Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 30:1-20

30  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bá wá sórí rẹ, ìbùkún+ àti ìfiré,+ èyí tí mo ti fi lélẹ̀ níwájú rẹ, tí ìwọ sì ti mú wọn padà wá sínú ọkàn-àyà+ rẹ láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fọ́n ọ ká sí,+  tí ìwọ sì ti padà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, tí o sì fetí sí ohùn rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ, pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn+ rẹ,  Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì mú àwọn òǹdè+ rẹ padà wá, yóò sì fi àánú+ hàn sí ọ, yóò sì tún kó ọ jọ láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn níbi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ ká sí.+  Bí àwọn ènìyàn rẹ tí a fọ́n ká bá wà ní ìpẹ̀kun ọ̀run, láti ibẹ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò ti kó ọ jọ, láti ibẹ̀ sì ni yóò ti mú ọ.+  Ní tòótọ̀, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ wá sí ilẹ̀ tí àwọn baba rẹ gbà, dájúdájú ìwọ yóò sì gbà á; ní tòótọ́, òun yóò sì ṣe rere fún ọ, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ sí i ju àwọn baba rẹ.+  Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì dádọ̀dọ́ ọkàn-àyà rẹ,+ àti ọkàn-àyà àwọn ọmọ+ rẹ, kí o lè fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ nítorí ìwàláàyè rẹ.+  Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì fi gbogbo ìbúra wọ̀nyí sórí àwọn ọ̀tá rẹ àti sórí àwọn tí ó kórìíra rẹ, tí wọ́n ti ṣe inúnibíni sí ọ.+  “Ní tìrẹ, ìwọ yóò yí padà, dájúdájú, ìwọ yóò sì fetí sí ohùn Jèhófà, ìwọ yóò sì pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mo ń pa fún ọ lónìí+ mọ́.  Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì mú kí o ní àníṣẹ́kù nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́+ rẹ ní tòótọ́, nínú èso ikùn rẹ àti èso àwọn ẹran agbéléjẹ̀+ rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ,+ ní yíyọrí sí aásìkí;+ nítorí pé Jèhófà yóò tún yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí rẹ fún rere, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí àwọn baba ńlá+ rẹ; 10  nítorí ìwọ yóò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o lè pa àwọn àṣẹ rẹ̀ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ tí a kọ sínú ìwé òfin+ yìí mọ́, nítorí pé ìwọ yóò padà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ.+ 11  “Nítorí àwọn àṣẹ yìí tí mo ń pa fún ọ lónìí kò ṣòro rárá fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ibi jíjì nnàréré.+ 12  Kò sí ní ọ̀run, tí ì bá fi yọrí sí wíwí pé, ‘Ta ni yóò gòkè re ọ̀run fún wa, kí ó sì mú un wá fún wa, kí ó lè jẹ́ kí a gbọ́ ọ, kí a lè ṣe é?’+ 13  Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ni ìhà kejì òkun, tí ì bá fi yọrí sí wíwí pé, ‘Ta ni yóò ré kọjá sí ìhà kejì òkun fún wa, kí ó sì mú un wá fún wa, kí ó lè jẹ́ kí a gbọ́ ọ, kí a lè ṣe é?’ 14  Nítorí ọ̀rọ̀ náà wà nítòsí rẹ gan-an, ní ẹnu ìwọ fúnra rẹ àti ní ọkàn-àyà+ ìwọ fúnra rẹ, kí o lè ṣe é.+ 15  “Wò ó, mo fi ìyè àti ire, àti ikú àti ibi,+ sí iwájú rẹ lónìí. 16  [Bí ìwọ yóò bá fetí sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ,] èyí tí èmi ń pa fún ọ lónìí, kí o bàa lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀ àti láti máa pa àwọn àṣẹ+ rẹ̀ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ rẹ̀ mọ́, nígbà náà, a óò mú kí o máa wà láàyè nìṣó,+ a ó sì sọ ọ́ di púpọ̀ sí i, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì bù kún ọ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń lọ láti gbà.+ 17  “Ṣùgbọ́n bí ọkàn-àyà rẹ bá yí padà, tí ìwọ kò sì fetí sílẹ̀,+ tí a sì sún ọ dẹ́ṣẹ̀, tí o sì tẹrí ba fún àwọn ọlọ́run mìíràn, tí o sì sìn wọ́n+ ní ti gidi, 18  èmi sọ ní tòótọ́ fún yín lónìí pé ṣíṣègbé ni ẹ̀yin yóò ṣègbé.+ Ẹ̀yin kì yóò mú ọjọ́ yín gùn lórí ilẹ̀ tí ìwọ ń sọdá Jọ́dánì lọ láti gbà. 19  Èmi ń fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí yín lónìí,+ pé èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ,+ ìbùkún+ àti ìfiré;+ kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó,+ ìwọ àti ọmọ+ rẹ, 20  nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn;+ nítorí òun ni ìyè rẹ àti gígùn ọjọ́ rẹ,+ kí ìwọ lè máa gbé lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù láti fi fún wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé