Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 19:1-21

19  “Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ké àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi ilẹ̀ wọn fún ọ kúrò, tí ìwọ sì lé wọn kúrò, tí o sì ń gbé nínú àwọn ìlú ńlá wọn àti ilé wọn,+  ìwọ yóò ya ìlú ńlá mẹ́ta sọ́tọ̀ gedegbe fún ara rẹ ní àárín ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ láti gbà.+  Ìwọ yóò pèsè ọ̀nà sílẹ̀ fún ara rẹ, ìwọ yóò sì pín ìpínlẹ̀ ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bẹ̀rẹ̀ sí fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní sí apá mẹ́ta, yóò sì wà fún gbogbo apànìyàn láti sá lọ sí ibẹ̀.+  “Wàyí o, èyí ni ẹjọ́ apànìyàn tí ó lè sá lọ sí ibẹ̀, kí ó sì wà láàyè: Nígbà tí ó bá kọlu ọmọnìkejì  rẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀, tí kì í sì í ṣe olùkórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí;+  tàbí nígbà tí ó bá bá ọmọnìkejì  rẹ̀ lọ sínú ẹgàn láti lọ ṣẹ́ igi, tí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi àáké gé igi, tí irin náà sì fò yọ kúrò lára ẹ̀rú,+ tí ó sì ba ọmọnìkejì  rẹ̀, tí ó sì kú, kí ó fúnra rẹ̀ sá lọ sí ọ̀kan lára ìlú ńlá wọ̀nyí, yóò sì wà láàyè.+  Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, olùgbẹ̀san+ ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ọkàn-àyà rẹ̀ gbóná, lè lépa apànìyàn náà, kí ó sì lé e bá ní ti gidi, níwọ̀n bí ọ̀nà náà ti jì n; ní tòótọ́, ó sì lè kọlu ọkàn rẹ̀ lọ́nà tí ó yọrí sí ikú, nígbà tí ó jẹ́ pé kò sí ìdájọ́ ikú+ kankan fún un, nítorí òun kì í ṣe olùkórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí.  Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé, ‘Ìlú ńlá mẹ́ta ni ìwọ yóò yà sọ́tọ̀ gedegbe fún ara rẹ.’+  “Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá sì mú ìpínlẹ̀ rẹ gbòòrò síwájú, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó búra fún àwọn baba ńlá+ rẹ, tí ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún ọ, èyí tí ó ṣèlérí láti fi fún àwọn baba ńlá+ rẹ,  nítorí tí ìwọ yóò pa gbogbo àṣẹ yìí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́ nípa títẹ̀lé e, láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀ nígbà gbogbo,+ nígbà náà, kí ìwọ fi ìlú ńlá mẹ́ta mìíràn kún àwọn mẹ́ta+ wọ̀nyí fún ara rẹ, 10  kí a má bàa ta ẹ̀jẹ̀+ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kankan sílẹ̀ ní àárín ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ó má sì sí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kankan lórí rẹ.+ 11  “Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan wà tí ó kórìíra+ ọmọnìkejì  rẹ̀, tí ó sì lúgọ dè é, tí ó sì dìde sí i, tí ó sì kọlu ọkàn rẹ̀ lọ́nà tí ó yọrí sí ikú, tí ó sì kú,+ tí ọkùnrin náà sì sá lọ sí ọ̀kan lára ìlú ńlá wọ̀nyí, 12  nígbà náà, kí àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá rẹ̀ ránṣẹ́ lọ mú un níbẹ̀, kí wọ́n sì fi í lé olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, ó sì gbọ́dọ̀ kú.+ 13  kí ojú rẹ má ṣe káàánú rẹ̀,+ kí ìwọ sì mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kúrò ní Ísírẹ́lì,+ kí o lè ní ire. 14  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sún ààlà ọmọnìkejì + rẹ sẹ́yìn, nígbà tí àwọn baba ńlá ìgbàanì bá ti pa ààlà ogún rẹ tí ìwọ yóò jogún ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ láti gbà. 15  “Kí ẹyọ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo má ṣe dìde sí ọkùnrin kan nípa ìṣìnà èyíkéyìí tàbí ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí,+ nínú ọ̀ran ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí tí ó bá dá. Ẹnu ẹlẹ́rìí méjì  tàbí ẹnu ẹlẹ́rìí mẹ́ta ni kí ọ̀ràn náà fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa.+ 16  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹlẹ́rìí kan tí ń pète-pèrò ohun àìtọ́ bá dìde sí ọkùnrin kan láti mú ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ wá lòdì sí i,+ 17  àwọn ọkùnrin méjèèjì  tí wọ́n ní awuyewuye náà yóò sì dúró níwájú Jèhófà, níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn onídàájọ́ tí yóò máa gbéṣẹ́ ṣe ní ọjọ́+ wọnnì. 18  Kí àwọn onídàájọ́ náà sì ṣàyẹ̀wò fínnífínní,+ bí ẹlẹ́rìí náà bá sì jẹ́ ẹlẹ́rìí èké, tí ó sì mú ẹ̀sùn èké wá lòdì sí arákùnrin rẹ̀, 19  kí ẹ̀yin náà ṣe sí i, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pète-pèrò láti ṣe sí arákùnrin rẹ̀,+ kí ìwọ sì mú ohun tí ó burú kúrò láàárín rẹ.+ 20  Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn tí ó kù yóò gbọ́, àyà yóò sì fò wọ́n, wọn kì yóò sì tún ṣe ohunkóhun tí ó burú bí èyí mọ́ láé láàárín rẹ.+ 21  Kí ojú rẹ má sì káàánú:+ ọkàn fún ọkàn, ojú fún ojú, eyín fún eyín, ọwọ́ fún ọwọ́, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀+ ni yóò jẹ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé