Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 18:1-22

18  “Kí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, gbogbo ẹ̀yà Léfì+ pátá, má ṣe bá Ísírẹ́lì ní ìpín tàbí ogún kankan. Àwọn ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun sí Jèhófà, àní ogún rẹ̀ pàápàá, ni kí wọ́n máa jẹ.+  Nítorí náà, kí ogún kankan má ṣe wá jẹ́ tirẹ̀ ní àárín àwọn arákùnrin rẹ̀. Jèhófà ni ogún+ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún un gan-an.  “Wàyí o, kí èyí máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó fi ẹran ẹbọ rúbọ, yálà akọ màlúù tàbí àgùntàn: Kí ẹni náà fi ibi palaba èjì ká àti páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ àti àpòlúkù fún àlùfáà.  Àkọ́kọ́ nínú ọkà rẹ, wáìnì rẹ tuntun àti òróró rẹ àti àkọ́kọ́ nínú irun tí a rẹ́ lára agbo ẹran rẹ ni kí o fi fún un.+  Nítorí òun ni ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yàn nínú gbogbo ẹ̀yà rẹ láti dúró láti máa ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Jèhófà, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, nígbà gbogbo.+  “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ọmọ Léfì lọ kúrò nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá rẹ ní gbogbo Ísírẹ́lì, níbi tí ó ti gbé fún ìgbà díẹ̀,+ tí ó sì dé ní tìtorí ìfàsí ọkàn rẹ̀ èyíkéyìí, sí ibi tí Jèhófà yóò yàn,+  kí ó ṣèránṣẹ́ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bákan náà bí gbogbo arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Léfì, tí wọ́n dúró níbẹ̀ níwájú Jèhófà.+  Ìpín ọgbọọgba ni kí ó jẹ,+ ní àfikún sí ohun tí ó rí láti inú àwọn ohun tí ó tà nínú àwọn ẹrù ti baba ńlá rẹ̀ ìgbàanì.  “Nígbà tí a bá mú ọ dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ kọ́ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí àwọn orílẹ̀-èdè+ wọnnì. 10  Kí a má ṣe rí láàárín rẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ń mú ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ la iná+ kọjá, ẹnikẹ́ni tí ń woṣẹ́,+ pidánpidán+ kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀+ tàbí oníṣẹ́ oṣó,+ 11  tàbí ẹni tí ń fi èèdì+ di àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò+ tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀+ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú.+ 12  Nítorí gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ní tìtorí ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọ̀nyí sì ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi lé wọn lọ kúrò níwájú rẹ.+ 13  Kí o fi ara rẹ hàn ní aláìní-àléébù lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ. 14  “Nítorí orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí ìwọ yóò lé kúrò a máa fetí sí àwọn tí ń pidán+ àti àwọn tí ń woṣẹ́;+ ṣùgbọ́n ní ti ìwọ, Jèhófà Ọlọ́run rẹ kò fi ohunkóhun bí èyí fún ọ.+ 15  Wòlíì kan láti àárín ìwọ fúnra rẹ, ní àárín àwọn arákùnrin rẹ, bí èmi, ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò gbé dìde fún ọ—òun ni kí ẹ̀yin fetí sí—+ 16  ní ìdáhùn sí gbogbo ohun tí o béèrè lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní Hórébù ní ọjọ́ ìpéjọ,+ pé, ‘Má ṣe tún jẹ́ kí n gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run mi mọ́, má sì jẹ́ kí n rí iná títóbi yìí mọ́ rárá, kí èmi má bàa kú.’+ 17  Látàrí èyí, Jèhófà wí fún mi pé, ‘Wọ́n ṣe dáadáa ní sísọ ohun tí wọ́n sọ.+ 18  Wòlíì kan ni èmi yóò gbé dìde fún wọn ní àárín àwọn arákùnrin wọn, bí ìwọ;+ ní tòótọ́, èmi yóò sì fi àwọn ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu+ rẹ̀, dájúdájú, òun yóò sì sọ gbogbo ohun tí èmi yóò pa láṣẹ fún un+ fún wọn. 19  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ẹni tí kò bá fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi tí òun yóò sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra mi yóò béèrè fún ìjíhìn lọ́wọ́ rẹ̀.+ 20  “‘Bí ó ti wù kí ó rí, wòlíì náà tí ó kùgbù sọ ọ̀rọ̀ kan ní orúkọ mi, tí èmi kò pa láṣẹ fún un láti sọ,+ tàbí tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ àwọn ọlọ́run+ mìíràn, wòlíì yẹn gbọ́dọ̀ kú.+ 21  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ìwọ sọ nínú ọkàn-àyà rẹ pé: “Báwo ni àwa yóò ṣe mọ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà kò sọ?”+ 22  nígbà tí wòlíì náà bá sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà, tí ọ̀rọ̀ náà kò sì ṣẹlẹ̀ tàbí kí ó ṣẹ ní ti gidi, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà kò sọ. Ìkùgbù ni wòlíì náà fi sọ ọ́.+ Jìnnìjì nnì kò gbọ́dọ̀ bá ọ nítorí rẹ̀.’+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé