Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Diutarónómì 12:1-32

12  “Ìwọ̀nyí ni ìlànà+ àti ìpinnu ìdájọ́+ tí ẹ̀yin yóò kíyè sára láti mú ṣe+ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ yóò yọ̀ǹda fún ọ láti gbà dájúdájú, ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ̀yin yóò fi wà láàyè lórí ilẹ̀.+  Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óò lé kúrò ti sin àwọn ọlọ́run wọn ni kí ẹ pa run+ pátápátá, lórí àwọn òkè ńlá gíga àti àwọn òkè kéékèèké àti lábẹ́ gbogbo igi gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+  Kí ẹ sì bi àwọn pẹpẹ+ wọn wó, kí ẹ sì fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀+ wọn túútúú, àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ wọn ni kí ẹ sì sun nínú iná, kí ẹ sì ké àwọn ère fífín+ àwọn ọlọ́run wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn run kúrò ní ibẹ̀.+  “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run yín,+  ṣùgbọ́n ibi tí Jèhófà Ọlọ́run yín yóò yàn nínú gbogbo ẹ̀yà yín láti fi orúkọ rẹ̀ sí, láti mú kí ó máa gbé, ni ẹ̀yin yóò wá kiri, ibẹ̀ sì ni kí o máa lọ.+  Ibẹ̀ sì ni kí ẹ mú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ yín wá àti àwọn ẹbọ yín àti àwọn ìdá mẹ́wàá+ yín àti ọrẹ ọwọ́+ yín àti àwọn ọrẹ ẹbọ+ ẹ̀jẹ́ yín àti àwọn ọrẹ+ àfínnúfíndọ̀ṣe yín àti àwọn àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran yín àti agbo ẹran+ yín.  Ibẹ̀ sì ni kí ẹ ti jẹun níwájú Jèhófà Ọlọ́run+ yín, kí ẹ sì máa yọ̀ nínú gbogbo ìdáwọ́lé yín,+ ẹ̀yin àti àwọn agbo ilé yín, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti bù kún ọ.  “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí àwa ń ṣe níhìn-ín lónìí, olúkúlùkù ohun yòówù tí ó tọ́ ní ojú+ òun fúnra rẹ̀,  nítorí, síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀yin kò tíì dé ibi ìsinmi+ àti ogún tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ. 10  Kí ẹ sì sọdá Jọ́dánì,+ kí ẹ sì máa gbé ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín yóò fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun ìní,+ dájúdájú, òun yóò sì fún yín ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá yín yíká-yíká, ní tòótọ́, ẹ̀yin yóò sì máa gbé lábẹ́ ààbò.+ 11  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ibi+ tí Jèhófà Ọlọ́run yín yóò yàn láti mú kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ni ẹ ó ti mú gbogbo èyí tí mo ń pa láṣẹ fún yín ṣẹ, àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ yín àti àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá+ yín àti ọrẹ+ ọwọ́ yín àti gbogbo onírúurú ààyò àwọn ọrẹ ẹbọ ẹ̀jẹ́+ yín tí ẹ̀yin yóò jẹ́ fún Jèhófà. 12  Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run+ yín, ẹ̀yin àti àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín àti àwọn ẹrúkùnrin yín àti àwọn ẹrúbìnrin yín àti ọmọ Léfì tí ó wà nínú àwọn ẹnubodè yín, nítorí tí kò bá yín ní ìpín tàbí ogún kankan.+ 13  Ṣọ́ ara rẹ, kí o má bàa rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun rẹ ní ibi èyíkéyìí mìíràn tí o bá rí.+ 14  Ṣùgbọ́n ibi tí Jèhófà yóò yàn nínú ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà rẹ ni kí o ti rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, ibẹ̀ sì ni kí o ti ṣe gbogbo ohun ti mo ń pa láṣẹ fún ọ.+ 15  “Kì kì ìgbàkígbà tí ọkàn rẹ bá fà sí ẹran ni o lè pa á,+ kí o sì jẹ ẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìbùkún Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí ó fi fún ọ, nínú gbogbo ẹnubodè rẹ. Ẹni tí ó jẹ aláìmọ́+ àti ẹni tí ó mọ́ lè jẹ ẹ́, bí àgbàlàǹgbó àti bí akọ àgbọ̀nrín.+ 16  Kì kì ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ.+ Orí ilẹ̀ ni kí o dà á jáde sí bí omi.+ 17  Nínú àwọn ẹnubodè rẹ, a kì yóò gbà ọ́ láyè láti jẹ ìdá mẹ́wàá ọkà+ rẹ tàbí ti wáìnì rẹ tuntun tàbí ti òróró rẹ tàbí àwọn àkọ́bí lára ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti lára agbo ẹran+ rẹ tàbí ti èyíkéyìí lára àwọn ọrẹ ẹbọ ẹ̀jẹ́ rẹ tí ìwọ yóò jẹ́ tàbí àwọn ọrẹ+ rẹ àfínnúfíndọ̀ṣe tàbí ọrẹ ọwọ́+ rẹ. 18  Ṣùgbọ́n níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o ti jẹ ẹ́, ní ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò yàn,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti ọmọ Léfì tí ó wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ; kí ìwọ sì máa yọ̀+ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ. 19  Ṣọ́ ara rẹ, kí o má bàa pa ọmọ Léfì+ tì ní gbogbo ọjọ́ rẹ lórí ilẹ̀ rẹ. 20  “Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò mú ìpínlẹ̀+ rẹ gbòòrò síwájú, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ+ gan-an, tí ìwọ yóò sì wí dájúdájú pé, ‘Jẹ́ kí n jẹ ẹran,’ nítorí tí ọkàn rẹ fà sí àtijẹ ẹran, ìgbàkígbà tí ọkàn rẹ bá fà sí i ni o lè jẹ ẹran.+ 21  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò yàn láti fi orúkọ+ rẹ̀ sí jì nnà réré sí ọ, nígbà náà, kí o pa lára ọ̀wọ́ ẹran rẹ tàbí lára agbo ẹran rẹ tí Jèhófà fi fún ọ, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ gan-an, kí o sì jẹ ẹ́ nínú àwọn ẹnubodè rẹ nígbàkígbà tí ọkàn rẹ bá fà sí i.+ 22  Kì kì bí a ti í jẹ+ àgbàlàǹgbó àti akọ àgbọ̀nrín, bẹ́ẹ̀ ni kí o jẹ ẹ́: ẹni tí ó jẹ́ aláìmọ́+ àti ẹni tí ó mọ́ lápapọ̀ lè jẹ ẹ́. 23  Kì kì pé kí o pinnu lọ́nà tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in láti má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀,+ nítorí pé ẹ̀jẹ̀ jẹ́ ọkàn,+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ jẹ ọkàn pẹ̀lú ẹran. 24  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́. Kí o dà á jáde sórí ilẹ̀ bí omi.+ 25  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ+ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, nítorí pé ìwọ yóò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú+ Jèhófà. 26  Kì kì àwọn ohun mímọ́+ rẹ tí yóò di tìrẹ, àti àwọn ọrẹ ẹbọ ẹ̀jẹ́+ rẹ ni kí o gbé, kí o sì wá sí ibi tí Jèhófà yóò yàn.+ 27  Kí o sì rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ rẹ, ẹran àti ẹ̀jẹ̀+ náà, lórí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ; ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ rẹ ni kí a sì tú jáde sára pẹpẹ Jèhófà+ Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n ẹran náà ni kí o jẹ. 28  “Ṣọ́ra, kí o sì ṣègbọràn sí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ,+ kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ+ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, nítorí pé ìwọ yóò ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ. 29  “Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ké àwọn orílẹ̀-èdè náà kúrò níwájú rẹ, àwọn tí ìwọ ń lọ lé kúrò,+ ìwọ yóò lé wọn kúrò, ìwọ yóò sì máa gbé ní ilẹ̀+ wọn. 30  Ṣọ́ ara rẹ, kí a má bàa dẹ pańpẹ́ mú ọ láti tọ̀ wọ́n+ lẹ́yìn, lẹ́yìn tí a ti pa wọ́n rẹ́ ráúráú kúrò níwájú rẹ, àti kí o má bàa ṣe ìwádìí nípa àwọn ọlọ́run wọn pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ṣe ń sin àwọn ọlọ́run wọn? Èmi, bẹ́ẹ̀ ni, èmi yóò sì ṣe bákan náà.’ 31  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, nítorí ohun gbogbo tí ó jẹ́ ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà tí ó sì kórìíra ní ti gidi ni wọ́n ti ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, pé àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn pàápàá ni wọ́n ń sun nínú iná déédéé sí àwọn ọlọ́run wọn.+ 32  Gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ kíyè sára láti tẹ̀ lé.+ Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi kún un tàbí kí ẹ mú kúrò nínú rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé