Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Diutarónómì 20:1-20

20  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o jáde lọ sí ìjà ogun lòdì sí àwọn ọ̀tá rẹ, tí ìwọ ní ti gidi sì rí àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ ogun àwọn ènìyàn tí wọ́n pọ̀ níye jù ọ́ lọ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ fòyà wọn; nítorí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,+ ẹni tí ó mú ọ gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ẹ bá ti sún mọ́ ìjà ogun náà, kí àlùfáà pẹ̀lú sún mọ́ tòsí, kí ó sì bá àwọn ènìyàn+ sọ̀rọ̀.  Kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Gbọ́, Ísírẹ́lì, ẹ̀yin ń sún mọ́ ojú ìjà ogun lòdì sí àwọn ọ̀tá yín lónìí. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ojora+ mú ọkàn-àyà yín. Ẹ má fòyà, kí ẹ má sì fi ìbẹ̀rù jì nnìjì nnì sá tàbí kí ẹ gbọ̀n jì nnìjì nnì nítorí wọn,+  nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run yín ń bá yín lọ láti jà fún yín ní ìlòdìsí àwọn ọ̀tá yín, kí ó bàa lè gbà yín là.’+  “Kí àwọn onípò àṣẹ+ pẹ̀lú bá àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀ pé, ‘Ta ni ọkùnrin tí ó ti kọ́ ilé tuntun, tí kò sì tíì ṣe ayẹyẹ ṣíṣí i? Kí ó lọ, kí ó sì padà sí ilé rẹ̀, kí ó má bàa di pé ó kú nínú ìjà ogun, kí ọkùnrin mìíràn sì ṣe ayẹyẹ ṣíṣí i.+  Ta sì ni ọkùnrin tí ó gbin ọgbà àjàrà, tí kò sì tíì bẹ̀rẹ̀ sí lò ó? Kí ó lọ, kí ó sì padà sí ilé rẹ̀, kí ó má bàa di pé ó kú nínú ìjà ogun, kí ọkùnrin mìíràn sì bẹ̀rẹ̀ sí lò ó.+  Ta sì ni ọkùnrin tí ń fẹ́ obìnrin kan sọ́nà, tí kò sì tíì gbé e? Kí ó lọ, kí ó sì padà sí ilé rẹ̀,+ kí ó má bàa di pé ó kú nínú ìjà ogun, kí ọkùnrin mìíràn sì gbé e.’  Kí àwọn onípò àṣẹ sì bá àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀ síwájú sí i pé, ‘Ta ni ọkùnrin tí ń bẹ̀rù, tí ó sì ń ṣọkàn ojo?+ Kí ó lọ, kí ó sì padà sí ilé rẹ̀, kí ó má bàa mú kí ọkàn-àyà àwọn arákùnrin rẹ̀ domi bí ọkàn-àyà+ tirẹ̀ fúnra rẹ̀.’  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí àwọn onípò àṣẹ bá parí bíbá àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀, kí wọ́n yan àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun sí orí àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú. 10  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ sún mọ́ ìlú ńlá kan láti bá a jà, kí o fi ọ̀rọ̀ àlàáfíà lọ̀ ọ́.+ 11  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ó bá fi ìdáhùn àlàáfíà fún ọ, tí ó sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún yín, àní yóò ṣẹlẹ̀ pé gbogbo ènìyàn tí a bá rí nínú rẹ̀ yóò di tìrẹ fún òpò àfipámúniṣe, wọn yóò sì máa sìn ọ́.+ 12  Ṣùgbọ́n bí òun kò bá wá àlàáfíà pẹ̀lú rẹ,+ tí òun ní ti tòótọ́ sì bá ọ jagun, tí ìwọ sì ní láti sàga tì í, 13  Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì fi í lé ọ lọ́wọ́ dájúdájú, ìwọ yóò sì fi ojú idà+ kọlu olúkúlùkù ọkùnrin nínú rẹ̀. 14  Kì kì àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké+ àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀+ àti ohun gbogbo tí ó bá wà nínú ìlú ńlá náà, gbogbo ohun ìfiṣèjẹ rẹ̀ ni kí o piyẹ́ fún ara rẹ;+ kí o sì jẹ ohun ìfiṣèjẹ àwọn ọ̀tá rẹ, tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.+ 15  “Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò ṣe sí gbogbo ìlú ńlá tí ó jì nnà réré sí ọ, tí wọn kò sí lára àwọn ìlú ńlá àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí. 16  Kì kì lára àwọn ìlú ńlá àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ pa ohun eléèémí kankan mọ́ láàyè,+ 17  nítorí pé ìwọ kò gbọ́dọ̀ kùnà láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun, àwọn ọmọ Hétì àti àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún ọ; 18  kí wọ́n má bàa kọ́ yín láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn, èyí tí wọ́n ti ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kí ẹ̀yin ní tòótọ́ sì ṣẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run+ yín. 19  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o sàga tì ìlú ńlá kan fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, nìpa bíbá a jà láti gbà á, ìwọ kò gbọ́dọ̀ run àwọn igi rẹ̀ nípa yíyọ àáké tì wọ́n; nítorí pé ìwọ yóò máa jẹ nínú wọn, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ gé wọn lulẹ̀,+ nítorí, ṣé ènìyàn ni igi pápá jẹ́ tí ìwọ yóò fi sàga tì í? 20  Kì kì igi tí o mọ̀ pé kì í ṣe igi fún oúnjẹ, òun ni kí ìwọ run, kí o gé e lulẹ̀, kí o sì sọ agbàrà+ ti ìlú ńlá náà tí ń bá ọ jagun, títí yóò fi wó lulẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé