Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 26:1-19

26  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, nígbà tí ìwọ bá dé orí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún, tí ìwọ sì gbà á, tí o sì ń gbé nínú rẹ̀,+  kí ìwọ mú lára àwọn àkọ́so+ gbogbo èso ilẹ̀ náà, èyí tí ìwọ yóò mú wá láti ilẹ̀ tìrẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, kí o sì kó wọn sínú apẹ̀rẹ̀, kí o sì lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò yàn láti mú kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀.+  Kí o sì wá sí ọ̀dọ̀ àlùfáà+ tí ń gbéṣẹ́ ṣe ní ọjọ́ wọnnì, kí o sì wí fún un pé, ‘Èmi yóò ròyìn lónìí fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ pé mo ti dé sí ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wa láti fi fún wa.’+  “Àlùfáà náà yóò sì gba apẹ̀rẹ̀ náà ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.  Kí o sì dáhùn, kí o sì wí níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ pé, ‘Baba mi jẹ́ ará Síríà+ tí ń ṣègbé lọ; ó sì tẹ̀ síwájú láti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì+ láti máa ṣe àtìpó níbẹ̀ pẹ̀lú iye ènìyàn tí o kéré+ gan-an; ṣùgbọ́n ibẹ̀ ni ó ti di orílẹ̀-èdè títóbi, tí ó lágbára ńlá, tí ó sì pọ̀ níye.+  Àwọn ọmọ Íjíbítì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe láburú sí wa, wọ́n sì ń ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́, wọ́n sì ń gbé ìsìnrú tí ó nira lé wa lórí.+  A sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá+ wa, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohùn+ wa, ó sì bojú wo ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́ àti ìdààmú wa àti ìnira wa.+  Níkẹyìn, Jèhófà mú wa jáde kúrò ní Íjíbítì nípasẹ̀ ọwọ́ líle+ àti apá nínà jáde+ àti nípasẹ̀ ẹ̀rù ńláǹlà+ àti nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu.+  Lẹ́yìn náà, ó mú wa wá sí ibí yìí, ó sì fi ilẹ̀ yìí fún wa, ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.+ 10  Wàyí o, àwọn àkọ́so èso ilẹ̀ tí Jèhófà fi fún mi rèé tí mo mú wá.’+ “Kí o sì kó wọn kalẹ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì tẹrí ba níwájú Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ. 11  Kí ìwọ sì máa yọ̀+ lórí gbogbo ohun rere tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi fún ìwọ àti agbo ilé rẹ, ìwọ àti àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àtìpó tí ó wà ní àárín rẹ.+ 12  “Nígbà tí o bá parí sísan gbogbo ìdá mẹ́wàá+ èso rẹ pátá ní ọdún kẹta,+ ọdún ìdá mẹ́wàá, kí o sì fi í fún àwọn ọmọ Léfì, àwọn àtìpó, àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti àwọn opó, kí wọ́n jẹ ẹ́ ní àwọn ẹnubodè rẹ, kí wọ́n sì tẹ́ ara wọn lọ́rùn.+ 13  Kí o sì wí níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ pé, ‘Mo ti mú ohun tí ó jẹ́ mímọ́ kúrò nínú ilé, mo sì tún ti fi í fún àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àtìpó àti àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti àwọn opó,+ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo àṣẹ rẹ tí o pa fún mi. Èmi kò tẹ àwọn àṣẹ rẹ lójú, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbàgbé.+ 14  Èmi kò jẹ lára rẹ̀ nígbà tí mo ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mú èyíkéyìí kúrò lára rẹ̀ nígbà tí mo jẹ́ aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi èyíkéyìí lára rẹ̀ fúnni nítorí ẹni tí ó ti kú. Mo fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run mi. Mo ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún mi. 15  Bojú wolẹ̀ ní ti gidi láti ibùgbé+ rẹ mímọ́, ọ̀run, kí o sì bù kún àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì+ àti ilẹ̀ tí ìwọ ti fi fún wa, gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún àwọn baba ńlá+ wa, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.’+ 16  “Ní òní yìí, Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń pa á láṣẹ fún ọ láti mú ìlànà àti ìpinnu ìdájọ́+ wọ̀nyí ṣẹ; kí o sì pa wọ́n mọ́, kí o sì fi gbogbo ọkàn-àyà+ rẹ àti gbogbo ọkàn+ rẹ mú wọn ṣẹ. 17  Jèhófà ni ìwọ ti sún láti sọ lónìí pé òun yóò di Ọlọ́run rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, tí o sì ń pa àwọn ìlànà+ rẹ̀ àti àwọn àṣẹ+ rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ rẹ̀ mọ́, tí o sì ń fetí sí ohùn+ rẹ̀. 18  Ní ti Jèhófà, ó ti sún ọ láti sọ lónìí pé ìwọ yóò di ènìyàn rẹ̀, àkànṣe dúkìá,+ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ+ gan-an, àti pé ìwọ yóò pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́, 19  àti pé òun yóò gbé ọ ga lékè gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù tí ó ṣe,+ ní yíyọrí sí ìyìn àti ìfùsì àti ẹwà, bí o ti ń fi ara rẹ hàn ní ènìyàn mímọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé