Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Diutarónómì 29:1-29

29  Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè láti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá ní ilẹ̀ Móábù yàtọ̀ sí májẹ̀mú tí ó ti bá wọn dá ní Hórébù.+  Mósè sì tẹ̀ síwájú láti pe gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ni ẹni tí ó rí gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe lójú yín ní ilẹ̀ Íjíbítì sí Fáráò àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀+ rẹ̀,  àwọn ìfihàn ẹ̀rí dídánilójú ńláǹlà tí ojú rẹ rí,+ àwọn iṣẹ́ àmì+ àti iṣẹ́ ìyanu ńláǹlà+ wọnnì.  Síbẹ̀ náà, Jèhófà kò tíì fi ọkàn-àyà fún yín láti mọ̀ àti ojú láti rí àti etí láti gbọ́ títí di òní+ yìí.  ‘Nígbà tí èmi ń bá a nìṣó láti ṣamọ̀nà yín fún ogójì ọdún ní aginjù,+ ẹ̀wù yín kò gbó mọ yín lára, sálúbàtà rẹ kò sì gbó mọ́ ọ lẹ́sẹ̀.+  Oúnjẹ ni ẹ̀yin kò jẹ,+ wáìnì àti ọtí tí ń pani ni ẹ̀yin kò sì mu, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ẹ dé ibí yìí, Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì+ àti Ógù+ ọba Báṣánì sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde bọ̀ láti wá pàdé wa nínú ìjà ogun, ṣùgbọ́n a ṣẹ́gun wọn.+  Lẹ́yìn náà, a gba ilẹ̀ wọn, a sì fi í fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè+ ní ogún.  Nítorí náà, kí ẹ máa pa àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn, kí ẹ lè mú ohun gbogbo tí ẹ ó ṣe yọrí sí rere.+ 10  “Gbogbo yín ni ẹ dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín lónìí, àwọn olórí ẹ̀yà yín, àwọn àgbà ọkùnrin yín àti àwọn onípò àṣẹ láàárín yín, olúkúlùkù ọkùnrin Ísírẹ́lì,+ 11  àwọn ọmọ yín kéékèèké, àwọn aya yín,+ àti àtìpó+ rẹ tí ó wà ní àárín ibùdó rẹ, láti orí aṣẹ́gi rẹ dórí olùfa omi+ rẹ, 12  kí o lè wọnú májẹ̀mú+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ àti ìbúra rẹ̀, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń bá ọ dá lónìí;+ 13  fún ète fífìdí rẹ múlẹ̀ lónìí, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn+ rẹ̀, àti kí ó lè fi ara rẹ̀ hàn ní Ọlọ́run+ rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ àti gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Jékọ́bù.+ 14  “Wàyí o, kì í ṣe ẹ̀yin nìkan ni èmi ń bá dá májẹ̀mú yìí àti ìbúra yìí,+ 15  ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ pẹ̀lú ẹni tí ó dúró pẹ̀lú wa níhìn-ín lónìí, níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa, àti pẹ̀lú àwọn tí wọn kò sí pẹ̀lú wa níhìn-ín lónìí;+ 16  (nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa nípa bí a ṣe gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì àti bí a ṣe kọjá ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ là kọjá.+ 17  Ẹ̀yin sì rí àwọn ohun ìríra wọn àti àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn,+ ti igi àti ti òkúta, ti fàdákà àti ti wúrà, tí ó wà pẹ̀lú wọn;) 18  kí ó má bàa sí ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí ìdílé tàbí ẹ̀yà kan láàárín yín tí ọkàn-àyà rẹ̀ ń yí padà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa lónìí láti lọ sin àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè+ wọnnì; kí ó má bàa sí gbòǹgbò kan láàárín yín tí ń so èso ọ̀gbìn onímájèlé àti iwọ.+ 19  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ẹnì kan bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìbúra+ yìí, tí ó sì súre fún ara rẹ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé, ‘Èmi yóò ní àlàáfíà,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi yóò máa rìn nínú agídí ọkàn-àyà+ mi,’ ti òun ti ìpètepèrò gbígbá èyí tí a bomi rin dáadáa lọ pa pọ̀ pẹ̀lú èyí tí òùngbẹ ń gbẹ, 20  Jèhófà kì yóò fẹ́ láti dárí jì  í,+ ṣùgbọ́n ìbínú+ Jèhófà àti ìgbóná ọkàn+ rẹ̀ yóò wá rú èéfín sí ẹni+ yẹn, dájúdájú, gbogbo ìbúra tí a kọ sínú ìwé+ yìí yóò sì sọ̀ kalẹ̀ sórí rẹ̀, Jèhófà yóò sì nu orúkọ rẹ̀ nù lábẹ́ ọ̀run ní ti gidi. 21  Nípa báyìí, Jèhófà yóò yà á sọ́tọ̀+ kúrò lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì fún ìyọnu àjálù, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ìbúra májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé òfin yìí. 22  “Ìran ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín tí yóò dìde lẹ́yìn yín, àti ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí yóò wá láti ilẹ̀ jíjì nnà, ni ó dájú pé wọn yóò sọ̀rọ̀, àní nígbà tí wọ́n bá rí ìyọnu àjàkálẹ̀ ilẹ̀ yẹn àti àwọn àrùn rẹ̀ tí Jèhófà ti mú kí ó ṣe é ní àìsàn,+ 23  imí ọjọ́ àti iyọ̀+ àti ìfinásun,+ tó bẹ́ẹ̀ tí a kì yóò fúnrúgbìn sí gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ tàbí kí ó rú jáde, bẹ́ẹ̀ ni ewéko èyíkéyìí kì yóò rú yọ nínú rẹ̀, bí ìbìṣubú Sódómù àti Gòmórà,+ Ádímà+ àti Sébóímù,+ tí Jèhófà bì ṣubú nínú ìbínú rẹ̀ àti nínú ìrunú rẹ̀;+ 24  bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sọ dájúdájú, pé, ‘Èé ṣe tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí?+ Kí ló fa ìgbóná ìbínú ńláǹlà yìí?’ 25  Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, ‘Ó jẹ́ nítorí pé wọ́n pa májẹ̀mú+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn tì, èyí tí ó bá wọn dá nígbà tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 26  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì ń tẹrí ba fún wọn, àwọn ọlọ́run tí wọn kò mọ̀, tí òun kò sì pín fún wọn.+ 27  Nígbà náà ni ìbínú Jèhófà ru sí ilẹ̀ yẹn nípa mímú gbogbo ìfiré tí a kọ sínú ìwé+ yìí wá sórí rẹ̀. 28  Nítorí èyí, Jèhófà fà wọ́n tu tigbòǹgbò-tigbòǹgbò kúrò lórí ilẹ̀ wọn nínú ìbínú+ àti ìhónú àti ìkannú ńláǹlà, ó sì sọ wọ́n sí ilẹ̀ mìíràn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí+ yìí.’ 29  “Àwọn ohun tí a fi pa mọ́+ jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run wa, ṣùgbọ́n àwọn ohun tí a ṣí payá+ jẹ́ ti àwa àti ti àwọn ọmọ wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, kí àwa lè máa ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ òfin+ yìí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé