Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 24:1-22

24  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan mú obìnrin kan gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀, tí ó sì fi í ṣe aya, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí obìnrin náà kò bá rí ojú rere ní ojú rẹ̀ nítorí pé ọkùnrin náà rí ohun àìbójúmu kan níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀,+ kí ọkùnrin náà kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀+ fún un, kí ó sì fi í lé e lọ́wọ́, kí ó sì rán an lọ kúrò ní ilé rẹ̀.+  Kí obìnrin náà sì jáde kúrò ní ilé ọkùnrin náà, kí ó sì lọ di ti ọkùnrin mìíràn.+  Bí ọkùnrin èyí ìkejì bá wá kórìíra rẹ̀, tí ó sì kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí ó sì fi í lé e lọ́wọ́, tí ó sì rán an lọ kúrò ní ilé rẹ̀, tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin èyí ìkejì tí ó mú un láti fi ṣe aya rẹ̀ bá kú,  ẹni tí ó ni ín lákọ̀ọ́kọ́ tí ó rán an lọ ni a kì yóò gbà láyè láti tún mú un padà láti di aya rẹ̀ lẹ́yìn tí a ti sọ obìnrin náà di ẹlẹ́gbin;+ nítorí ìyẹn jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí níwájú Jèhófà, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ mú ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún wọnú ẹ̀ṣẹ̀.  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan fẹ́ aya tuntun,+ kí ó má ṣe jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, kí a má sì gbé ohunkóhun mìíràn kà á lórí. Kí ó máa wà lómìnira nìṣó nínú ilé rẹ̀ fún ọdún kan, kí ó sì mú kí aya tí ó fẹ́ máa yọ̀.+  “Kí ẹnikẹ́ni má fi ipá gba ọlọ ọlọ́wọ́ tàbí ọmọ orí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò,+ nítorí pé ọkàn ni ó ń fi ipá gbà gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a rí ọkùnrin kan tí ó jí+ ọkàn kan tí ó jẹ́ ti àwọn arákùnrin rẹ̀ ọmọ Ísírẹ́lì gbé, tí ó sì hùwà sí i lọ́nà ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀, tí ó sì tà á,+ kí ajínigbé náà kú. Kí o sì mú ohun tí ó burú kúrò láàárín rẹ.+  “Máa ṣọ́ra fún àrùn ẹ̀tẹ̀,+ kí o sì kíyè sára gidi gan-an láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìtọ́ni tí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, yóò máa fi fún yín.+ Gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún wọn gan-an ni kí ẹ kíyè sára+ láti máa ṣe.  Kí a ṣe ìrántí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe sí Míríámù ní ọ̀nà, nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Íjíbítì.+ 10  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o wín ọmọnìkejì rẹ ní ohun yíyá èyíkéyìí,+ ìwọ kò gbọ́dọ̀ wọnú ilé rẹ̀ láti gba ohun tí ó fi dógò+ lọ́wọ́ rẹ̀. 11  Kí o dúró ní òde, kí ẹni tí ìwọ sì yá ní nǹkan mú ohun ìdógò náà jáde wá fún ọ ní òde. 12  Bí ẹni náà bá sì wà nínú ìdààmú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ lọ sùn ti ìwọ ti ohun ìdógò+ rẹ̀. 13  Lọ́nàkọnà, kí ìwọ dá ohun ìdógò náà padà fún un ní gbàrà tí oòrùn bá ti wọ̀,+ kí ó sì lọ sùn ti òun ti ẹ̀wù rẹ̀,+ yóò sì súre+ fún ọ; yóò sì túmọ̀ sí òdodo fún ọ níwájú Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ. 14  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lu lébìrà tí a gbà sí iṣẹ́, tí ó wà nínú ìdààmú, tí ó sì jẹ́ òtòṣì, ní jì bìtì, yálà lára àwọn arákùnrin rẹ tàbí lára àwọn àtìpó rẹ tí wọ́n wà ní ilẹ̀ rẹ, ní àwọn ẹnubodè+ rẹ. 15  Ọjọ́ rẹ̀ ni kí o fi owó ọ̀yà+ rẹ̀ fún un, kí oòrùn má sì wọ̀ bá wọn, nítorí pé ó wà nínú ìdààmú, tí ó sì ń gbé ọkàn rẹ̀ lé owó ọ̀yà rẹ̀; kí ó má bàa ké pe Jèhófà sí ọ,+ yóò sì di ẹ̀ṣẹ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ.+ 16  “Kí a má ṣe fi ikú pa àwọn baba ní tìtorí àwọn ọmọ, kí a má sì fi ikú pa àwọn ọmọ ní tìtorí àwọn baba.+ Kí a fi ikú pa olúkúlùkù nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀.+ 17  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ yí ìdájọ́ àtìpó+ tàbí ọmọdékùnrin aláìníbaba+ po, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ fi ipá gba ẹ̀wù opó gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.+ 18  Kí ìwọ sì rántí pé o di ẹrú ní Íjíbítì, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì tẹ̀ síwájú láti tún ọ rà padà kúrò níbẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ láti ṣe nǹkan yìí. 19  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o kárúgbìn ìkórè rẹ nínú pápá+ rẹ, tí o sì gbàgbé ìtí kan sínú pápá náà, ìwọ kò gbọ́dọ̀ padà lọ gbé e. Kí ó wà níbẹ̀ fún àwọn àtìpó, fún àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti fún àwọn opó;+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè bù kún ọ nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́+ rẹ. 20  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o lu igi ólífì rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ tún padà lọ wo àwọn ẹ̀tun rẹ̀ ní títọ àwọn ibi tí o ti kọjá. Kí ó wà níbẹ̀ fún àwọn àtìpó, fún àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti fún àwọn opó.+ 21  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o kó àwọn èso àjàrà ọgbà àjàrà rẹ jọ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ kó àsẹ́kùsílẹ̀ ní títọ àwọn ibi tí o ti kọjá. Kí wọ́n wà níbẹ̀ fún àwọn àtìpó, fún àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti fún àwọn opó. 22  Kí ìwọ sì rántí pé o di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ láti ṣe nǹkan yìí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé