Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 14:1-29

14  “Ọmọ Jèhófà Ọlọ́run+ yín ni ẹ̀yin jẹ́. Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ kọ+ ara yín ní abẹ tàbí kí ẹ mú iwájú orí ara yín pá+ nítorí òkú.  Nítorí ènìyàn mímọ́+ ni o jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, Jèhófà sì ti yàn ọ́ láti di ènìyàn rẹ̀, àkànṣe dúkìá,+ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ irú ohun èyíkéyìí tí ó jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.+  Irú èyí ni ẹranko tí ẹ óò máa jẹ:+ akọ màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́,  akọ àgbọ̀nrín àti àgbàlàǹgbó àti èsúwó+ àti ẹ̀kìrì àti ẹtu àti àgùntàn ìgbẹ́ àti olúbe;  àti gbogbo ẹranko tí ó la pátákò, tí ó sì ní àlàfo tí ó pín pátákò sí méjì , tí ń jẹ àpọ̀jẹ, nínú àwọn ẹranko.+ Òun ni kí ẹ máa jẹ.  Kì kì irú èyí ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú àwọn ti ń jẹ àpọ̀jẹ tàbí tí ó la pátákò, tí ó ní àlàfo: ràkúnmí+ àti ehoro+ àti gara orí àpáta,+ nítorí tí wọ́n jẹ́ ajẹ àpọ̀jẹ ṣùgbọ́n wọn kò la pátákò. Aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.  Ẹlẹ́dẹ̀+ pẹ̀lú, nítorí tí ó la pátákò ṣùgbọ́n kò jẹ àpọ̀jẹ. Aláìmọ́ ni ó jẹ́ fún yín. Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ ìkankan nínú ẹran wọn, òkú wọn ni ẹ̀yin kò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn.+  “Irú èyí nínú ohun gbogbo tí ó wà nínú omi ni kí ẹ máa jẹ: Ohun gbogbo tí ó bá ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́ ni kí ẹ máa jẹ.+ 10  Ohun gbogbo tí kò bá sì ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́ kankan ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ.+ Aláìmọ́ ni ó jẹ́ fún yín. 11  “Ẹyẹ èyíkéyìí tí ó mọ́ ni kí ẹ máa jẹ. 12  Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ni àwọn tí ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ: idì àti idì ajẹja àti igún dúdú,+ 13  àti àwòdì pupa àti àwòdì dúdú+ àti ẹyẹ adọdẹ ní irú tirẹ̀; 14  àti gbogbo ẹyẹ ìwò+ ní irú tirẹ̀; 15  àti ògòǹgò+ àti òwìwí àti ẹyẹ àkẹ̀ àti àṣáǹwéwé ní irú tirẹ̀; 16  òwìwí kékeré àti òwìwí elétí gígùn+ àti ògbùgbú, 17  àti ẹyẹ òfú+ àti igún àti ẹyẹ àgò, 18  àti ẹyẹ àkọ̀ àti ẹyẹ wádòwádò ní irú tirẹ̀, àti àgbìgbò àti àdán.+ 19  Gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn abìyẹ́lápá sì jẹ́ aláìmọ́ fún yín.+ A kò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n. 20  Ẹ̀dá èyíkéyìí tí ń fò, tí ó mọ́, ni kí ẹ máa jẹ. 21  “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran+ èyíkéyìí. Àtìpó tí ó wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ ni o lè fi í fún, kí ó sì jẹ ẹ́; tàbí a lè tà á fún ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, nítorí pé ìwọ jẹ́ ènìyàn mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ se ọmọ ẹran nínú wàrà ìyá rẹ̀.+ 22  “Láìkùnà, kí o máa san ìdá mẹ́wàá gbogbo èso irúgbìn rẹ, èyí tí ń jáde wá láti inú pápá ní ọdọọdún.+ 23  Àti níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ní ibi tí yóò yàn láti mú kí orúkọ rẹ̀ máa gbé, ni kí o ti jẹ ìdá mẹ́wàá ọkà+ rẹ, wáìnì rẹ tuntun àti òróró rẹ àti àwọn àkọ́bí nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti nínú agbo ẹran rẹ;+ kí ìwọ lè kọ́ láti bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ nígbà gbogbo.+ 24  “Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìrìn àjò náà gùn jù fún ọ,+ nítorí pé ìwọ kò ní lè gbé e, níwọ̀n bí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò yàn láti fi orúkọ+ rẹ̀ sí yóò ti jì nnà réré jù fún ọ, (nítorí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò bù kún ọ,)+ 25  nígbà náà, kí ìwọ sọ ọ́ di owó, kí o sì di owó náà sí ọwọ́ rẹ, kí o sì rin ìrìn àjò lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò yàn. 26  Kí o sì ná owó náà sórí ohun yòówù tí ọkàn rẹ bá fà sí,+ bí màlúù àti àgùntàn àti ewúrẹ́ àti wáìnì àti ọtí+ tí ń pani àti ohunkóhun tí ọkàn rẹ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ; kí ìwọ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì máa yọ̀,+ ìwọ àti agbo ilé rẹ. 27  Ọmọ Léfì tí ó sì wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ pa á tì,+ nítorí tí kò bá ọ+ ní ìpín tàbí ogún kankan. 28  “Ní òpin ọdún mẹ́ta, ìwọ yóò kó gbogbo ìdá mẹ́wàá lára èso rẹ ní ọdún+ yẹn jáde, kí o sì kó o kalẹ̀ nínú àwọn ẹnubodè rẹ. 29  Àti ọmọ Léfì+ náà, nítorí tí kò bá ọ ní ìpín tàbí ogún kankan, àti àtìpó+ àti ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó,+ tí wọ́n wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ, yóò wá, wọn yóò sì jẹun, wọn yóò sì yó; kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bàa lè bù kún+ ọ nínú gbogbo iṣẹ́+ ọwọ́ rẹ tí ìwọ yóò ṣe.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé