Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Dáníẹ́lì 9:1-27

9  Ní ọdún kìíní Dáríúsì+ ọmọkùnrin Ahasuwérúsì, tí ó jẹ́ irú-ọmọ àwọn ará Mídíà,+ ẹni tí a ti fi jẹ ọba lórí ìjọba àwọn ará Kálídíà;+  ní ọdún kìíní ìgbà ìjọba rẹ̀, èmi fúnra mi, Dáníẹ́lì, fi òye mọ̀ láti inú ìwé, iye ọdún nípa èyí tí ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jeremáyà wòlíì+ wá, láti mú ìparundahoro Jerúsálẹ́mù ṣẹ,+ èyíinì ni, àádọ́rin ọdún.+  Mo sì ń bá a lọ láti kọjú mi+ sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, láti lè wá a pẹ̀lú àdúrà+ àti pẹ̀lú ìpàrọwà, pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà àti aṣọ àpò ìdọ̀họ àti eérú.+  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́, mo sì wí pé:+ “Áà Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni ńlá,+ Ẹni tí ń múni kún fún ẹ̀rù, tí ń pa májẹ̀mú+ àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ mọ́ sí àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí ó sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+  a ti ṣẹ̀,+ a sì ti ṣe àìtọ́, a sì ti ṣe ohun burúkú, a sì ti ṣọ̀tẹ̀;+ yíyà kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ+ sì ti ṣẹlẹ̀.  A kò sì fetí sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, wòlíì,+ tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ fún àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé wa àti àwọn baba ńlá wa àti fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.+  Jèhófà, tìrẹ ni òdodo, ṣùgbọ́n tiwa ni ìtìjú gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí,+ fún àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àti fún gbogbo àwọn ti Ísírẹ́lì, àwọn tí ó wà nítòsí àti àwọn tí ó jìnnà réré ní gbogbo ilẹ̀ tí o fọ́n wọn ká sí nítorí ìwà àìṣòótọ́ tí wọ́n hù sí ọ.+  “Jèhófà, tiwa ni ìtìjú, ti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé wa àti àwọn baba ńlá wa, nítorí a ti ṣẹ̀ sí ọ.+  Ti Jèhófà Ọlọ́run wa ni àánú+ àti ìṣe ìdáríjì,+ nítorí a ti ṣọ̀tẹ̀ sí i.+ 10  A kò sì ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa nípa rírìn nínú òfin rẹ̀ tí ó gbé ka iwájú wa láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wòlíì.+ 11  Gbogbo Ísírẹ́lì sì ti tẹ òfin rẹ lójú, yíyà kúrò sì ti ṣẹlẹ̀ nípa ṣíṣàìgbọràn sí ohùn rẹ,+ tí o fi da ègún àti ìbúra+ tí a kọ sínú òfin Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ jáde sórí wa, nítorí a ti ṣẹ̀ sí I. 12  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ti sọ lòdì sí wa+ àti lòdì sí àwọn onídàájọ́ tí ń ṣe ìdájọ́ wa+ ṣẹ, nípa mímú ìyọnu àjálù ńláǹlà wá sórí wa, irú èyí tí a kò ṣe lábẹ́ gbogbo ọ̀run bí èyí tí a ṣe ní Jerúsálẹ́mù.+ 13  Gan-an gẹ́gẹ́ bí a tí kọ ọ́ sínú òfin Mósè,+ gbogbo ìyọnu àjálù yìí—ó ti dé sórí wa,+ a kò sì tu ojú Jèhófà Ọlọ́run wa nípa yíyípadà kúrò nínú ìṣìnà wa+ àti nípa fífi ìjìnlẹ̀ òye hàn nínú òótọ́ rẹ.+ 14  “Jèhófà sì wà lójúfò sí ìyọnu àjálù náà, ó sì mú un wá sórí wa+ níkẹyìn, nítorí Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ olódodo nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe; a kò sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀.+ 15  “Wàyí o, Jèhófà Ọlọ́run wa, ìwọ tí o mú àwọn ènìyàn rẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì nípa ọwọ́ líle,+ tí o sì tẹ̀ síwájú láti ṣe orúkọ fún ara rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí,+ a ti ṣẹ̀,+ a ti ṣe ohun burúkú. 16  Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ìṣe òdodo rẹ,+ jọ̀wọ́, kí ìbínú rẹ àti ìhónú rẹ yí padà kúrò lọ́dọ̀ ìlú ńlá rẹ, Jerúsálẹ́mù, òkè ńlá mímọ́ rẹ;+ nítorí, fún ẹ̀ṣẹ̀ wa àti ìṣìnà àwọn baba ńlá wa,+ Jerúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ohun ẹ̀gàn lójú gbogbo àwọn tí ó yí wa ká.+ 17  Wàyí o, Ọlọ́run wa, fetí sílẹ̀, sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti sí ìpàrọwà rẹ̀, sì jẹ́ kí ojú rẹ tàn+ sára ibùjọsìn rẹ tí a sọ di ahoro,+ nítorí ti Jèhófà. 18  Ọlọrun mi, dẹ etí sílẹ̀, kí o sì gbọ́.+ La ojú rẹ kí o sì rí ipò ahoro wa àti ìlú ńlá tí a fi orúkọ rẹ pè;+ nítorí kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìṣe òdodo wa ni a ń jẹ́ kí ìpàrọwà wa wá síwájú rẹ,+ bí kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àánú rẹ.+ 19  Sáà gbọ́,+ Jèhófà. Sáà dárí jì,+ Jèhófà. Sáà fetí sílẹ̀ kí o sì gbé ìgbésẹ̀,+ Jèhófà. Má ṣe jáfara,+ nítorí tìrẹ, Ọlọ́run mi, nítorí orúkọ rẹ ni a fi pe ìlú ńlá rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ.”+ 20  Nígbà tí mo ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, tí mo sì ń gbàdúrà, tí mo sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi+ àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì,+ tí mo sì ń jẹ́ kí ìbéèrè mi fún ojú rere wá síwájú Jèhófà Ọlọ́run mi, nítorí òkè ńlá mímọ́+ Ọlọ́run mi, 21  nígbà tí mo ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ nínú àdúrà náà, họ́wù, ọkùnrin náà Gébúrẹ́lì,+ ẹni tí mo ti rí nínú ìran náà ní ìbẹ̀rẹ̀,+ ní dídi ẹni tí àárẹ̀ ti dá lágara, dé ọ̀dọ̀ mi ní ìgbà ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn alẹ́.+ 22  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí là mí lóye, ó bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Ìwọ Dáníẹ́lì, nísinsìnyí mo wá láti mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye pẹ̀lú ìmọ̀.+ 23  Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìpàrọwà rẹ, ọ̀rọ̀ kan jáde lọ, èmi fúnra mi sì wá láti ròyìn, nítorí o jẹ́ ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi.+ Nítorí náà, gba ọ̀ràn náà yẹ̀ wò,+ sì ní òye nínú ohun tí o rí. 24  “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ wà tí a ti pinnu sórí àwọn ènìyàn rẹ+ àti sórí ìlú ńlá mímọ́ rẹ,+ láti lè mú ìrélànàkọjá kásẹ̀ nílẹ̀,+ àti láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ kúrò,+ àti láti ṣe ètùtù nítorí ìṣìnà,+ àti láti mú òdodo wá fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ àti láti fi èdìdì tẹ+ ìran àti wòlíì, àti láti fòróró yan Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́.+ 25  Kí o mọ̀, kí o sì ní ìjìnlẹ̀ òye pé láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà+ láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́+ títí di ìgbà Mèsáyà+ Aṣáájú,+ ọ̀sẹ̀ méje yóò wà, àti ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta.+ Òun yóò padà, a ó sì tún un kọ́ ní ti gidi, pẹ̀lú ojúde ìlú àti yàrà ńlá, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà kíkangógó. 26  “Àti lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta náà, a óò ké Mèsáyà kúrò,+ kì yóò sì sí nǹkan kan fún un.+ “Ìlú ńlá náà àti ibi mímọ́+ ni àwọn ènìyàn aṣáájú tí ń bọ̀ yóò run.+ Òpin rẹ̀ yóò sì jẹ́ nípasẹ̀ ìkún omi. Ogun yóò sì wà títí di ìgbà òpin; ohun tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí ni ìsọdahoro.+ 27  “Yóò sì mú májẹ̀mú+ máa ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan;+ àti ní ìdajì ọ̀sẹ̀ náà yóò mú kí ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn kásẹ̀ nílẹ̀.+ “Àti lórí ìyẹ́ apá ohun ìríra ni ẹni tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro+ yóò wà; títí di ìparun pátápátá, ohun tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí yóò máa dà jáde sórí ẹni tí ó wà ní ahoro pẹ̀lú.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé