Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 21:1-23

21  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a rí ẹnì kan tí a pa ní orí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ láti gbà, tí ó ṣubú sórí pápá, tí ẹni tí ó kọlù ú lọ́nà tí ó fi yọrí sí ikú+ kò sì di mímọ̀,  kí àwọn àgbà ọkùnrin rẹ àti àwọn onídàájọ́+ rẹ jáde lọ, kí wọ́n sì lọ wọnlẹ̀ dé àwọn ìlú ńlá tí ó wà ní gbogbo àyíká ẹni tí a pa náà;  yóò sì jẹ́ ìlú ńlá tí ó sún mọ́ ẹni tí a pa náà jù lọ. Kí àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá náà sì mú ẹgbọrọ abo màlúù láti inú ọ̀wọ́ ẹran tí a kò tíì fi ṣiṣẹ́, tí kò tíì fa àjàgà;  kí àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá yẹn sì mú ẹgbọrọ abo màlúù náà sọ̀ kalẹ̀ lọ sí àfonífojì  olójú ọ̀gbàrá tí omi ti ń ṣàn, nínú èyí tí kì í ti í sábà sí ilẹ̀ ríro tàbí fífúnrúgbìn, kí wọ́n sì ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ abo màlúù náà níbẹ̀ ní àfonífojì  olójú ọ̀gbàrá+ náà.  “Kí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, sì sún mọ́ tòsí, nítorí pé àwọn ni ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yàn láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un+ àti láti máa súre+ ní orúkọ Jèhófà àti ní ẹnu àwọn ẹni tí gbogbo awuyewuye lórí gbogbo ìwà ipá yóò ti yanjú kúrò nílẹ̀.+  Lẹ́yìn náà, kí gbogbo àgbà ọkùnrin ìlú ńlá yẹn, tí wọ́n sún mọ́ ẹni tí a pa náà jù lọ, wẹ ọwọ́+ wọn sórí ẹgbọrọ abo màlúù náà, ọrùn èyí tí a ṣẹ́ ní àfonífojì  olójú ọ̀gbàrá;  wọn yóò sì dáhùn, wọn yóò sì wí pé, ‘Ọwọ́ wa kò ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ojú wa kò rí i kí a ta á sílẹ̀.+  Jèhófà, má ṣe kà á sí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì lọ́rùn, àwọn tí o tún rà padà,+ má sì fi ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀+ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sí àárín àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì.’ Kí a má sì ka ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ náà sí wọn lọ́rùn.  Ìwọ—ìwọ yóò sì mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kúrò ní àárín+ rẹ, nítorí pé ìwọ yóò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú+ Jèhófà. 10  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o jáde lọ sí ibi ìjà ogun lòdì sí àwọn ọ̀tá rẹ, tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,+ tí o sì ti kó wọn lọ ní òǹdè;+ 11  tí ìwọ sì rí obìnrin kan tí ó lẹ́wà ní ìrísí lára àwọn òǹdè náà, tí ìwọ sì ti fà mọ́ ọn,+ tí o sì mú un ṣe aya rẹ, 12  nígbà náà, kí ìwọ mú un wá sí àárín ilé rẹ. Wàyí o, kí ó fá orí rẹ̀,+ kí ó sì bójú tó àwọn èékánná rẹ̀, 13  kí ó sì mú aṣọ àlàbora oko òǹdè kúrò lárá rẹ̀, kí ó sì máa gbé nínú ilé rẹ, kí ó sì sunkún baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ fún oṣù òṣùpá kan+ gbáko; àti lẹ́yìn ìyẹn, kí ìwọ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí o sì fi í ṣe ìyàwó rẹ, kí ó sì di aya rẹ. 14  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ìwọ kò bá ní inú dídùn sí i, nígbà náà, kí o rán an lọ,+ lọ́nà tí ó ṣètẹ́wọ́gbà ní ọkàn tirẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ má ṣe tà á gbowó rárá. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ hùwà sí i lọ́nà ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀+ lẹ́yìn tí ìwọ ti tẹ́ ẹ lógo. 15  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ní aya méjì , tí ó nífẹ̀ẹ́ ọ̀kan tí ó sì kórìíra èkejì , tí àwọn méjèèjì , ìyẹn ẹni tí a nífẹ̀ẹ́ àti ẹni tí a kórìíra, sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un, tí ọmọkùnrin àkọ́bí sì wá jẹ́ ti ẹni+ tí ó kórìíra, 16  yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ní ọjọ́ tí ó bá fi ohun tí ó ní fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, a kì yóò gbà á láyè láti sọ ọmọkùnrin ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ di àkọ́bí rẹ̀ sí àdánù ọmọkùnrin ẹni tí ó kórìíra, èyí àkọ́bí.+ 17  Nítorí ó yẹ kí ó múra tán láti gba ọmọkùnrin ẹni tí ó kórìíra gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí nípa fífi ipa méjì  fún un nínú ohun gbogbo tí a rí pé ó ní,+ nítorí pé ẹni yẹn ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ agbára ìbímọ+ rẹ̀. Ẹ̀tọ́ ipò àkọ́bí jẹ́ tirẹ̀.+ 18  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan wá ní ọmọ kan tí ó jẹ́ alágídí àti ọlọ̀tẹ̀,+ tí ó kì í fetí sí ohùn baba rẹ̀ tàbí ohùn ìyá+ rẹ̀, tí wọ́n sì ti tọ́ ọ sọ́nà ṣùgbọ́n tí kò jẹ́ fetí sí wọn,+ 19  kí baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ dì í mú, kí wọ́n sì mú un jáde lọ bá àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá rẹ̀ àti sí ẹnubodè ibi tí ó ń gbé,+ 20  kí wọ́n sì wí fún àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá rẹ̀ pé, ‘Ọmọ wa yìí jẹ́ alágídí àti ọlọ̀tẹ̀; kì í fetí sí ohùn wa,+ alájẹkì+ àti ọ̀mùtípara+ ni.’ 21  Nígbà náà, kí gbogbo ọkùnrin ìlú ńlá rẹ̀ sọ ọ́ ní òkúta, kí ó sì kú. Nípa bẹ́ẹ̀, kí o mú ohun tí ó burú kúrò láàárín rẹ, gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì gbọ́, àyà yóò sì fò+ wọ́n ní ti gidi. 22  “Bí ó bá sì wá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ní ẹ̀ṣẹ̀ tí ó yẹ fún ìdájọ́ ikú, tí a sì fi ikú pa+ á, tí ìwọ sì ti gbé e kọ́ sórí òpó igi,+ 23  kí òkú rẹ̀ má ṣe wà lórí òpó igi+ ní gbogbo òru; ṣùgbọ́n, lọ́nàkọnà, kí ẹ sin ín ní ọjọ́ yẹn, nítorí ohun ègún Ọlọ́run ni ẹni tí a gbé kọ́;+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ sọ ilẹ̀ rẹ di ẹlẹ́gbin, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé