Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 15:1-23

15  “Ní òpin ọdún méje-méje, kí o máa ṣe ìtúsílẹ̀.  Èyí sì ni irú ọ̀nà ìtúsílẹ̀+ náà: ìtúsílẹ̀ yóò wà láti ọwọ́ olúkúlùkù ẹni tí a jẹ ní gbèsè lórí gbèsè tí ó lè gbà kí ọmọnìkejì  rẹ̀ jẹ. Kí ó má ṣe fipá mú ọmọnìkejì  rẹ̀ tàbí arákùnrin rẹ̀ fún sísan,+ nítorí pé ìtúsílẹ̀ fún Jèhófà ni a ó pè.+  Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè+ ni o lè fipá mú fún sísan; ṣùgbọ́n ohun yòówù tí ó bá jẹ́ tìrẹ tí ó bá wà lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ ni kí o jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tú sílẹ̀.  Bí ó ti wù kí ó rí, kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ́ òtòṣì láàárín rẹ, nítorí pé, láìkùnà, Jèhófà yóò bù kún+ ọ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún láti gbà,+  kìkì bí ìwọ kì yóò bá kùnà láti fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ kí o lè kíyè sára láti pa gbogbo àṣẹ yìí tí mo ń pa fún ọ lónìí+ mọ́.  Nítorí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò bù kún ọ, ní tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ gan-an, dájúdájú, ìwọ yóò sì wín+ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú gbígba ohun ìdógò, nígbà tí ó jẹ́ pé ìwọ fúnra rẹ kì yóò yá nǹkan; ìwọ yóò sì jọba lé orí àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀, nígbà tí ó jẹ́ pé ìwọ ni wọn kì yóò jọba lé lórí.+  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀kan lárá àwọn arákùnrin rẹ di òtòṣì láàárín rẹ nínú ọ̀kan lárá àwọn ìlú ńlá rẹ, ní ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ sé ọkàn-àyà rẹ le tàbí kí ó háwọ́ sí arákùnrin rẹ tí ó jẹ́ òtòṣì.+  Nítorí ìwọ ní láti fi ìwà ọ̀làwọ́ la ọwọ́ rẹ sí i,+ kí o sì wín in lọ́nàkọnà pẹ̀lú gbígba ohun ìdógò, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n tí ó ń fẹ́ ti pọ̀ tó, èyí tí ó ṣe aláìní.  Ṣọ́ ara rẹ, kí ọ̀rọ̀ játijàti má bàa wà nínú ọkàn-àyà+ rẹ pé, ‘Ọdún keje, ọdún ìtúsílẹ̀, ti sún mọ́lé,’+ kí ojú rẹ sì di aláìláàánú ní ti gidi sí arákùnrin rẹ tí ó jẹ́ òtòṣì,+ kí ìwọ má sì fún un ní nǹkan kan, tí ó sì ní láti ké pe Jèhófà sí ọ,+ tí ó sì di ẹ̀ṣẹ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ.+ 10  Kí o fi fún un lọ́nàkọnà,+ kí ọkàn-àyà rẹ má sì ṣahun nínú fífi fún un, nítorí pé ní tìtorí èyí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò ṣe bù kún ọ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ àti nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.+ 11  Nítorí òtòṣì kì yóò kásẹ̀ nílẹ̀ láé láàárín ilẹ̀+ náà. Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé, ‘Kí o fi ìwà ọ̀làwọ́ la ọwọ́ rẹ sí arákùnrin rẹ tí ó jẹ́ òtòṣì, tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ní ilẹ̀+ rẹ.’ 12  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a ta arákùnrin rẹ fún ọ, tí ó jẹ́ ọkùnrin Hébérù tàbí obìnrin Hébérù,+ tí ó sì ti sìn ọ fún ọdún mẹ́fà, nígbà náà, ní ọdún keje, kí o rán an jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ ní ẹni tí a dá sílẹ̀ lómìnira.+ 13  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé o rán an jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ ní ẹni tí a dá sílẹ̀ lómìnira, ìwọ kò gbọ́dọ̀ rán an jáde lọ́wọ́ òfo.+ 14  Dájúdájú, kí o fi ohun kan láti inú agbo ẹran rẹ àti ilẹ̀ ìpakà rẹ àti ibi ìfún-òróró àti ìfúntí wáìnì rẹ mú un gbára dì. Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti bù kún ọ gan-an ni kí o ṣe fi fún un.+ 15  Kí o sì rántí pé o di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì, tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì tẹ̀ síwájú láti tún ọ rà padà.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ ohun yìí fún ọ lónìí. 16  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ó bá wí fún ọ pé, ‘Èmi kì yóò jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ!’ nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ ìwọ àti agbo ilé rẹ ní ti gidi, níwọ̀n bí nǹkan ti dára fún un nígbà tí ó wà pẹ̀lú rẹ,+ 17  kí ìwọ mú òòlu kí o sì fi dá etí rẹ̀ lu mọ́ ara ilẹ̀kùn, òun yóò sì di ẹrú rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Kí o sì ṣe báyìí sí ẹrúbìnrin rẹ pẹ̀lú. 18  Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun kan tí ó le ní ojú rẹ nígbà tí o bá rán an jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ ní ẹni tí a dá sílẹ̀ lómìnira;+ nítorí pé ní ìlọ́po méjì  iye owó lébìrà+ tí a háyà ni ó sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì ti bù kún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá ṣe.+ 19  “Gbogbo àkọ́bí tí ó jẹ́ akọ tí a óò bí nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti nínú agbo ẹran rẹ ni kí o sọ di mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi àkọ́bí màlúù rẹ tí ó jẹ́ akọ ṣe iṣẹ́ kankan, bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe rẹ́ irun àkọ́bí agbo ẹran rẹ.+ 20  Iwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o ti máa jẹ ẹ́ lọ́dọọdún ní ibi tí Jèhófà yóò yàn,+ ìwọ àti agbo ilé rẹ. 21  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àbùkù kan wà lára rẹ̀, tí ó jẹ́ arọ tàbí afọ́jú, àbùkù búburú èyíkéyìí, ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi í rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ. 22  Inú àwọn ẹnubodè rẹ ni kí o ti jẹ ẹ́, aláìmọ́ àti ẹni tí ó mọ́ lápapọ̀,+ bí àgbàlàǹgbó àti bí akọ àgbọ̀nrín.+ 23  Kì kì ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ.+ Orí ilẹ̀ ni kí o dà á jáde sí bí omi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé