwájú láti pe Jóṣúà, ó sì wí fún un lójú gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ nítorí pé ìwọ—ìwọ ni yóò mú àwọn ènìyàn yìí wọ ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wọn láti fi fún wọn, ìwọ fúnra rẹ ni yóò sì fi í fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún.+  Jèhófà sì ni ẹni tí ń lọ níwájú rẹ. Òun fúnra rẹ̀ ni yóò máa wà pẹ̀lú rẹ nìṣó.+ Òun kì yóò kọ̀ ọ́ tì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá. Má fòyà tàbí kí o jáyà.”+  Lẹ́yìn náà, Mósè kọ̀wé òfin+ yìí, ó sì fi í fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn olùru àpótí májẹ̀mú+ Jèhófà, àti fún gbogbo àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì. 10  Mósè sì ń bá a lọ láti pàṣẹ fún wọn pé: “Ní òpin ọdún méje-méje, ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ nínú ọdún ìtúsílẹ̀,+ ní àjọyọ̀ àtíbàbà,+ 11  nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì bá wá rí ojú Jèhófà+ Ọlọ́run rẹ ní ibi tí yóò yàn,+ ìwọ yóò ka òfin yìí ní iwájú gbogbo Ísírẹ́lì ní etí-ìgbọ́+ wọn. 12  Pe àwọn ènìyàn+ náà jọpọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àtìpó tí ó wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ, kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́,+ bí wọn yóò ti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run+ yín, kí wọ́n sì kíyè sára láti mú gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ṣe. 13  Kí àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ̀ sì fetí sílẹ̀,+ kí wọ́n sì kọ́ láti bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ̀yin yóò fi wà láàyè lórí ilẹ̀ tí ẹ ó sọdá Jọ́dánì láti gbà.”+ 14  Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Wò ó! Ọjọ́ ti sún mọ́lé fún ọ láti kú.+ Pe Jóṣúà, kí ẹ sì dúró nínú àgọ́ ìpàdé, kí èmi lè fàṣẹ yàn án.”+ Nítorí náà, Mósè àti Jóṣúà lọ, wọ́n sì dúró nínú àgọ́ ìpàdé.+ 15  Nígbà náà ni Jèhófà fara hàn nínú àgọ́ náà nínú ọwọ̀n àwọsánmà, ọwọ̀n àwọsánmà náà sì dúró lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà àgọ́+ náà. 16  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Wò ó! Ìwọ yóò dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ;+ àwọn ènìyàn yìí yóò sì dìde dájúdájú,+ wọn yóò sì ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè tí ó wà ní ilẹ̀ tí wọ́n ń lọ,+ ní àárín wọn gan-an, dájúdájú wọn yóò sì ṣá mi tì,+ wọn yóò sì ba májẹ̀mú mi tí mo bá wọn dá jẹ́.+ 17  Látàrí ìyẹn, ìbínú mi yóò ru sí wọn ní ọjọ́ yẹn,+ dájúdájú, èmi yóò sì ṣá wọn tì,+ èmi yóò sì fi ojú mi pa mọ́ fún wọn,+ wọn yóò sì di ohun tí a óò jó run; ọ̀pọ̀ ìyọnu àjálù àti wàhálà yóò sì bá wọn,+ dájúdájú, wọn yóò sì sọ ní ọjọ́ náà pé, ‘Kì  í ha ṣe nítorí pé Ọlọ́run wa kò sí láàárín wa ni ìyọnu àjálù wọ̀nyí fi wá sórí wa?’+ 18  Ní tèmi, èmi yóò fi ojú mi pa mọ́ pátápátá ní ọjọ́ yẹn nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù, nítorí pé wọ́n ti yí padà sí àwọn ọlọ́run mìíràn.+ 19  “Wàyí o, ẹ kọ̀wé orin+ yìí fún ara yín, kí ẹ sì fi í kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Ẹ fi í sí ẹnu wọn, kí orin yìí lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 20  Nítorí èmi yóò mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn,+ èyí tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin,+ dájúdájú wọn yóò sì jẹun,+ wọn yóò sì yó, wọn yóò sì sanra,+ wọn yóò sì yí padà sí àwọn ọlọ́run mìíràn,+ wọn yóò sì sìn wọ́n ní ti gidi, wọn yóò sì hùwà àìlọ́wọ̀ sí mi, wọn yóò sì ba májẹ̀mú mi jẹ́.+ 21  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ìyọnu àjálù àti wàhálà bá bá wọn,+ orin yìí yóò dáhùn níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, nítorí pé a kì yóò gbàgbé rẹ̀ ní ẹnu àwọn ọmọ wọn, nítorí mo mọ ìtẹ̀sí èrò+ wọn dáadáa, èyí tí wọ́n ń mú dàgbà lónìí, kí n tó mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀.” 22  Nítorí náà, Mósè kọ̀wé orin yìí ní ọjọ́ yẹn, kí ó lè fi í kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 23  Ó sì tẹ̀ síwájú láti fàṣẹ yan Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì,+ ó sì wí pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ nítorí pé ìwọ—ìwọ ni yóò mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá sí ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún wọn,+ èmi fúnra mi yóò sì máa wà pẹ̀lú rẹ nìṣó.” 24  O sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Mósè parí kíkọ àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí sínú ìwé títí wọ́n fi parí,+ 25  Mósè bẹ̀rẹ̀ sí pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì, àwọn olùru àpótí májẹ̀mú+ Jèhófà, pé: 26  “Bí ẹ bá ti gba ìwé òfin+ yìí, kí ẹ fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ó sì máa ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí ọ níbẹ̀.+ 27  Nítorí èmi—èmi mọ ìṣọ̀tẹ̀+ rẹ àti ọrùn líle+ rẹ dáadáa. Bí ẹ̀yin bá jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ nínú ìwà híhù sí Jèhófà,+ nígbà tí mo ṣì wà láàyè lónìí pẹ̀lú yín, mélòómélòó wá ni ẹ̀yin yóò jẹ́ bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ikú mi! 28  Pe gbogbo àgbà ọkùnrin ẹ̀yà yín àti àwọn onípò àṣẹ+ láàárín yín jọpọ̀ sọ́dọ̀ mi, kí ẹ sì jẹ́ kí n sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní etí-ìgbọ́ wọn, sì jẹ́ kí n fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí wọn.+ 29  Nítorí èmi mọ̀ dáadáa pé, lẹ́yìn ikú mi, ẹ̀yin kì yóò kùnà láti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun,+ dájúdájú ẹ̀yin yóò sì yà kúrò ní ọ̀nà tí mo pàṣẹ fún yín nípa rẹ̀; ó sì dájú pé ìyọnu àjálù+ yóò ṣẹlẹ̀ sí yín ní òpin àwọn ọjọ́ náà, nítorí tí ẹ̀yin yóò ṣe ohun tí ó burú lójú Jèhófà láti mú un bínú nípa àwọn iṣẹ́ ọwọ́ yín.”+ 30  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ọ̀rọ̀ orin yìí ní etí-ìgbọ́ gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì títí wọ́n fi parí:+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé