Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Diutarónómì 10:1-22

10  “Ní àkókò yẹn gan-an, Jèhófà wí fún mi pé, ‘Gbẹ́ wàláà òkúta méjì  fún ara rẹ bí àwọn ti àkọ́kọ́,+ kí o sì gòkè wá sọ́dọ̀ mi ní orí òkè ńlá náà, kí o sì fi igi+ ṣe àpótí fún ara rẹ.  Èmi yóò sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó fara hàn lára àwọn wàláà ti àkọ́kọ́, èyí tí o fọ́ túútúú, sára wàláà náà, kí o sì fi wọ́n sí inú àpótí náà.’  Nítorí náà, mo fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àpótí kan, mo sì gbẹ́ wàláà òkúta méjì  bí àwọn+ ti àkọ́kọ́, mo sì gòkè lọ sórí òkè ńlá náà, wàláà méjèèjì  sì wà ní ọwọ́ mi.  Nígbà náà ni ó kọ ìkọ̀wé kan náà bí ti àkọ́kọ́+ sára àwọn wàláà náà, Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá+ náà, tí Jèhófà ti sọ fún yín ní òkè ńlá náà, láti àárín iná+ wá, ní ọjọ́ ìpéjọ;+ lẹ́yìn èyí ni Jèhófà fi wọ́n fún mi.  Lẹ́yìn náà ni mo yí padà, tí mo sì sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òkè ńlá+ náà, tí mo sì fi àwọn wàláà náà sí inú àpótí tí mo ṣe, kí wọ́n lè máa wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún mi+ gan-an.  “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣí ní Béérótì Bene-jáákánì+ lọ sí Mósérà. Ibẹ̀ ni Áárónì kú sí, tí a sì sin ín síbẹ̀;+ Élíásárì ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà dípò rẹ̀.+  Ibẹ̀ ni wọ́n ti ṣí lọ sí Gúdígódà, àti láti Gúdígódà lọ sí Jótíbátà,+ ilẹ̀ tí ó ní àwọn àfonífojì  olójú ọ̀gbàrá tí omi ti ń ṣàn.  “Ní àkókò yẹn gan-an, Jèhófà ya ẹ̀yà Léfì+ sọ́tọ̀ láti máa ru àpótí májẹ̀mú Jèhófà,+ láti máa dúró níwájú Jèhófà ní ṣíṣe ìránṣẹ́ fún un+ àti láti máa súre ní orúkọ rẹ̀ títí di òní+ yìí.  Ìdí nìyẹn tí Léfì kò fi wá ní ìpín àti ogún+ kankan pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀. Jèhófà ni ogún rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wí fún un+ gan-an. 10  Èmi—èmi sì dúró ní òkè ńlá náà, bí ti àwọn ọjọ́ àkọ́kọ́, ogójì  ọ̀sán àti ogójì  òru,+ Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti fetí sí mi ní àkókò yẹn+ pẹ̀lú. Jèhófà kò fẹ́ run+ ọ. 11  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún mi pé, ‘Dìde, máa lọ níwájú àwọn ènìyàn náà fún àtiṣí lọ, kí wọ́n lè wọlé láti gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá wọn láti fi fún wọn.’+ 12  “Wàyí o, ìwọ Ísírẹ́lì, kí sì ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń béèrè lọ́wọ́ rẹ,+ bí kò ṣe láti máa fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn+ rẹ bẹ̀rù+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o lè máa rìn ní gbogbo ọ̀nà+ rẹ̀ àti láti máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀+ àti láti máa sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ; 13  láti máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀+ rẹ̀ tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, fún ire rẹ?+ 14  Kíyè sí i, ti Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run,+ ilẹ̀ ayé+ àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀. 15  Kì kì àwọn baba ńlá rẹ ni Jèhófà fà mọ́ láti lè nífẹ̀ẹ́ wọn, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi yan ọmọ wọn lẹ́yìn wọn,+ àní ẹ̀yin, nínú gbogbo ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí. 16  Kí ẹ sì dá adọ̀dọ́ ọkàn-àyà+ yín, kí ẹ má sì tún mú ọrùn yín le mọ́.+ 17  Nítorí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run+ àti Olúwa àwọn olúwa,+ Ọlọ́run títóbi, alágbára ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù,+ tí kì í fi ojúsàájú+ bá ẹnikẹ́ni lò tàbí kí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+ 18  tí ń mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún fún ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó,+ tí ó sì nífẹ̀ẹ́ àtìpó+ láti fi oúnjẹ àti aṣọ àlàbora fún un. 19  Kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ àtìpó,+ nítorí ẹ̀yin di àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 20  “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o bẹ̀rù.+ Òun ni kí o máa sìn,+ òun ni kí o sì rọ̀ mọ́,+ àti pé nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀ ni kí o máa sọ àwọn gbólóhùn ìbúra.+ 21  Òun ni Ẹni tí ìwọ yóò máa fi ìyìn fún,+ òun sì ni Ọlọ́run rẹ, tí ó ti fi ọ́ ṣe àwọn ohun títóbi àti amúnikún-fún-ẹ̀rù tí ojú rẹ ti rí+ wọ̀nyí. 22  Ti àwọn ti àádọ́rin ọkàn ni àwọn baba ńlá rẹ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì,+ nísinsìnyí, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì ti sọ ọ́ dà bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé