Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 28:1-68

28  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ìwọ kì yóò bá kùnà láti fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa kíkíyè sára láti tẹ̀ lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí èmi ń pa fún ọ lónìí,+ dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú yóò gbé ọ ga lékè gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.+  Gbogbo ìbùkún wọ̀nyí yóò sì wá sórí rẹ, yóò sì dé bá ọ,+ nítorí pé ìwọ ń bá a nìṣó láti máa fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ:  “Ìbùkún ni yóò jẹ́ tìrẹ ní ìlú ńlá,+ ìbùkún ni yóò sì jẹ́ tìrẹ ní pápá.+  “Ìbùkún ni fún èso ikùn+ rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ àti èso ẹranko agbéléjẹ̀+ rẹ, ọmọ ẹran ọ̀sìn rẹ àti àtọmọdọ́mọ agbo ẹran rẹ.+  “Ìbùkún ni fún apẹ̀rẹ̀+ rẹ àti ọpọ́n ìpo-nǹkan+ rẹ.  “Ìbùkún ni yóò jẹ́ tìrẹ nígbà tí o bá wọlé, ìbùkún ni yóò sì jẹ́ tìrẹ nígbà tí o bá jáde.+  “Jèhófà yóò mú kí o ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ tí wọ́n dìde sí ọ níwájú rẹ.+ Wọn yóò jáde sí ọ ní ọ̀nà kan, ṣùgbọ́n wọn yóò sá lọ níwájú rẹ ní ọ̀nà méje.+  Jèhófà yóò fàṣẹ gbé ìbùkún kalẹ̀ fún ọ lórí àwọn ilé ìtọ́jú ẹrù+ rẹ àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ,+ dájúdájú, òun yóò sì bù kún ọ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ.  Jèhófà yóò fìdí rẹ múlẹ̀ bí àwọn ènìyàn mímọ́ fún ara rẹ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ọ,+ nítorí pé ìwọ ń bá a lọ láti máa pa àwọn àṣẹ+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, o sì ti rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. 10  Gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé yóò sì rí i pé orúkọ Jèhófà ni a fi ń pè ọ́,+ àyà rẹ yóò sì máa fò wọ́n ní tòótọ́.+ 11  “Jèhófà yóò sì mú kí aásìkí rẹ kún àkúnwọ́sílẹ̀ ní ti gidi nínú èso ikùn rẹ+ àti èso àwọn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ,+ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fi fún ọ.+ 12  Jèhófà yóò ṣí ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ rere rẹ̀ fún ọ, ọ̀run, láti fi òjò fún ọ lórí ilẹ̀ rẹ ní àsìkò+ rẹ̀ àti láti bù kún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;+ dájúdájú ìwọ yóò sì wín ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, nígbà tí ìwọ fúnra rẹ kì yóò yá nǹkan.+ 13  Jèhófà yóò sì fi ọ́ sí ipò orí+ ní tòótọ́, kì í sì í ṣe sí ipò ìrù; kìkì òkè ni ìwọ yóò sì máa wà, ìwọ kì yóò sì wà ní ìsàlẹ̀, nítorí pé ìwọ ń bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, èyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí láti pa mọ́ àti láti mú ṣe. 14  Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ yà kúrò nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń pa láṣẹ fún yín lónìí, sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ láti rìn tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn+ wọ́n. 15  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ìwọ kò bá ní fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ nípa kíkíyè sára láti tẹ̀ lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ àti ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, kí gbogbo ìfiré wọ̀nyí pẹ̀lú wá sórí rẹ, kí wọ́n sì dé bá ọ:+ 16  “Ègún ni fún ọ ní ìlú ńlá,+ ègún sì ni fún ọ ní pápá.+ 17  “Ègún ni fún apẹ̀rẹ̀+ rẹ àti ọpọ́n ìpo-nǹkan+ rẹ. 18  “Ègún ni fún èso ikùn+ rẹ àti èso ilẹ̀+ rẹ, ọmọ ẹran ọ̀sìn rẹ àti àtọmọdọ́mọ agbo ẹran+ rẹ. 19  “Ègún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ègún sì ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.+ 20  “Jèhófà yóò rán ègún,+ ìdàrúdàpọ̀+ àti ìbáwí mímúná+ sórí rẹ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ tí ìwọ yóò gbìyànjú láti mú ṣe, títí a ó fi pa ọ́ rẹ́ ráúráú, tí ìwọ yóò sì ṣègbé ní wéréwéré, nítorí búburú àwọn ìṣe rẹ, ní ti pé ìwọ ti ṣá mi tì.+ 21  Jèhófà yóò jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn lẹ̀ mọ́ ọ títí òun yóò fi pa ọ́ run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀ tí ìwọ ń lọ gbà.+ 22  Jèhófà yóò fi ikọ́ ẹ̀gbẹ+ àti ibà amáragbóná fòfò àti ara wíwú àti ooru aṣeni-níbà àti idà+ àti ìjógbẹ+ àti èbíbu+ kọlù ọ́, dájúdájú, wọn yóò sì lépa rẹ títí ìwọ yóò fi ṣègbé. 23  Sánmà rẹ tí ó wà lókè orí rẹ yóò sì di bàbà, ilẹ̀ tí ó sì wà lábẹ́ rẹ yóò di irin.+ 24  Jèhófà yóò pèsè erukutu àti ekuru gẹ́gẹ́ bí òjò ilẹ̀ rẹ. Láti ọ̀run ni yóò ti sọ̀ kalẹ̀ wá sórí rẹ, títí a ó fi pa ọ́ rẹ́ ráúráú. 25  Jèhófà yóò mú kí a ṣẹ́gun rẹ níwájú àwọn ọ̀tá+ rẹ. Ọ̀nà kan ni ìwọ yóò gbà jáde sí wọn, ṣùgbọ́n ọ̀nà méje ni ìwọ yóò gbà sá lọ níwájú wọn; ìwọ yóò sì di ohun ada-jì nnìjì nnì-boni lójú gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé.+ 26  Òkú rẹ yóò sì di oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá tí ń fò lójú ọ̀run àti fún ẹranko inú pápá, láìsí ẹnikẹ́ni láti mú wọn wárìrì.+ 27  “Jèhófà yóò fi oówo Íjíbítì+ àti jẹ̀díjẹ̀dí àti ifo àti àwúfọ́ awọ ara kọlù ọ́, láti inú èyí tí a kì yóò lè mú ọ lára dá. 28  Jèhófà yóò fi ìṣiwèrè+ àti ìpàdánù agbára ìríran+ àti ìdàrúdàpọ̀ ọkàn-àyà+ kọlù ọ́. 29  Ní tòótọ́, ìwọ yóò sì di ẹni tí ń tá ràrà kiri ní ọjọ́kanrí, gan-an gẹ́gẹ́ bí afọ́jú kan ti ń tá ràrà kiri nínú ìṣúdùdù,+ ìwọ kì yóò sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ yọrí sí rere; ìwọ nìkan ni yóò sì di ẹni tí a ń lù ní jì bìtì tí a sì ń jà lólè nígbà gbogbo, láìsí ẹnikẹ́ni láti gbà ọ́ là.+ 30  Ìwọ yóò fẹ́ obìnrin kan sọ́nà ṣùgbọ́n ọkùnrin mìíràn yóò fipá bá a lò pọ̀.+ Ìwọ yóò kọ́ ilé ṣùgbọ́n ìwọ kò ní gbé inú rẹ̀.+ Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà ṣùgbọ́n ìwọ kò ní bẹ̀rẹ̀ sí lò ó.+ 31  Akọ màlúù rẹ ni a ó pa níbẹ̀ lójú rẹ—ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ nǹkan kan lára rẹ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni a ó fi ìjàlólè gbà kúrò níwájú rẹ—ṣùgbọ́n kò ní padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. Àgùntàn rẹ ni a ó fi fún àwọn ọ̀tá rẹ—ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní olùgbàlà+ kankan. 32  Àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ni a ó fi fún àwọn ènìyàn mìíràn,+ tí ojú rẹ yóò sì máa wò wọ́n, tí yóò sì máa ṣàfẹ́rí wọn nígbà gbogbo—ṣùgbọ́n kì yóò sí agbára kankan ní ọwọ́ rẹ.+ 33  Èso ilẹ̀ rẹ àti gbogbo àmújáde rẹ ni àwọn ènìyàn kan tí ìwọ kò mọ̀ yóò jẹ;+ ìwọ yóò sì di ẹnì kan tí a kàn ń lù ní jì bìtì ti a sì ń tẹ̀ rẹ́ nígbà gbogbo.+ 34  Dájúdájú, ìwọ yóò sì ya wèrè nítorí ohun tí ojú rẹ yóò rí.+ 35  “Jèhófà yóò fi oówo afòòró-ẹ̀mí kọlù ọ́ lórí eékún méjèèjì  àti ojúgun méjèèjì , láti inú èyí tí a kì yóò lè mú ọ lára dá, láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ títí dé àtàrí rẹ.+ 36  Jèhófà yóò kó ìwọ+ àti ọba+ rẹ tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ lórí rẹ lọ sí orílẹ̀-èdè kan tí ìwọ kò mọ̀, yálà ìwọ tàbí àwọn baba ńlá rẹ; ibẹ̀ sì ni ìwọ yóò ti sin àwọn ọlọ́run mìíràn, ti igi àti ti òkúta.+ 37  Ìwọ yóò sì di ohun ìyàlẹ́nu,+ ọ̀rọ̀ òwe+ àti ìṣáátá láàárín gbogbo ènìyàn tí Jèhófà yóò kó ọ lọ bá. 38  “Ọ̀pọ̀ irúgbìn ni ìwọ yóò kó jáde lọ sí pápá, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni ìwọ yóò kó jọ,+ nítorí pé àwọn eéṣú yóò jẹ ẹ́ run.+ 39  Àwọn ọgbà àjàrà ni ìwọ yóò gbìn, tí ìwọ yóò sì ro dájúdájú, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní mu wáìnì kankan, ìwọ kò sì ní kó nǹkan kan wọlé,+ nítorí pé kòkòrò mùkúlú yóò jẹ ẹ́ tán.+ 40  Ìwọ yóò wá ní àwọn igi ólífì ní gbogbo ìpínlẹ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní fi òróró kankan pa ara rẹ, nítorí pé àwọn ólífì rẹ yóò wọ̀ dànù.+ 41  Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin ni ìwọ yóò bí, ṣùgbọ́n wọn kò ní máa bá a lọ láti jẹ́ tìrẹ, nítorí pé wọn yóò lọ sí oko òǹdè.+ 42  Gbogbo igi rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ ni àwọn kòkòrò akùnrànyìn yóò fi ṣe ìní. 43  Àtìpó tí ó wà láàárín rẹ ni yóò máa ròkè sí i lékè rẹ ṣáá, nígbà tí ìwọ—ìwọ yóò túbọ̀ máa relẹ̀ sí i ṣáá.+ 44  Òun ni ẹni tí yóò máa wín ọ, nígbà tí ìwọ—ìwọ kò ní wín in.+ Òun ni yóò di orí, nígbà tí ìwọ—ìwọ yóò di ìrù.+ 45  “Dájúdájú, gbogbo ìfiré+ wọ̀nyí ni yóò sì wá sórí rẹ, wọn yóò sì lépa rẹ, wọn yóò sì bá ọ, títí a ó fi pa ọ́ rẹ́ ráúráú,+ nítorí pé ìwọ kò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ nípa pípa àwọn àṣẹ rẹ̀ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ tí ó ti pa láṣẹ fún ọ mọ́.+ 46  Wọn yóò sì máa bá a lọ láti wà lórí ìwọ àti àwọn ọmọ tí ó jẹ́ tìrẹ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àmì àti àmì àgbàyanu kan fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ 47  nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ kò fi ayọ̀ yíyọ̀ àti ìdùnnú+ ọkàn-àyà sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ nítorí ọ̀pọ̀ yanturu ohun gbogbo.+ 48  Àwọn ọ̀tá+ rẹ tí Jèhófà yóò rán sí ọ ni ìwọ yóò sì sìn pẹ̀lú ebi+ àti òùngbẹ àti ìhòòhò àti nínú àìní ohun gbogbo; dájúdájú, òun yóò sì fi àjàgà irin sí ọrùn rẹ, títí yóò fi pa ọ́ rẹ́ ráúráú.+ 49  “Jèhófà yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ láti ibi jíjì nnàréré,+ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí idì ti í kù gìrì mọ́ nǹkan,+ orílẹ̀-èdè kan tí ìwọ kò ní lóye ahọ́n rẹ̀,+ 50  orílẹ̀-èdè kan tí ó jẹ́ òǹrorò ní ojú,+ tí kì yóò ṣe ojúsàájú arúgbó tàbí kí ó fi ojú rere hàn sí ọ̀dọ́ ènìyàn.+ 51  Dájúdájú, wọn yóò sì jẹ àwọn èso ẹran agbéléjẹ̀ rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ, títí a ó fi pa ọ́ rẹ́ ráúráú,+ wọn kò sì ní jẹ́ kí ọkà kankan, wáìnì tuntun tàbí òróró kankan, ọmọ ẹran ọ̀sìn rẹ tàbí àtọmọdọ́mọ agbo ẹran rẹ kankan, ṣẹ́ kù fún ọ, títí wọn yóò fi pa ọ́ run.+ 52  Wọn yóò sì sàga tì ọ́ nínú gbogbo ẹnubodè rẹ, títí àwọn ògiri rẹ gíga tí ó sì jẹ́ olódi, nínú èyí tí ìwọ ní ìgbẹ́kẹ̀lé, yóò fi wó lulẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóò sàga tì ọ́ dájúdájú, nínú gbogbo ẹnubodè rẹ, nínú gbogbo ilẹ̀ rẹ, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti fi fún ọ.+ 53  Nígbà náà, ìwọ yóò ní láti jẹ àwọn èso ikùn rẹ, ẹran ara àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ,+ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti fi fún ọ, nítorí ìlepinpin àti másùnmáwo tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi há ọ mọ́. 54  “Ní ti ọkùnrin tí ó jẹ́ ẹlẹgẹ́ gidigidi àti ajíṣefínní láàárín rẹ, ojú+ rẹ̀ yóò ní ìtẹ̀sí èrò ibi sí arákùnrin rẹ̀ àti aya rẹ̀ tí ó ń ṣìkẹ́ àti ìyókù lára àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ́ kù fún un, 55  kí ó má bàa fún ọ̀kan nínú wọn ní èyíkéyìí lára ẹran ara àwọn ọmọ rẹ̀ tí òun yóò jẹ, nítorí pé kò ní ohunkóhun rárá tí ó ṣẹ́ kù fún un nítorí ìlepinpin àti másùnmáwo tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi há ọ mọ́ nínú gbogbo ẹnubodè+ rẹ. 56  Ní ti obìnrin tí ó jẹ́ ẹlẹgẹ́ àti ajíṣefínní láàárín rẹ, tí kò gbìdánwò rí láti fi àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ kan ilẹ̀ nítorí jíjẹ́ tí ó jẹ́ ajíṣefínní àti nítorí jíjẹ́ tí ó jẹ́ ẹlẹgẹ́,+ ojú rẹ̀ yóò ní ìtẹ̀sí èrò ibi sí ọkọ rẹ̀ tí ó ń ṣìkẹ́ àti ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀, 57  àní sí ibi-ọmọ rẹ̀ tí ó jáde wá láàárín àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ pàápàá àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó bí,+ nítorí pé yóò jẹ wọ́n ní ìkọ̀kọ̀ nítorí àìní ohun gbogbo nítorí ìlepinpin àti másùnmáwo tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi há ọ mọ́ nínú àwọn ẹnubodè+ rẹ. 58  “Bí ìwọ kò bá ní kíyè sí àtimú gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí tí a kọ sínú ìwé+ yìí ṣe kí o lè bẹ̀rù orúkọ ológo+ àti amúnikún-fún-ẹ̀rù+ yìí, àní Jèhófà,+ Ọlọ́run rẹ, 59  dájúdájú, Jèhófà pẹ̀lú yóò mú kí àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ àti àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ àwọn ọmọ tí ó jẹ́ tìrẹ múná janjan ní ti gidi, àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ ńlá tí ó sì wà pẹ́ títí,+ àti àìsàn afòòró-ẹ̀mí tí ó sì wà pẹ́ títí.+ 60  Òun, ní ti gidi, yóò sì mú gbogbo òkùnrùn Íjíbítì, níwájú èyí tí àyà ti fò ọ́, níwájú wọn padà wá sórí rẹ, wọn yóò sì lẹ̀ mọ́ ọ dájúdájú.+ 61  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àìsàn èyíkéyìí àti ìyọnu àjàkálẹ̀ èyíkéyìí, tí a kò kọ sínú ìwé òfin yìí, ni Jèhófà yóò mú wá sórí rẹ, títí a ó fi pa ọ́ rẹ́ ráúráú. 62  Iye kéréje ni a ó sì ṣẹ́ yín kù ní ti gidi,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti dà bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó,+ nítorí pé ìwọ kò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ. 63  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí yín láti ṣe rere fún yín àti láti sọ yín di púpọ̀ sí i,+ bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà yóò ṣe yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí yín láti pa yín run àti láti pa yín rẹ́ ráúráú;+ a ó sì fipá mú yín kúrò lórí ilẹ̀ tí ìwọ ń lọ gbà.+ 64  “Dájúdájú, Jèhófà yóò sì tú ọ ká sáàárín gbogbo ènìyàn láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì  ilẹ̀ ayé,+ ibẹ̀ sì ni ìwọ yóò ti sin àwọn ọlọ́run mìíràn tí ìwọ kò mọ̀, yálà ìwọ tàbí àwọn baba ńlá rẹ, ti igi àti ti òkúta.+ 65  Ìwọ kò sì ní ní ìdẹ̀rùn láàárín orílẹ̀-èdè wọnnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ibi ìsinmi+ èyíkéyìí fún àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ; Jèhófà yóò sì fi ọkàn-àyà+ ìwárìrì àti ojú ṣíṣe bàìbàì+ àti ìbọ́hùn ọkàn fún ọ níbẹ̀ ní ti gidi. 66  Ìwọ yóò sì wà nínú ewu títóbi jù lọ nítorí ẹ̀mí rẹ, ìwọ yóò sì wà nínú ìbẹ̀rùbojo ní òru àti ní ọ̀sán, ìgbésì ayé rẹ kì yóò sì dá ọ lójú.+ 67  Ìwọ yóò wí ní òwúrọ̀ pé, ‘Ì bá ṣe pé alẹ́ ni!’ àti ní alẹ́, ìwọ yóò wí pé, ‘Ì bá ṣe pé òwúrọ̀ ni!’ nítorí ìbẹ̀rùbojo ọkàn-àyà rẹ tí ìwọ yóò fi wà nínú ìbẹ̀rùbojo àti nítorí ìrí ojú rẹ̀ tí ìwọ yóò rí.+ 68  Dájúdájú, Jèhófà yóò sì mú ọ padà wá sí Íjíbítì nípasẹ̀ àwọn ọkọ̀ òkun, ní ọ̀nà tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ìwọ kì yóò tún rí i mọ́ láé,’+ ẹ̀yin yóò sì ní láti ta ara yín níbẹ̀ fún àwọn ọ̀tá gẹ́gẹ́ bí ẹrúkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin,+ ṣùgbọ́n kò ní sí olùrà kankan.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé