Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Diutarónómì 25:1-19

25  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé awuyewuye kan dìde láàárín àwọn ènìyàn,+ tí wọ́n sì kó ara wọn wá fún ìdájọ́,+ kí wọ́n ṣe ìdájọ́ wọn, kí wọ́n sì pe olódodo ní olódodo, kí wọ́n sì pe ẹni burúkú ní ẹni burúkú.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ẹni burúkú náà bá yẹ fún lílù,+ kí onídàájọ́ náà mú kí a dá a dọ̀bálẹ̀, kí a sì fún un ní ẹgba+ níwájú onídàájọ́ náà ní iye tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú iṣẹ́ burúkú rẹ̀.  Kí ó nà án ní ogójì ẹgba. Kí ó má ṣe fi ìkankan kún un, kí ó má bàa máa bá a lọ láti nà án ní ẹgba púpọ̀ ní àfikún sí ìwọ̀nyí,+ kí a sì dójú ti arákùnrin rẹ ní ti tòótọ́ ní ojú rẹ.  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dí akọ màlúù lẹ́nu nígbà tí ó bá ń pa ọkà.+  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn arákùnrin ń gbé pa pọ̀, tí ọ̀kan nínú wọ́n sì kú láìjẹ́ pé ó ní ọmọ, aya ẹni tí ó kú kò gbọ́dọ̀ di ti ọkùnrin àjèjì kan ní òde. Kí arákùnrin ọkọ rẹ̀ lọ bá a, kí ó sì mú un láti fi ṣe aya rẹ̀, kí ó sì ṣú u lópó.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé àkọ́bí tí obìnrin náà yóò bí yóò jogún orúkọ arákùnrin+ rẹ̀ tí ó kú, kí a má bàa nu orúkọ rẹ̀ kúrò ní Ísírẹ́lì.+  “Wàyí o, bí ọkùnrin náà kò bá ní inú dídùn sí mímú opó arákùnrin rẹ̀, nígbà náà, kí opó arákùnrin rẹ gòkè lọ sí ẹnubodè, sọ́dọ̀ àwọn àgbà ọkùnrin,+ kí ó sì wí pé, ‘Arákùnrin ọkọ mi kọ̀ láti pa orúkọ arákùnrin rẹ̀ mọ́ láàyè ní Ísírẹ́lì. Òun kò gbà láti ṣú mi lópó.’  Kí àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá ọkùnrin náà sì pè é, kí wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀, kí ó sì dúró, kí ó sì wí pé, ‘Èmi kò ní inú dídùn sí mímú un.’+  Látàrí èyí, opó arákùnrin rẹ̀ yóò sún mọ́ ọn lójú àwọn àgbà ọkùnrin náà, yóò sì bọ́ sálúbàtà ọkùnrin náà kúrò ní ẹsẹ̀+ rẹ̀, yóò sì tutọ́ sí i ní ojú,+ yóò sì dá a lóhùn pé, ‘Bí ó ti yẹ kí a ṣe nìyẹn sí ọkùnrin tí kì yóò gbé agbo ilé+ arákùnrin rẹ̀ ró.’ 10  Ní Ísírẹ́lì, a ó sì máa pe orúkọ rẹ̀ ní ‘Ilé ẹni tí a bọ́ sálúbàtà rẹ̀.’ 11  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọkùnrin ń bá ara wọn jì jàkadì, tí aya ọ̀kan nínú wọn sì sún mọ́ tòsí láti dá ọkọ rẹ̀ nídè kúrò ní ọwọ́ ẹni tí ń lù ú, tí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde, tí ó sì rá ọkùnrin náà mú ní abẹ́,+ 12  nígbà náà, kí ìwọ gé ọwọ́ rẹ̀ kúrò. Kí ojú rẹ má ṣe káàánú+ rárá. 13  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní oríṣi ìwọ̀n+ méjì nínú àpò rẹ, ọ̀kan tí ó tóbi àti ọ̀kan tí ó kéré. 14  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní oríṣi òṣùwọ̀n eéfà+ méjì nínú ilé rẹ, ọ̀kan tí ó tóbi àti ọ̀kan tí ó kéré. 15  Ìwọ̀n tí ó péye tí ó sì tọ́ ni kí ó máa ní. Òṣùwọ̀n eéfà tí ó péye tí ó sì tọ́ ni kí o máa ní, kí ọjọ́ rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ.+ 16  Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, gbogbo aláìṣèdájọ́ òdodo, jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ. 17  “Kí a ṣe ìrántí ohun tí Ámálékì ṣe sí ọ ní ọ̀nà nígbà tí ẹ̀yin ń ti Íjíbítì+ jáde wá, 18  bí ó ṣe pàdé rẹ ní ọ̀nà tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu gbogbo àwọn tí ń wọ́sẹ̀ rìn ní ìhà ẹ̀yìn rẹ, nígbà tí okun rẹ tán, tí àárẹ̀ sì mú ọ; òun kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.+ 19  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá fún ọ ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá rẹ tí ó wà yíká-yíká ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún láti gbà,+ kí o nu mímẹ́nu kan Ámálékì kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbàgbé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé