Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Diutarónómì 23:1-25

23  “Ọkùnrin èyíkéyìí tí a bá tẹ̀ lọ́dàá+ nípa fífọ́ kórópọ̀n+ rẹ̀ tàbí kíké ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ kúrò kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.  “Ọmọ àlè+ kankan kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà. Àní títí dé ìran kẹwàá pàápàá, ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ tirẹ̀ kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.  “Ọmọ Ámónì tàbí ọmọ Móábù kankan kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+ Àní títí dé ìran kẹwàá pàápàá, ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ tiwọn kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà fún àkókò tí ó lọ kánrin,  fún ìdí náà pé wọn kò wá fi oúnjẹ àti omi ṣe àrànṣe+ fún yín ní ọ̀nà nígbà tí ẹ ń jáde kúrò ní Íjíbítì,+ àti nítorí pé wọ́n háyà Báláámù ọmọkùnrin Béórì láti Pétórì ti Mesopotámíà sí ọ láti pe ibi wá sórí rẹ.+  Jèhófà Ọlọ́run rẹ kò sì fẹ́ fetí sí Báláámù;+ ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run rẹ yí ìfiré náà padà sí ìbùkún+ ní tìtorí rẹ, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ.+  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ fún àlàáfíà wọn àti aásìkí wọn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe họ́ọ̀ sí ọmọ Édómù, nítorí arákùnrin+ rẹ ni. “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe họ́ọ̀ sí ọmọ Íjíbítì, nítorí ìwọ di àtìpó ní ilẹ̀+ rẹ̀.  Àwọn ọmọ tí a bá bí fún wọn ní ìran kẹta lè fúnra wọn wá sínú ìjọ Jèhófà.  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o jáde lọ sínú ibùdó láti gbéjà ko àwọn ọ̀tá rẹ, kí o pa ara rẹ mọ́ kúrò nínú gbogbo ohun búburú.+ 10  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan nínú rẹ kò máa bá a nìṣó ní wíwà ní ẹni tí ó mọ́, nítorí ìsọdèérí tí ó ṣẹlẹ̀ ní òru,+ kí ó jáde lọ sí òde ibùdó. Kò gbọ́dọ̀ wá sí àárín ibùdó.+ 11  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ilẹ̀ bá ń ṣú lọ, kí ó fi omi wẹ̀, nígbà tí oòrùn bá sì ti wọ̀, ó lè wá sí àárín ibùdó.+ 12  Kí ibi ìkọ̀kọ̀ sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìlò rẹ ní òde ibùdó, kí ìwọ sì máa jáde lọ sí ibẹ̀. 13  Kí igi ìgbẹ́lẹ̀ sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìlò rẹ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìṣiṣẹ́ rẹ, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ìwọ bá lóṣòó ní òde, kí ìwọ sì fi í wa ihò pẹ̀lú, kí ó sì yí padà, kí o sì bo ìgbọ̀nsẹ̀+ rẹ. 14  Nítorí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń rìn káàkiri láàárín ibùdó rẹ láti dá ọ nídè+ àti láti jọ̀wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ fún ọ;+ kí ibùdó rẹ sì máa wà ní mímọ́,+ kí ó má bàa rí nǹkan kan tí kò bójú mu nínú rẹ, kí ó sì yí padà dájúdájú kúrò láti máa bá ọ rìn.+ 15  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi ẹrú lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí ó bá sá lọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ.+ 16  Ọ̀dọ̀ rẹ ni yóò máa gbé nìṣó láàárín rẹ ní ibi yòówù tí ó bá yàn nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá+ rẹ, ní ibi yòówù tí ó bá fẹ́. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe é+ níkà. 17  “Èyíkéyìí nínú àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ di kárùwà+ inú tẹ́ńpìlì, bẹ́ẹ̀ ni èyíkéyìí nínú àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ di kárùwà+ inú tẹ́ńpìlì. 18  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú ọ̀yà+ iṣẹ́ aṣẹ́wó tàbí iye owó ajá+ wá sínú ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí, nítorí pé wọ́n jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, àní àwọn méjèèjì . 19  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú kí arákùnrin rẹ san èlé,+ èlé lórí owó, èlé lórí oúnjẹ,+ èlé lórí ohunkóhun tí ẹnì kan lè gba èlé. 20  Ìwọ lè mú kí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè+ san èlé, ṣùgbọ́n arákùnrin rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú kí ó san èlé;+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè bù kún ọ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ lórí ilẹ̀ tí ìwọ ń lọ, kí o bàa lè gbà á.+ 21  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà+ Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi sísan án+ falẹ̀, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ láìkùnà, ní tòótọ́, yóò sì di ẹ̀ṣẹ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ.+ 22  Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ fà sẹ́yìn láti jẹ́ ẹ̀jẹ́, kì yóò di ẹ̀ṣẹ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ.+ 23  Àsọjáde ètè rẹ ni kí ìwọ pa mọ́,+ kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti jẹ́jẹ̀ẹ́ gan-an fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe tí o fi ẹnu rẹ sọ.+ 24  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o lọ sínú ọgbà àjàrà ọmọnìkejì rẹ, kìkì èso àjàrà tí ó tó fún ọ ni kí ìwọ jẹ tẹ́ ọkàn rẹ lọ́rùn, ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi ìkankan sínú ìkóhunsí rẹ.+ 25  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o lọ sínú ọkà tí ó wà ní ìdúró tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ, àwọn ṣírí tí ó ti gbó nìkan ni kí o fi ọwọ́ rẹ já, ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi dòjé síwá-sẹ́yìn lórí ọkà tí ó wà ní ìdúró tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì  rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé