Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Diutarónómì 1:1-46

1  Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ fún gbogbo Ísírẹ́lì ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì+ ní aginjù, ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ níwájú Súfù, láàárín Páránì+ àti Tófélì àti Lábánì àti Hásérótì+ àti Dísáhábù,  ìrìn ọjọ́ mọ́kànlá ni ó jẹ́ láti Hórébù ní gbígba ti Òkè Ńlá Séírì sí Kadeṣi-bánéà.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ní ọdún ogójì ,+ ní oṣù kọkànlá, ní ọjọ́ kìíní oṣù, Mósè bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un nípa wọn,  lẹ́yìn tí ó ṣẹ́gun Síhónì+ ọba àwọn Ámórì, ẹni tí ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì, àti Ógù+ ọba Báṣánì, ẹni tí ń gbé ní Áṣítárótì,+ ní Édíréì.+  Ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì ní ilẹ̀ Móábù, Mósè dáwọ́ lé ṣíṣe àlàyé òfin yìí,+ pé:  “Jèhófà Ọlọ́run wa bá wa sọ̀rọ̀ ní Hórébù+ pé, ‘Ẹ ti gbé pẹ́ tó ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá yìí.+  Ẹ yí padà, kí ẹ sì mú ọ̀nà yín pọ̀n, kí ẹ sì máa lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti àwọn Ámórì+ àti sí gbogbo àdúgbò wọn ní Árábà,+ ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá+ àti Ṣẹ́fẹ́là àti Négébù+ àti etí òkun,+ ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì,+ àti Lẹ́bánónì,+ títí dé odò ńlá náà, Odò Yúfírétì.+  Ẹ wò ó, mo fi ilẹ̀ náà síwájú yín. Ẹ wọ̀ ọ́, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà, nípa èyí tí Jèhófà búra fún àwọn baba yín, fún Ábúráhámù, Ísákì+ àti Jékọ́bù,+ láti fi í fún àwọn àti irú-ọmọ wọn lẹ́yìn wọn.’+  “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ èyí fún yín ní àkókò yẹn gan-an pé, ‘Èmi kò lè dá yín gbé.+ 10  Jèhófà Ọlọ́run yín ti sọ yín di púpọ̀, ẹ̀yin sì nìyí lónìí bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó.+ 11  Kí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín mú yín pọ̀ sí i+ ní ìlọ́po ẹgbẹ̀rún iye tí ẹ jẹ́, kí ó sì bù kún+ yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún yín.+ 12  Báwo ni mo ṣe lè dá ẹrù ìnira yín àti ẹrù yín àti aáwọ̀ yín gbé?+ 13  Ẹ wá àwọn ọkùnrin ọlọ́gbọ́n àti olóye+ atí onírìírí+ nínú àwọn ẹ̀yà yín rí, kí èmi lè gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí lórí yín.’+ 14  Látàrí èyí, ẹ dá mi lóhùn, ẹ sì wí pé, ‘Ohun tí o sọ pé kí a ṣe dára.’ 15  Nítorí náà, mo mú àwọn olórí ẹ̀yà yín, àwọn ọkùnrin ọlọ́gbọ́n, tí wọ́n sì ní ìrírí, mo sì fi wọ́n ṣe olórí yín, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti olórí àràádọ́ta àti olórí ẹ̀wẹ̀ẹ̀wá àti àwọn onípò àṣẹ nínú àwọn ẹ̀yà yín.+ 16  “Mo sì ń bá a lọ láti pàṣẹ fún àwọn onídàájọ́ yín ní àkókò yẹn gan-an, pé, ‘Nígbà tí ẹ bá ń gbọ́ ẹjọ́ láàárín àwọn arákùnrin yín, ẹ gbọ́dọ̀ fi òdodo ṣe ìdájọ́+ láàárín ọkùnrin kan àti arákùnrin rẹ̀ tàbí àtìpó rẹ̀.+ 17  Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú nínú ìdájọ́.+ Ẹ gbọ́dọ̀ gbọ́ ti ẹni kékeré bákan náà bí ti ẹni ńlá.+ Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí jì nnìjì nnì bá yín nítorí ènìyàn kan,+ nítorí pé ti Ọlọ́run ni ìdájọ́;+ ẹjọ́ tí ó bá sì le jù fún yín, kí ẹ gbé e wá fún mi, èmi yóò sì gbọ́ ọ.’+ 18  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí pàṣẹ gbogbo ohun tí ẹ gbọ́dọ̀ ṣe fún yín ní àkókò yẹn gan-an. 19  “Nígbà náà, a ṣí kúrò ní Hórébù, a sì la gbogbo aginjù ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù+ yẹn kọjá, èyí tí ẹ̀yin ti rí, ní ojú ọ̀nà ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti àwọn Ámórì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wa; ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a sì dé Kadeṣi-bánéà.+ 20  Mo sì wí fún yín pé, ‘Ẹ ti dé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti àwọn Ámórì, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run wa yóò fi fún wa.+ 21  Wò ó, Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti jọ̀wọ́ ilẹ̀ náà fún ọ.+ Gòkè lọ, gbà á, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ ti sọ fún ọ.+ Má fòyà, kí o má sì jáyà.’+ 22  “Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo yín sún mọ́ mi, ẹ sì wí pé, ‘Jẹ́ kí a rán àwọn ọkùnrin ṣáájú wa, kí wọ́n lè ṣàyẹ̀wò ilẹ̀ náà fún wa, kí wọ́n sì mú ọ̀rọ̀ padà wá fún wa nípa ọ̀nà tí àwa yóò gbà gòkè lọ àti àwọn ìlú ńlá tí àwa yóò dé.’+ 23  Tóò, ohun náà dára ní ojú mi, tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi mú àwọn ọkùnrin méjì lá lára yín, ẹnì kan fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.+ 24  Nígbà náà ni wọ́n yí padà, tí wọ́n sì gòkè lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà,+ tí wọ́n sì lọ títí dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Éṣíkólì,+ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe amí rẹ̀. 25  Wọ́n sì ń bá a lọ láti kó lára èso ilẹ̀ náà+ ní ọwọ́ wọn, tí wọ́n sì kó o sọ̀ kalẹ̀ wá fún wa, wọ́n sì mú ọ̀rọ̀ padà wá fún wa pé, ‘Ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wa yóò fi fún wa dára.’+ 26  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ gòkè lọ,+ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà Ọlọ́run yín.+ 27  Ẹ sì ń ráhùn ṣáá nínú àwọn àgọ́ yín, ẹ sì ń wí pé, ‘Tìtorí pé Jèhófà kórìíra+ wa ni ó fi mú wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì+ láti fi wá lé àwọn Ámórì lọ́wọ́, láti pa wá rẹ́ ráúráú.+ 28  Ibo ni àwa ń gòkè lọ? Àwọn arákùnrin wa ti mú kí ọkàn-àyà wa domi,+ wọ́n sọ pé: “Àwọn ènìyàn tí ó tóbi tí wọ́n sì ga jù wá lọ,+ àwọn ìlú ńlá tí ó tóbi tí a sì mọdi wọn kan ọ̀run,+ àti àwọn ọmọ Ánákímù+ pẹ̀lú, ni a rí níbẹ̀.”’ 29  “Nítorí náà, mo wí fún yín pé, ‘Ẹ má ṣe gbọ̀n rìrì, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má fòyà nítorí wọn.+ 30  Jèhófà Ọlọ́run yín ni ẹni tí ń lọ níwájú yín. Òun yóò jà fún yín,+ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ṣe fún yín ní Íjíbítì ní ojú ẹ̀yin fúnra yín,+ 31  àti ní aginjù,+ níbi tí o ti rí i bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti gbé ọ,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan ti í gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ rìn títí di ìgbà tí ẹ dé ibí yìí.’+ 32  Ṣùgbọ́n láìka ọ̀rọ̀ yìí sí, ẹ̀yin kò lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ 33  ẹni tí ń lọ níwájú yín ní ọ̀nà náà láti ṣe amí ibì kan fún yín láti dó sí,+ nípasẹ̀ iná ní òru, kí ẹ lè ríran rí ojú ọ̀nà tí ẹ ó rìn àti nípasẹ̀ àwọsánmà ní ìgbà ọ̀sán.+ 34  “Ní gbogbo àkókò yìí, Jèhófà gbọ́ ohùn àwọn ọ̀rọ̀ yín. Nítorí náà, ìkannú rẹ́ ru, ó sì búra+ pé, 35  ‘Kò sí ìkankan nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ ti ìran búburú yìí tí yóò rí ilẹ̀ rere tí mo búra láti fi fún àwọn baba yín,+ 36  àyàfi Kálébù ọmọkùnrin Jéfúnè.+ Òun ni yóò rí i, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni èmi yóò sì fi ilẹ̀ tí ó rìn lórí rẹ̀ fún, nítorí òtítọ́ náà pé ó tọ Jèhófà lẹ́yìn ní kíkún.+ 37  (Ìbínú Jèhófà ru sókè sí èmi pàápàá ní tìtorí yín, ó wí pé, ‘Ìwọ náà kò ní wọ ibẹ̀.+ 38  Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì, tí ó ń dúró níwájú rẹ, ni ẹni tí yóò wọ ibẹ̀.’+ Òun ni ó ti sọ di alágbára,+ nítorí pé òun ni yóò mú kí Ísírẹ́lì jogún rẹ̀.) 39  Ní ti àwọn ọmọ yín kéékèèké tí ẹ sọ pé: “Ohun tí a piyẹ́ ni wọn yóò dà!”+ àwọn ọmọ yín tí wọn kò sì mọ rere tàbí búburú lónìí, àwọn ni yóò wọ ibẹ̀, àwọn ni èmi yóò sì fi í fún, àwọn ni yóò sì gbà á. 40  Ní ti ẹ̀yin fúnra yín, ẹ yíjú padà, kí ẹ sì ṣí kúrò ní aginjù ní gbígba ti Òkun Pupa.’+ 41  “Látàrí èyí, ẹ dáhùn, ẹ sì wí fún mi pé, ‘A ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.+ Àwa—àwa yóò gòkè lọ, a ó sì jà ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa ti pa láṣẹ fún wa!’ Nítorí náà, olúkúlùkù yín fi àwọn ohun ìjà ogun rẹ̀ di àmùrè, ẹ sì wò ó bí ẹni pé ó rọrùn láti gòkè lọ sí òkè ńlá náà.+ 42  Ṣùgbọ́n Jèhófà wí fún mi pé, ‘Sọ fún wọn pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ gòkè lọ jà, nítorí èmi kò sí ní àárín yín;+ kí a má bàa ṣẹ́gun yín níwájú àwọn ọ̀tá yín.”’+ 43  Nítorí náà, mo bá yín sọ̀rọ̀, ẹ̀yin kò sì fetí sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀tẹ̀+ sí àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, ẹ sì mú gbogbo ènìyàn gbaná jẹ, ẹ sì gbìyànjú láti gòkè lọ sí òkè ńlá náà.+ 44  Nígbà náà ni àwọn Ámórì tí wọ́n ń gbé ní òkè ńlá náà jáde wá pàdé yín, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa yín,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí kòkòrò oyin ti máa ń ṣe, tí wọ́n sì ń tú yín ká ní Séírì títí dé Hóómà.+ 45  Lẹ́yìn náà, ẹ padà, ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún níwájú Jèhófà, ṣùgbọ́n Jèhófà kò fetí sí ohùn yín,+ bẹ́ẹ̀ ni kò fi etí sí yín.+ 46  Nítorí náà, ẹ ń bá a nìṣó ní gbígbé ní Kádéṣì fún ọjọ́ púpọ̀, ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ fi gbé níbẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé