Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Diutarónómì 16:1-22

16  “Máa pa oṣù Ábíbù mọ́,+ kí o sì máa ṣe ayẹyẹ ìrékọjá fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ nítorí pé oṣù Ábíbù ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ mú ọ jáde kúrò ní Íjíbítì ní òru.+  Kí o sì fi ìrékọjá náà rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, nínú agbo ẹran àti nínú ọ̀wọ́ ẹran,+ ní ibi tí Jèhófà yóò yàn láti mú kí orúkọ rẹ̀ máa gbé.+  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó ní ìwúkàrà pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún ọjọ́ méje.+ Kí o jẹ ẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àkàrà aláìwú, oúnjẹ ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́, nítorí pé ní kánjúkánjú ni o jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kí o lè rántí ọjọ́ ìjáde rẹ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ.+  Kí a má sì ṣe rí ìyẹ̀fun àpòrọ́ kíkan èyíkéyìí pẹ̀lú rẹ ní gbogbo ìpínlẹ̀ rẹ fún ọjọ́ méje,+ bẹ́ẹ̀ ni kí èyíkéyìí nínú ẹran tí ẹ ó fi rúbọ ní alẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́, má ṣe wà láti òru títí di òwúrọ̀.+  A kì yóò gbà ọ́ láyè láti fi ìrékọjá náà rúbọ ní èyíkéyìí nínú àwọn ìlú ńlá rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ.  Ṣùgbọ́n ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò yàn láti mú kí orúkọ rẹ̀ máa gbé+ ni kí o ti fi ìrékọjá náà rúbọ ní alẹ́ ní gbàrà tí oòrùn bá ti wọ̀,+ ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ tí ìwọ jáde kúrò ní Íjíbítì.  Kí o sì sè é, kí o sì jẹ ẹ́+ ní ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò yàn,+ kí o sì yíjú padà ní òwúrọ̀, kí o sì lọ sí àwọn àgọ́ rẹ.  Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi jẹ àwọn àkàrà aláìwú; àti ní ọjọ́ keje, àpéjọ ọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ yóò wà. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.  “Ọ̀sẹ̀ méje ni kí o kà fún ara rẹ. Bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí a kọ́kọ́ ti dòjé bọ ọkà tí ó wà ní ìdúró ni ìwọ yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí ka ọ̀sẹ̀ méje+ náà. 10  Lẹ́yìn náà ni kí o ṣe àjọyọ̀ àwọn ọ̀sẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, ní ìbámu pẹ̀lú ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe ọwọ́ rẹ tí ìwọ yóò mú wá, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ti bù kún ọ.+ 11  Kí o sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti ọmọ Léfì tí ó wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ àti àtìpó+ àti ọmọdékùnrin aláìníbaba+ àti opó,+ tí wọ́n wà ní àárín rẹ, ní ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò yàn láti mú kí orúkọ rẹ̀ máa gbé.+ 12  Kí o sì rántí pé o di ẹrú ní Íjíbítì,+ kí o sì máa pa ìlànà+ wọ̀nyí mọ́, kí o sì máa mú wọn ṣe. 13  “Àjọyọ̀ àwọn àtíbàbà+ ni kí o máa ṣe ayẹyẹ rẹ̀ fún ara rẹ fún ọjọ́ méje, nígbà tí o bá ṣe ìkórèwọlé ilẹ̀ ìpakà rẹ àti ibi ìfún-òróró àti ìfúntí wáìnì rẹ. 14  Kí o sì máa yọ̀ nígbà àjọyọ̀ rẹ,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti ọmọ Léfì àti àtìpó àti ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó, tí wọ́n wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ. 15  Ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi ṣe àjọyọ̀+ náà fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ibi tí Jèhófà yóò yàn, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò bù kún+ ọ nínú gbogbo èso rẹ àti nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, kí ìwọ sì kún fún ìdùnnú.+ 16  “Ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún, kí gbogbo tìrẹ tí ó jẹ́ ọkùnrin fara hàn níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ibi tí òun yóò yàn:+ ní àjọyọ̀ àwọn àkàrà aláìwú+ àti ní àjọyọ̀ àwọn ọ̀sẹ̀+ àti ní àjọyọ̀ àwọn àtíbàbà,+ kí ẹnì kankan má sì fara hàn níwájú Jèhófà lọ́wọ́ òfo.+ 17  Kí ẹ̀bùn ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ní ìwọ̀n ìbùkún Jèhófà Ọlọ́run rẹ èyí tí ó ti fi fún ọ.+ 18  “Kí o yan àwọn onídàájọ́+ àti àwọn onípò àṣẹ+ fún ara rẹ nínú gbogbo ẹnubodè rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà rẹ, kí wọ́n sì fi ìdájọ́ òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn náà. 19  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ yí ìdájọ́ po.+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú+ tàbí kí o gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ojú àwọn ọlọ́gbọ́n,+ a sì máa fi èrú yí ọ̀rọ̀ àwọn olódodo po. 20  Ìdájọ́ òdodo—ìdájọ́ òdodo ni kí ìwọ máa lépa,+ kí ìwọ bàa lè máa wà láàyè nìṣó, kí ìwọ ní ti gidi sì lè gba ilẹ̀ náà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ.+ 21  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ri irú igi èyíkéyìí mọ́lẹ̀ bí òpó ọlọ́wọ̀ fún ara rẹ nítòsí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí ìwọ yóò ṣe fún ara rẹ.+ 22  “Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má ṣe gbé ọwọ̀n ọlọ́wọ̀+ nà ró fún ara rẹ, ohun kan tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ kórìíra ní tòótọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé