Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 11:1-32

11  “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, kí o sì máa pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe rẹ sí i mọ́ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ rẹ̀ àti àwọn àṣẹ rẹ̀ nígbà gbogbo.  Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa lónìí (nítorí àwọn tí mo bá sọ̀rọ̀ kì í ṣe àwọn ọmọ yín tí wọn kò tíì mọ̀ tí wọn kò sì tíì rí ìbáwí Jèhófà+ Ọlọ́run yín, títóbi+ rẹ̀, ọwọ́ líle+ rẹ̀ àti apá rẹ̀ nínà jáde,+  tàbí àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe ní àárín Íjíbítì+ sí Fáráò ọba Íjíbítì àti sí gbogbo ilẹ̀ rẹ̀;  tàbí ohun tí ó ṣe sí àwọn ẹgbẹ́ ológun Íjíbítì, sí àwọn ẹṣin rẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ tí òun mú kí omi Òkun Pupa kún àkúnya bò lójú nígbà tí wọ́n ń lépa wọn,+ tí Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti pa wọ́n run títí di òní+ yìí;  tàbí ohun tí ó ṣe sí yín nínú aginjù títí tí ẹ fi dé ibí yìí;  tàbí ohun tí ó ṣe sí Dátánì àti Ábírámù,+ àwọn ọmọ Élíábù ọmọkùnrin Rúbẹ́nì, nígbà tí ilẹ̀ la ẹnu tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé wọn mì àti agbo ilé wọn àti àgọ́ wọn àti gbogbo ohun alààyè tí ó tẹ̀ lé wọn ní àárín gbogbo Ísírẹ́lì);+  nítorí ojú yín ni ó rí gbogbo iṣẹ́ ńlá Jèhófà tí ó ṣe.+  “Kí ẹ sì máa pa gbogbo àṣẹ+ tí mo ń pa fún ọ lónìí mọ́, kí ẹ bàa lè di alágbára, kí ẹ sì lè wọlé ní tòótọ́, kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí ẹ ó sọdá sí láti gbà,+  àti kí ẹ bàa lè mú ọjọ́+ yín gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá yín láti fi fún wọn àti fún irú-ọmọ+ wọn, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.+ 10  “Nítorí ilẹ̀ tí ìwọ ń lọ láti gbà kò dà bí ilẹ̀ Íjíbítì tí ẹ̀yin ti jáde wá, níbi tí o ti máa ń fún irúgbìn rẹ, tí o sì ní láti fi ẹsẹ̀ rẹ ṣe ìbomirin, bí ti ọgbà ọ̀gbìn. 11  Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń sọdá sí láti gbà jẹ́ ilẹ̀ àwọn òkè ńlá àti àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì .+ Láti inú òjò ojú ọ̀run ni ó ti ń mu omi; 12  ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń bójú tó. Ojú+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà lára rẹ̀ nígbà gbogbo, láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọdún dé òpin ọdún. 13  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ẹ̀yin kì yóò bá kùnà láti ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ+ mi, èyí tí mo ń pa fún yín lónìí, láti lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín àti láti lè máa fi gbogbo ọkàn-àyà yín àti gbogbo ọkàn+ yín sìn ín, 14  dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò pèsè òjò fún ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀,+ òjò ìgbà ìkórè àti òjò ìgbà ìrúwé,+ ní tòótọ́, ìwọ yóò sì kó ọkà rẹ jọ àti wáìnì dídùn rẹ àti òróró rẹ. 15  Dájúdájú, èmi yóò sì pèsè ewéko ní pápá rẹ, fún àwọn ẹran agbéléjẹ̀+ rẹ, ní tòótọ́, ìwọ yóò sì jẹun, ìwọ yóò sì yó.+ 16  Ẹ ṣọ́ra yín, kí a má bàa ré ọkàn-àyà yín lọ,+ tí ẹ ó sì yà kúrò ní tòótọ́, tí ẹ ó sì jọ́sìn àwọn ọlọ́run mìíràn, tí ẹ ó sì tẹrí ba fún wọn,+ 17  tí ìbínú Jèhófà a sì ru sí yín ní ti gidi, tí yóò sì sé ojú ọ̀run pa tó bẹ́ẹ̀ tí òjò kò fi ní sí,+ tí ilẹ̀ kò sì ní fi èso rẹ̀ fúnni, tí ẹ̀yin yóò sì fi ìyára kánkán ṣègbé kúrò lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà yóò fi fún yín.+ 18  “Kí ẹ sì fi ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí ọkàn-àyà+ yín àti ọkàn yín, kí ẹ sì dè wọ́n gẹ́gẹ́ bí àmì mọ́ ọwọ́ yín, wọn yóò sì jẹ́ ọ̀já ìgbàjú láàárín àwọn ojú+ yín. 19  Kí ẹ fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, kí o bàa lè máa sọ̀rọ̀ wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o ba ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.+ 20  Kí o sì kọ wọ́n sára òpó ilẹ̀kùn ilé rẹ àti sára àwọn ẹnubodè+ rẹ, 21  kí ọjọ́ yín àti ọjọ́ àwọn ọmọ yín bàa lè pọ̀+ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá yín láti fi fún wọ́n,+ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ọ̀run lókè ilẹ̀ ayé.+ 22  “Nítorí bí ẹ̀yin bá pa gbogbo àṣẹ+ yìí tí mo ń pa fún yín mọ́ délẹ̀délẹ̀ láti lè ṣe é, láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ yín, láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà+ rẹ̀ àti láti rọ̀ mọ́ ọn,+ 23  Jèhófà pẹ̀lú yóò lé gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí lọ ní tìtorí yín,+ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi jù yín, tí wọ́n sì pọ̀ níye jù yín+ ni ẹ̀yin yóò sì lé kúrò dájúdájú. 24  Gbogbo ibi tí àtẹ́lẹsẹ̀ yín bá tẹ̀ yóò di tiyín.+ Láti aginjù títí dé Lẹ́bánónì, láti Odò náà, Odò Yúfírétì, dé òkun ìwọ̀-oòrùn ni yóò di ààlà yín.+ 25  Kò sí ọkùnrin kankan tí yóò mú ìdúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí yín.+ Ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ yín àti ẹ̀rù yín ni Jèhófà Ọlọ́run yín yóò fi sí iwájú gbogbo ilẹ̀+ tí ẹ̀yin yóò rìn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún yín gan-an. 26  “Wò ó, èmi ń fi ìbùkún àti ìfiré+ sí iwájú yín lónìí: 27  ìbùkún, kìkì bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run+ yín tí èmi ń pa láṣẹ fún yín lónìí; 28  àti ìfiré,+ bí ẹ̀yin kò bá ní ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run+ yín, tí ẹ sì yà ní ti gidi kúrò lójú ọ̀nà tí mo ń pa láṣẹ fún yín lónìí, láti rìn tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, tí ẹ̀yin kò mọ̀. 29  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tí ìwọ ń lọ gbà,+ ìwọ yóò súre lórí Òkè Ńlá Gérísímù+ àti ìfiré lórí Òkè Ńlá Ébálì.+ 30  Wọn kò ha wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì, ní ìhà wíwọ̀ oòrùn, ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì tí wọ́n ń gbé ní Árábà,+ ní iwájú Gílígálì,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn igi ńlá Mórè?+ 31  Nítorí ẹ̀yin ń sọdá Jọ́dánì láti wọlé lọ gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín yóò fi fún yín, kí ẹ sì gbà á, kí ẹ sì máa gbé lórí rẹ̀.+ 32  Kí ẹ sì kíyè sára láti mú gbogbo ìlànà àti ìpinnu ìdájọ́+ tí mo ń fi sí iwájú yín lónìí+ ṣe.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé