Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Dáníẹ́lì 7:1-28

7  Ní ọdún kìíní Bẹliṣásárì,+ ọba Bábílónì, Dáníẹ́lì fúnra rẹ̀ lá àlá, ó sì rí àwọn ìran orí rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀.+ Ní àkókò yẹn, ó kọ àlá náà sílẹ̀.+ Ó sì sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn nípa ọ̀ràn náà.  Dáníẹ́lì sọ pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé mo rí i nínú ìran mi ní òru, sì wò ó! ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin+ ọ̀run ń ru alagbalúgbú òkun sókè.+  Ẹranko mẹ́rin tí ó tóbi fàkìàfakia+ sì ń jáde bọ̀ láti inú òkun,+ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀+ síra.  “Èyí àkọ́kọ́ dà bí kìnnìún,+ ó sì ní ìyẹ́ apá idì.+ Mo ń wò ó títí a fi fa ìyẹ́ apá rẹ̀ tu, a sì gbé e sókè lórí ilẹ̀ ayé,+ a sì mú kí ó dìde dúró lórí ẹsẹ̀ méjì bí ènìyàn, a sì fún un ní ọkàn-àyà ènìyàn.+  “Sì wò ó! ẹranko mìíràn, èkejì, ó dà bí béárì.+ A sì gbé e sókè ní ìhà kan,+ egungun ìhà mẹ́ta sì wà ní ẹnu rẹ̀ láàárín eyín rẹ̀; ohun tí wọn sì ń sọ fún un nìyí, ‘Dìde, jẹ ẹran púpọ̀.’+  “Lẹ́yìn èyí, mo ń wò ó, sì kíyè sí i! ẹranko mìíràn, ọ̀kan tí ó dà bí àmọ̀tẹ́kùn,+ ṣùgbọ́n, ó ní ìyẹ́ apá mẹ́rin ti ẹ̀dá tí ń fò ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ẹranko náà sì ní orí mẹ́rin,+ agbára ìṣàkóso ni a sì fi fún un ní ti gidi.  “Lẹ́yìn èyí, mo rí i nínú ìran òru, sì wò ó! ẹranko kẹrin, tí ń bani lẹ́rù, tí ń jáni láyà, tí ó sì lágbára lọ́nà kíkàmàmà.+ Ó sì ní eyín irin, wọ́n tóbi. Ó ń jẹ ní àjẹrun, ó sì ń fọ́ túútúú, ohun tí ó sì ṣẹ́ kù ni ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó jẹ́ ohun kan tí ó yàtọ̀ sí gbogbo ẹranko yòókù tí ó wà ṣáájú rẹ̀, ó sì ní ìwo mẹ́wàá.+  Mo ń ronú nípa àwọn ìwo náà, sì wò ó! ìwo mìíràn, ọ̀kan tí ó kéré,+ jáde wá láàárín wọn, mẹ́ta lára àwọn ìwo àkọ́kọ́ ni a sì fà tu níwájú rẹ̀. Sì wò ó! àwọn ojú bí ojú ènìyàn wà lára ìwo yìí, àti ẹnu tí ń sọ àwọn nǹkan kàbìtìkàbìtì.+  “Mo ń wò títí a fi gbé àwọn ìtẹ́ kalẹ̀,+ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé+ sì jókòó. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ìrì dídì+ gẹ́lẹ́, irun orí rẹ̀ sì dà bí irun àgùntàn tí ó mọ́.+ Ọwọ́ iná ni ìtẹ́ rẹ̀;+ iná tí ń jó ni àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀.+ 10  Ìṣàn iná tí ń ṣàn sì wà, ó ń jáde lọ ní iwájú rẹ̀.+ Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń dúró níwájú rẹ̀ gangan.+ Kóòtù+ mú ìjókòó, a sì ṣí àwọn ìwé. 11  “Mo ń wò ní àkókò yẹn nítorí ìró àwọn ọ̀rọ̀ kàbìtìkàbìtì tí ìwo náà ń sọ;+ mo ń wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa ara rẹ̀ run, a sì fi í fún iná tí ń jó.+ 12  Ṣùgbọ́n ní ti ìyókù àwọn ẹranko náà,+ a gba agbára ìṣàkóso wọn kúrò, a sì fún wọn ní ìwàláàyè tí a mú gùn sí i fún ìgbà kan àti àsìkò kan.+ 13  “Mo rí i nínú ìran òru, sì wò ó! ó ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn+ ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà+ ọ̀run; ó sì wọlé wá sọ́dọ̀ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,+ wọ́n mú un wá, àní sún mọ́ iwájú Ẹni náà.+ 14  A sì fún un ní agbára ìṣàkóso+ àti iyì+ àti ìjọba,+ pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.+ Agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kì yóò kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí a kì yóò run.+ 15  “Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, wàhálà-ọkàn bá ẹ̀mí mi nínú mi ní tìtorí èyí, ìran orí mi sì bẹ̀rẹ̀ sí kó jìnnìjìnnì bá mi.+ 16  Mo sún mọ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó dúró, kí n lè béèrè ìsọfúnni tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀ lórí gbogbo èyí lọ́wọ́ rẹ̀.+ Bí ó sì ti ń bá a lọ láti sọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀ràn náà gan-an di mímọ̀ fún mi, ó sọ fún mi pé, 17  “‘Ní ti àwọn ẹranko títóbi fàkìàfakia yìí, nítorí pé mẹ́rin ni wọ́n,+ ọba mẹ́rin ni yóò dìde ní ilẹ̀ ayé.+ 18  Ṣùgbọ́n àwọn ẹni mímọ́+ ti Onípò Àjùlọ+ yóò gba ìjọba, wọn yóò sì gba ìjọba+ náà fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin dórí àkókò tí ó lọ kánrin.’ 19  “Nígbà náà ni mo fẹ́ mọ̀ dájú nípa ẹranko kẹrin, èyí tí ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn yòókù, tí ó bani lẹ́rù lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, tí eyín rẹ̀ jẹ́ irin, tí èékánná rẹ̀ sì jẹ́ bàbà, tí ń jẹ ní àjẹrun, tí ó sì ń fọ́ túútúú, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ ohun tí ó ṣẹ́ kù mọ́lẹ̀;+ 20  àti ní ti ìwo mẹ́wàá tí ó wà ní orí rẹ̀,+ àti ìwo mìíràn+ tí ó jáde wá, tí mẹ́ta sì ṣubú níwájú rẹ̀,+ àní ìwo náà tí ó ní ojú àti ẹnu tí ń sọ àwọn nǹkan kàbìtìkàbìtì,+ tí ìrísí rẹ̀ sì tóbi ju ti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ. 21  “Mo ń wò ó nígbà tí ìwo yẹn gan-an bá àwọn ẹni mímọ́ ja ogun, ó sì ń borí wọn,+ 22  títí Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé+ fi dé, a sì ṣèdájọ́ àre fún àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ,+ àkókò kan pàtó sì dé tí àwọn ẹni mímọ́ gba ìjọba.+ 23  “Èyí ni ohun tí ó sọ, ‘Ní ti ẹranko kẹrin, ìjọba kẹrin yóò wá wà ní ilẹ̀ ayé, tí yóò yàtọ̀ sí gbogbo ìjọba yòókù; yóò sì jẹ gbogbo ilẹ̀ ayé ní àjẹrun, yóò sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, yóò sì fọ́ ọ túútúú.+ 24  Àti ní ti ìwo mẹ́wàá náà, láti inú ìjọba yẹn, ọba mẹ́wàá ni yóò dìde;+ òmíràn yóò sì tún dìde lẹ́yìn wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì yàtọ̀ sí àwọn ti àkọ́kọ́,+ yóò sì tẹ́ ọba mẹ́ta lógo.+ 25  Àní yóò sì sọ ọ̀rọ̀ lòdì sí Ẹni Gíga Jù Lọ,+ yóò sì máa bá a lọ ní fífòòró àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ.+ Yóò sì pète-pèrò láti yí àwọn àkókò+ àti òfin+ padà, a ó sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún àkókò kan, àti àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò.+ 26  Kóòtù sì ń bá a lọ láti jókòó,+ wọ́n sì gba agbára ìṣàkóso rẹ̀ kúrò níkẹyìn, kí a bàa lè pa á rẹ́ ráúráú, kí a sì pa á run pátápátá.+ 27  “‘Àti ìjọba àti agbára ìṣàkóso àti ìtóbilọ́lá àwọn ìjọba lábẹ́ gbogbo ọ̀run ni a sì fi fún àwọn tí í ṣe ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ.+ Ìjọba wọ́n jẹ́ ìjọba tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ àní àwọn ni gbogbo agbára ìṣàkóso yóò máa sìn, tí wọn yóò sì ṣègbọràn sí.’+ 28  “Títí dé orí kókó yìí ni òpin ọ̀ràn náà. Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, ìrònú mi kó jìnnìjìnnì bá mi gidigidi, tí àwọ̀ ara mi fi yí padà nínú mi; ṣùgbọ́n ọ̀ràn náà ni mo pa mọ́ sínú ọkàn-àyà mi.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé