Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 22:1-30

22  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ rí akọ màlúù arákùnrin rẹ tàbí àgùntàn rẹ̀ tí ń ṣáko lọ, kí ìwọ sì mọ̀ọ́mọ̀ fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wọn.+ Lọ́nàkọnà, kí ìwọ mú wọn padà lọ bá arákùnrin+ rẹ.  Bí arákùnrin rẹ kò bá sí nítòsí rẹ, tí ìwọ kò sì mọ̀ ọ́n, kí ìwọ mú un wá sí ilé, sínú ilé rẹ, kí ó sì máa wà pẹ̀lú rẹ títí arákùnrin rẹ yóò fi wá a. Kí ìwọ sì dá a padà fún un.+  Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó ṣe sí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí aṣọ àlàbora rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí ohunkóhun tí ó bá sọnù tí ó jẹ́ ti arákùnrin rẹ, tí ó sọnù lọ́wọ́ rẹ̀, tí ìwọ sì rí. A kì yóò gbà ọ́ láyè láti fà sẹ́yìn.  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ arákùnrin rẹ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tí ó ṣubú lulẹ̀ lójú ọ̀nà, kí o sì mọ̀ọ́mọ̀ fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wọn. Lọ́nàkọnà, kí ìwọ ràn án lọ́wọ́ láti gbé wọn dìde.+  “Aṣọ èyíkéyìí tí í ṣe ti abarapá ọkùnrin ni a kò gbọ́dọ̀ fi wọ obìnrin, bẹ́ẹ̀ ni abarapá ọkùnrin kò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ obìnrin;+ nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìtẹ́ ẹyẹ kan wà níwájú rẹ ní ojú ọ̀nà, lórí igi èyíkéyìí tàbí lórí ilẹ̀ tòun ti àwọn ọmọ+ tàbí àwọn ẹyin, tí ìyá sì jókòó sórí àwọn ọmọ tàbí àwọn ẹyin náà, ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú ìyá náà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ.+  Rí i dájú pé o jẹ́ kí ìyá lọ, ṣùgbọ́n o lè kó àwọn ọmọ fún ara rẹ; kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí o sì lè mú ọjọ́+ rẹ gùn ní ti gidi.  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o kọ́ ilé tuntun, kí o ṣe ìgbátí sí òrùlé+ rẹ, kí ìwọ má bàa fi ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ sórí ilé rẹ nítorí pé ẹnì kan tí ń ṣubú lọ lè já bọ́ láti orí rẹ̀.  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn oríṣi méjì + sínú ọgbà àjàrà rẹ, kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àmújáde irúgbìn tí ìwọ bá fún àti àmújáde ọgbà àjàrà náà má bàa di èyí tí a sọ di ti ibùjọsìn. 10  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túlẹ̀ pa pọ̀.+ 11  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ wọ irú aṣọ aládàpọ̀ irun àgùntàn àti aṣọ ọ̀gbọ̀ pa pọ̀.+ 12  “Kí o ṣe wajawaja fún ara rẹ sí ẹ̀bẹ̀ẹ̀bátí mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aṣọ tí ìwọ fi ń bo ara rẹ.+ 13  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan fẹ́ aya kan, tí ó sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní tòótọ́, tí ó sì wá kórìíra obìnrin náà,+ 14  tí ó sì fi ẹ̀sùn ìṣe olókìkí burúkú kan obìnrin náà, tí ó sì mú orúkọ+ búburú wá sórí rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Èyí ni obìnrin tí mo fẹ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ ọn, èmi kò sì rí ẹ̀rí jíjẹ́ wúńdíá lára rẹ̀’;+ 15  kí baba ọ̀dọ́mọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ sì mú ẹ̀rí jíjẹ́ wúńdíá ọ̀dọ́mọbìnrin náà jáde wá fún àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá náà ní ẹnubodè rẹ̀;+ 16  kí baba ọ̀dọ́mọbìnrin náà sì wí fún àwọn àgbà ọkùnrin náà pé, ‘Mo fi ọmọbìnrin mi fún ọkùnrin yìí ní aya, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra+ rẹ̀. 17  Ẹ sì kíyè sí i, ó ń fi ẹ̀sùn ìṣe olókìkí burúkú+ kan obìnrin náà pé: “Mo rí i pé ọmọbìnrin rẹ kò ní ẹ̀rí jíjẹ́ wúńdíá.”+ Wàyí o, ẹ̀rí jíjẹ́ wúńdíá ọmọbìnrin mi rèé.’ Kí wọ́n sì tẹ́ aṣọ àlàbora náà síwájú àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá náà. 18  Kí àwọn àgbà ọkùnrin+ ìlú ńlá yẹn sì mú ọkùnrin náà, kí wọ́n sì bá a wí.+ 19  Kí wọ́n sì bu ọgọ́rùn-ún ṣékélì fàdákà lé e gẹ́gẹ́ bí ìtanràn, kí wọ́n sì fi wọ́n fún baba ọ̀dọ́mọbìnrin náà, nítorí pé ó mú orúkọ búburú wá sórí wúńdíá Ísírẹ́lì;+ yóò sì máa bá a lọ láti jẹ́ aya rẹ̀. A kì yóò gbà á láyè láti kọ obìnrin náà sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé ọkùnrin náà. 20  “Àmọ́ ṣá o, bí ó bá jẹ́ pé ohun yìí jẹ́ òtítọ́, tí a kò rí ẹ̀rí jíjẹ́ wúńdíá lára ọ̀dọ́mọbìnrin+ náà, 21  kí wọ́n mú ọ̀dọ́mọbìnrin náà jáde wá sí ẹnu ọ̀nà ilé baba rẹ̀, kí àwọn ọkùnrin ìlú ńlá rẹ̀ sì sọ ọ́ ní òkúta, kí ó sì kú, nítorí pé ó ti hu ìwà ẹ̀gọ̀ tí ń dójú tini+ ní Ísírẹ́lì nípa ṣíṣe kárùwà ní ilé baba rẹ̀.+ Nípa bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò mú ohun tí ó burú kúrò láàárín rẹ.+ 22  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a rí ọkùnrin kan tí ó sùn ti obìnrin kan tí ó jẹ́ ti ẹnì kan,+ nígbà náà kí àwọn méjèèjì  kú pa pọ̀, ọkùnrin tí ó sùn ti obìnrin náà àti obìnrin+ náà. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò mú ohun tí ó burú kúrò ní Ísírẹ́lì.+ 23  “Bí ó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀dọ́mọbìnrin wúńdíá kan wà, tí ọkùnrin kan fẹ́ sọ́nà,+ tí ọkùnrin kan, ní ti tòótọ́, sì rí i ní ìlú ńlá, tí ó sì sùn tì í,+ 24  kí ẹ mú àwọn méjèèjì  jáde wá sí ẹnubodè ìlú ńlá yẹn, kí ẹ sì sọ wọ́n ní òkúta, kí wọ́n sì kú, ọ̀dọ́mọbìnrin náà fún ìdí náà pé kò lọgun nínú ìlú ńlá náà, àti ọkùnrin náà fún ìdí náà pé ó tẹ́ aya ọmọnìkejì + rẹ̀ lógo. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò mú ohun tí ó jẹ́ ibi kúrò láàárín rẹ.+ 25  “Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó bá jẹ́ pé pápá ni ọkùnrin náà ti rí ọ̀dọ́mọbìnrin náà tí a fẹ́ sọ́nà, tí ọkùnrin náà sì rá a mú, tí ó sì sùn tì í, ọkùnrin tí ó sùn tì í yóò kú ní òun nìkan, 26  ọ̀dọ́mọbìnrin náà ni ìwọ kì yóò sì ṣe nǹkan kan fún. Ọ̀dọ́mọbìnrin náà kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan tí ó yẹ fún ikú, nítorí pé gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ọkùnrin kan dìde sí ọmọnìkejì  rẹ̀, tí ó sì ṣìkà pa á+ ní ti gidi, àní ọkàn kan, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí fún ẹjọ́ yìí. 27  Nítorí pápá ni ọkùnrin náà ti rí i. Ọ̀dọ́mọbìnrin tí a fẹ́ sọ́nà náà lọgun, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan láti gbà á sílẹ̀. 28  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan rí ọ̀dọ́mọbìnrin kan, wúńdíá tí a kò tíì fẹ́ sọ́nà, tí ọkùnrin náà, ní ti tòótọ́, sì gbá a mú, tí ó sì sùn tì í,+ tí a sì mú wọn,+ 29  ọkùnrin tí ó sùn tì í yóò fún baba ọ̀dọ́mọbìnrin náà ní àádọ́ta ṣékélì fàdákà,+ obìnrin náà yóò sì di aya rẹ̀ nítorí òtítọ́ náà pé ó tẹ́ obìnrin náà lógo. A kì yóò gbà á láyè láti kọ obìnrin náà sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́+ ayé ọkùnrin náà. 30  “Ọkùnrin kankan kò gbọ́dọ̀ gba aya baba rẹ̀, kí ó má bàa ṣí apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ baba rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé