Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Diutarónómì 27:1-26

27  Mósè àti àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ láti pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé: “Kí gbogbo àṣẹ tí mo ń pa fún yín lónìí+ di pípamọ́.  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ní ọjọ́ náà tí ẹ̀yin yóò bá sọdá Jọ́dánì+ sórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, kí o gbé àwọn òkúta ńláńlá nà ró fún ara rẹ, kí o sì fi ẹfun kùn wọ́n.  Kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin+ yìí sára wọn nígbà tí o bá ti sọdá,+ kí o bàa lè wọ ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ wí fún ọ.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ẹ̀yin bá ti sọdá Jọ́dánì, kí ẹ gbé òkúta wọ̀nyí nà ró, gàn-an gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń pàṣẹ fún yín lónìí, ní Òkè Ńlá Ébálì,+ kí o sì fi ẹfun+ kùn wọ́n.  Kí ìwọ sì mọ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ tí a fi àwọn òkúta mọ. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo irinṣẹ́ irin lára wọn.+  Àwọn odindi òkúta ni kí o fi mọ pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lórí rẹ̀.+  Kí o sì rú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀,+ kí o sì jẹ wọ́n níbẹ̀,+ kí o sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ.  Kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin+ yìí sórí àwọn òkúta náà, ní mímú kí wọ́n ṣe ketekete gan-an.”+  Lẹ́yìn náà, Mósè àti àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, sọ fún gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì. Òní yìí ni ìwọ di ènìyàn Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ. 10  Kí ìwọ sì fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì mú àwọn àṣẹ+ rẹ̀ àti ìlànà+ rẹ̀ ṣẹ, èyí tí èmi ń pa láṣẹ fún ọ lónìí.” 11  Mósè sì ń bá a lọ láti pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà ní ọjọ́ yẹn pé: 12  “Àwọn tí ó tẹ̀ lé e yìí ni àwọn tí yóò dúró láti súre fún àwọn ènìyàn náà lórí Òkè Ńlá Gérísímù+ nígbà tí ẹ̀yin bá ti sọdá Jọ́dánì: Síméónì àti Léfì àti Júdà àti Ísákárì àti Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì. 13  Àwọn tí ó sì tẹ̀ lé e yìí ni àwọn tí yóò dúró fún ìfiré+ lórí Òkè Ńlá Ébálì:+ Rúbẹ́nì, Gádì àti Áṣérì àti Sébúlúnì, Dánì àti Náfútálì. 14  Kí àwọn ọmọ Léfì sì dáhùn, kí wọ́n sì fi ohùn ríròkè sọ fún olúkúlùkù ènìyàn ní Ísírẹ́lì pé:+ 15  “‘Ègún ni fún ẹni tí ó ṣe ère gbígbẹ́+ tàbí ère dídà,+ ohun tí ó jẹ́ ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà,+ ohun tí oníṣẹ́ apákó-òun-irin ṣe,+ tí ó sì fi í sí ibi tí ó fara sin.’ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’)+ 16  “‘Ègún ni fún ẹni tí ó fojú tín-ín-rín baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀.’+ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’) 17  “‘Ègún ni fún ẹni tí ó sún ààlà ọmọnìkejì rẹ̀ sẹ́yìn.’+ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’) 18  “‘Ègún ni fún ẹni tí ó mú kí àwọn afọ́jú máa ṣáko lọ kúrò ní ọ̀nà.’+ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’) 19  “‘Ègún ni fún ẹni tí ó yí+ ìdájọ́+ àtìpó,+ ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó+ po.’ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’) 20  “‘Ègún ni fún ẹni tí ó bá sùn ti aya baba rẹ̀, nítorí tí ó ṣí apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ baba rẹ̀.’+ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’) 21  “‘Ègún ni fún ẹni tí ó bá sùn ti ẹranko èyíkéyìí.’+ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’) 22  “‘Ègún ni fún ẹni tí ó bá sùn ti arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀.’+ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’) 23  “‘Ègún ni fún ẹni tí ó bá sùn ti ìyá ìyàwó rẹ̀.’+ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’) 24  “‘Ègún ni fún ẹni tí ó kọlu ọmọnìkejì rẹ̀ lọ́nà tí ó yọrí sí ikú láti ibi tí ó fara sin.’+ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’) 25  “‘Ègún ni fún ẹni tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti kọlu ọkàn lọ́nà tí ó yọrí sí ikú, nígbà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.’+ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’) 26  “‘Ègún ni fún ẹni tí kì yóò fi àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí sí ìlò láti máa pa wọ́n mọ́.’+ (Kí gbogbo ènìyàn náà sì wí pé, ‘Àmín!’)

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé