Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 13:1-18

13  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wòlíì+ kan tàbí alálàá+ kan tí ń lá àlá dìde ní àárín rẹ, tí ó sì fún ọ ní àmì tàbí àmì àgbàyanu+ ní ti gidi,  tí àmì náà tàbí àmì àgbàyanu náà sì ṣẹ ní ti gidi, nípa èyí tí ó sọ fún ọ+ pé, ‘Jẹ́ kí a rìn tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, àwọn tí ìwọ kò mọ̀, sì jẹ́ kí a sìn wọ́n,’  ìwọ kò gbọ́dọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ wòlíì yẹn tàbí sí alálàá tí ń lá àlá+ yẹn, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run yín ń dán yín wò+ láti mọ̀ bóyá ẹ fi gbogbo ọkàn-àyà yín àti gbogbo ọkàn+ yín nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín.  Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ máa rìn tọ̀ lẹ́yìn, òun sì ni kí ẹ máa bẹ̀rù, àwọn àṣẹ rẹ̀ sì ni kí ẹ máa pa mọ́, ohùn rẹ̀ sì ni kí ẹ máa fetí sí, òun sì ni kí ẹ máa sìn, òun sì ni kí ẹ rọ̀ mọ́.+  Wòlíì+ yẹn tàbí alálàá yẹn tí ń lá àlá ni kí ẹ fi ikú pa,+ nítorí pé ó ti sọ̀rọ̀ nípa ìdìtẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, tí ó sì tún ọ rà padà kúrò ní ilé àwọn ẹrú, láti yí ọ padà kúrò ní ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ pàṣẹ fún ọ láti máa rìn;+ kí o sì mú ohun tí ó jẹ́ ibi kúrò ní àárín rẹ.+  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin rẹ, ọmọ ìyá rẹ, tàbí ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin rẹ tàbí aya rẹ tí o ń ṣìkẹ́ tàbí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ tí ó dà bí ọkàn+ rẹ, gbìyànjú láti dẹ ọ́ lọ ní ìkọ̀kọ̀ pé, ‘Jẹ́ kí a lọ sin àwọn ọlọ́run+ mìíràn,’ èyí tí ìwọ kò mọ̀, yálà ìwọ tàbí àwọn baba ńlá rẹ,  àwọn kan lára àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn tí ó wà yí yín ká, àwọn tí ó wà nítòsí rẹ tàbí àwọn tí ó jì nnà réré sí ọ, láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ náà dé ìpẹ̀kun kejì  ilẹ̀ náà,  ìwọ kò gbọ́dọ̀ gba pẹ̀lú ohun tí ó fẹ́, tàbí kí o fetí sí i,+ kí ojú rẹ má sì ṣe káàánú rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ní ìyọ́nú, tàbí kí o dáàbò bò ó;  ṣùgbọ́n pípa ni kí o pa á láìkùnà.+ Ọwọ́ rẹ ni kí ó kọ́kọ́ wá sára rẹ̀ láti fi ikú pa á, àti ọwọ́ gbogbo ènìyàn lẹ́yìn náà.+ 10  Kí o sì sọ ọ́ lókùúta, kí ó sì kú,+ nítorí tí ó ti wá ọ̀nà láti yí ọ padà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, jáde kúrò ní ilé àwọn ẹrú.+ 11  Nígbà náà ni gbogbo Ísírẹ́lì yóò gbọ́, wọn yóò sì fòyà, wọn kò sì ní ṣe ohunkóhun bí ohun búburú yìí mọ́ ní àárín rẹ.+ 12  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o gbọ́, tí a sọ ọ́ nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá rẹ, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ láti máa gbé níbẹ̀, pé, 13  ‘Àwọn ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun ti jáde láàárín+ rẹ, kí wọ́n lè gbìyànjú láti yí àwọn olùgbé ìlú ńlá+ wọn padà, pé: “Jẹ́ kí a lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn,” èyí tí ẹ̀yin kò mọ̀,’ 14  kí ìwọ tọsẹ̀ rẹ̀, kí o sì ṣe àyẹ̀wò, kí ó sì wádìí kínníkínní;+ bí ohun náà bá sì fìdí múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ pé, ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí yìí ni a ti ṣe láàárín rẹ, 15  kí ìwọ fi ojú idà+ kọlu àwọn olùgbé ìlú ńlá yẹn láìkùnà. Òun àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀ àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún ìparun+ nípa ojú idà. 16  Kí o sì kó gbogbo ohun ìfiṣèjẹ rẹ̀ jọ sí àárín ojúde ìlú rẹ̀, kí o sì fi iná sun ìlú ńlá+ náà àti gbogbo ohun ìfiṣèjẹ rẹ̀ bí odindi ọrẹ ẹbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò sì di òkìtì àwókù fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Kí a má ṣe tún un kọ́ láé. 17  Kí nǹkan kan má sì lẹ̀ mọ́ ọwọ́ rẹ rárá lára ohun tí a sọ di ọlọ́wọ̀ nípasẹ̀ ìfòfindè,+ kí Jèhófà lè yí padà kúrò nínú ìbínú rẹ̀ jíjófòfò,+ kí ó sì lè fi àánú fún ọ ní tòótọ́, kí ó sì lè fi àánú+ hàn sí ọ dájúdájú, kí ó sì sọ ọ́ di púpọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ.+ 18  Nítorí o ní láti máa fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa pípa gbogbo àṣẹ+ rẹ̀ tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́, kí o bàa lè máa ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé