Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Diutarónómì 2:1-37

2  “Lẹ́yìn náà, a yí padà, a sì ṣí kúrò lọ sí aginjù ní gbígba ti Òkun Pupa, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún mi;+ a sì lo ọ̀pọ̀ ọjọ́ ní lílọ yí ká Òkè Ńlá Séírì.  Níkẹyìn, Jèhófà sọ èyí fún mi pé,  ‘Ẹ ti lọ yí ká òkè ńlá yìí pẹ́ tó.+ Ẹ yíjú padà sí àríwá.  Sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ibi ojú ààlà àwọn arákùnrin yín,+ àwọn ọmọ Ísọ̀,+ tí wọ́n ń gbé ní Séírì+ ní ẹ ó gbà kọjá; àyà yóò sì fò wọ́n nítorí yín,+ ẹ sì ní láti kíyè sára gidigidi.  Ẹ má ṣe kó wọnú gbọ́nmi-si omi-ò-to pẹ̀lú wọn, nítorí bí ó tilẹ̀ ṣe ìwọ̀n fífẹ̀ àtẹ́lẹsẹ̀ ni, èmi kì yóò fún yín lára ilẹ̀ wọn; nítorí tí mo ti fi Òkè Ńlá Séírì fún Ísọ̀ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.+  Oúnjẹ tí ẹ bá fi owó rà lọ́dọ̀ wọn ni kí ẹ jẹ; omi tí ẹ bá sì fi owó rà lọ́dọ̀ wọn ni kí ẹ mu.+  Nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti bù kún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ gbogbo.+ Ó mọ̀ dáadáa nípa rírìn tí o ń rìn la aginjù ńlá yìí já. Fún ogójì + ọdún wọ̀nyí, Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà pẹ̀lú rẹ. Ìwọ kò ṣaláìní ohun kan.”’+  Nítorí náà, a gba ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa kọjá, àwọn ọmọ Ísọ̀,+ tí wọ́n ń gbé ní Séírì, láti ọ̀nà ti Árábà,+ láti Élátì àti láti Esioni-gébérì.+ “Lẹ́yìn èyí, a yí padà, a sì gba ti ọ̀nà aginjù Móábù+ kọjá lọ.  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún mi pé, ‘Má ṣe fìtínà Móábù tàbí kí o kó wọnú ogun pẹ̀lú wọn, nítorí èmi kì yóò fún ọ ní èyíkéyìí lára ilẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní, nítorí àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì+ ni mo ti fi Árì+ fún gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní. 10  (Àwọn Émímù+ ń gbé inú rẹ̀ ní ìgbà àtijọ́, àwọn ènìyàn kan tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì pọ̀ níye, tí wọ́n sì ga bí àwọn Ánákímù.+ 11  Ní ti àwọn Réfáímù,+ àwọn pẹ̀lú ni a kà sí pé wọ́n dà bí àwọn Ánákímù,+ àwọn ọmọ Móábù a sì máa pè wọ́n ní Émímù. 12  Àwọn Hórì+ sì ń gbé ní Séírì ní ìgbà àtijọ́, àwọn ọmọ Ísọ̀+ sì tẹ̀ síwájú láti lé wọn kúrò àti láti pa wọ́n rẹ́ ráúráú kúrò níwájú wọn àti láti máa gbé ní àyè wọn,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Ísírẹ́lì yóò ti ṣe sí ilẹ̀ tí ó jẹ́ ilẹ̀ ìní rẹ̀, èyí tí Jèhófà yóò fi fún wọn dájúdájú.) 13  Lọ́tẹ̀ yìí, ẹ dìde, kí ẹ sì mú ọ̀nà yín pọ̀n ní sísọdá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Séréédì.’+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a bẹ̀rẹ̀ sí sọdá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Séréédì. 14  Àwọn ọjọ́ tí a sì fi rìn láti Kadeṣi-bánéà títí a fi sọdá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Séréédì jẹ́ ọdún méjì dínlógójì , títí gbogbo ìran àwọn ọkùnrin ogun fi wá sí òpin wọn ní àárín ibùdó, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti búra fún wọn.+ 15  Ọwọ́+ Jèhófà pẹ̀lú sì wà lára wọn láti kó ìdààmú bá wọn láàárín ibùdó náà, títí wọ́n fi wá sí òpin wọn.+ 16  “Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí gbogbo àwọn ọkùnrin ogun ti kú tán láàárín àwọn ènìyàn náà,+ 17  Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀ síwáju sí i pé, 18  ‘Ìwọ yóò kọjá lónìí ní ìpínlẹ̀ Móábù, ìyẹn ni, Árì,+ 19  ìwọ yóò sì sún mọ́ iwájú àwọn ọmọ Ámónì. Má ṣe fìtínà wọn tàbí kí o kó wọnú gbọ́nmi-si omi-ò-to pẹ̀lú wọn, nítorí èmi kì yóò fún ọ ní èyíkéyìí lára ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní, nítorí àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì ni mo ti fi í fún gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.+ 20  Ilẹ̀ àwọn Réfáímù+ ni a ti sábà máa ń kà á sí pẹ̀lú. (Àwọn Réfáímù ń gbé inú rẹ̀ ní ìgbà àtijọ́, àwọn ọmọ Ámónì a sì máa pè wọ́n ní Sámúsúmímù. 21  Wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì pọ̀ níye, tí wọ́n sì ga bí àwọn Ánákímù;+ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n rẹ́ ráúráú+ kúrò níwájú wọn, kí wọ́n bàa lè lé wọn kúrò, kí wọ́n sì máa gbé ní àyè wọn; 22  gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún àwọn ọmọ Ísọ̀, tí wọ́n ń gbé ní Séírì,+ nígbà tí ó pa àwọn Hórì+ rẹ́ ráúráú kúrò níwájú wọn, kí wọ́n bàa lè lé wọn kúrò, kí wọ́n sì máa gbé ní àyè wọn títí di òní yìí. 23  Ní ti àwọn Áfímù,+ tí wọ́n ń gbé ní àwọn ibi ìtẹ̀dó títí dé Gásà,+ àwọn Káfítórímù,+ tí wọ́n wá láti Káfítórì,+ pa wọ́n rẹ́ ráúráú, kí wọ́n bàa lè máa gbé ní àyè wọn.) 24  “‘Ẹ dìde, ẹ ṣí kúrò kí ẹ sì sọdá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì.+ Ẹ wò ó, mo ti fi Síhónì+ ọba Hẹ́ṣíbónì, tí í ṣe Ámórì, lé ọ lọ́wọ́. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí gba ilẹ̀ rẹ̀, kí ẹ sì kó wọnú ogun pẹ̀lú rẹ̀. 25  Ní òní yìí, èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ rẹ àti ìbẹ̀rù rẹ sí iwájú àwọn ènìyàn tí ń bẹ lábẹ́ gbogbo ọ̀run, àwọn tí yóò gbọ́ ìròyìn nípa rẹ; àti pé ní tòótọ́, a óò kó ṣìbáṣìbo bá wọn, wọn yóò sì ní ìrora bí ti ìbímọ nítorí rẹ.’+ 26  “Nígbà náà ni mo fi àwọn ọ̀rọ̀ àlàáfíà+ rán àwọn ońṣẹ́ láti aginjù Kédémótì+ sí Síhónì+ ọba Hẹ́ṣíbónì pé, 27  ‘Jẹ́ kí n la ilẹ̀ rẹ kọjá. Ojú ọ̀nà nìkan ni èmi yóò rìn. Èmi kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+ 28  Oúnjẹ tí ìwọ bá tà gbowó lọ́wọ́ mi ni èmi yóò jẹ; omi tí mo bá sì fi owó rà lọ́wọ́ rẹ ni èmi yóò mu. Kì kì kí o sáà jẹ́ kí n fi ẹsẹ̀ mi là á kọjá,+ 29  gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísọ̀ tí wọ́n ń gbé ní Séírì+ àti àwọn ọmọ Móábù+ tí wọ́n ń gbé ní Árì ti ṣe fún mi, títí èmi yóò fi ré Jọ́dánì kọjá sí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wa yóò fi fún wa.’+ 30  Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì kò sì jẹ́ kí a la ọ̀dọ̀ òun kọjá, nítorí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ di èyí tí ó ṣoríkunkun,+ kí ọkàn-àyà rẹ̀ pẹ̀lú sì di líle, kí ó bàa lè fi í lé ọ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí.+ 31  “Látàrí èyí, Jèhófà wí fún mi pé, ‘Wò ó, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí jọ̀wọ́ Síhónì àti ilẹ̀ rẹ̀ fún ọ. Bẹ̀rẹ̀ sí gba ilẹ̀ rẹ̀.’+ 32  Nígbà tí Síhónì jáde wá, òun àti gbogbo ènìyàn rẹ̀, láti pàdé wa nínú ìjà ogun ní Jáhásì,+ 33  nígbà náà ni Jèhófà Ọlọ́run wa jọ̀wọ́ rẹ̀ fún wa,+ tí a fi ṣẹ́gun òun+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn rẹ̀. 34  A sì bẹ̀rẹ̀ sí gba gbogbo ìlú ńlá rẹ̀ ní àkókò yẹn gan-an, tí a sì ń ya olúkúlùkù ìlú ńlá sọ́tọ̀ fún ìparun,+ àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké. A kò ṣẹ́ olùlàájá kankan kù. 35  Àwọn ẹran agbéléjẹ̀ nìkan ni a kó gẹ́gẹ́ bí ohun tí a piyẹ́ fún ara wa, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ohun ìfiṣèjẹ tí ó wà ní àwọn ìlú ńlá tí a gbà.+ 36  Láti Áróérì,+ èyí tí ó wà ní bèbè àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì, àti ìlú ńlá tí ó wà ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, títí dé Gílíádì, kò sí ìlú kankan tí ó ga jù fún wa.+ Jèhófà Ọlọ́run wa jọ̀wọ́ gbogbo wọn fún wa. 37  Kì kì pé ìwọ kò sún mọ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ gbogbo bèbè àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Jábókù,+ tàbí àwọn ìlú ńlá ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà, tàbí ohunkóhun nípa èyí tí Jèhófà Ọlọ́run wa ti pa àṣẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé