Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Dáníẹ́lì 6:1-28

6  Ó dára lójú Dáríúsì, ó sì fi ọgọ́fà baálẹ̀ jẹ lórí ìjọba náà, tí yóò wà lórí gbogbo ìjọba náà;+  wọ́n sì ní àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga mẹ́ta lórí wọn, lára àwọn tí Dáníẹ́lì jẹ́ ọ̀kan,+ kí àwọn baálẹ̀ yìí+ lè máa fún wọn ní ìròyìn nígbà gbogbo, kí ọba má bàa di ẹni tí ó pàdánù.+  Nígbà náà ni Dáníẹ́lì yìí ń fi ara rẹ̀ hàn yàtọ̀+ ṣáá lórí àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀, níwọ̀n bí ẹ̀mí àrà ọ̀tọ̀ kan ti wà nínú rẹ̀;+ ọba sì ń pète-pèrò láti gbé e lékè lórí gbogbo ìjọba náà.  Ní àkókò yẹn, àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ ń wá ọ̀nà láti rí ohun àfiṣe-bojúbojú lòdì sí Dáníẹ́lì nípa ìjọba náà;+ ṣùgbọ́n wọn kò lè rí ohun àfiṣe-bojúbojú tàbí ohun ìsọnidìbàjẹ́ kankan rárá, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tí kò sì sí ìwà àìnáání tàbí ohun ìsọnidìbàjẹ́ kankan rárá tí a rí nínú rẹ̀.+  Nítorí náà, àwọn abarapá ọkùnrin náà sọ pé: “A kò lè rí ohun àfiṣe-bojúbojú kankan rárá nínú Dáníẹ́lì yìí, bí kò ṣe pé a bá rí i lòdì sí i nínú òfin Ọlọ́run rẹ̀.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ yìí, bí àgbájọ ènìyàn kan, wọlé tọ ọba lọ,+ ohun tí wọ́n sì sọ fún un nìyí: “Kí Dáríúsì Ọba kí ó pẹ́ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  Gbogbo àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga nínú ìjọba náà, àwọn aṣíwájú àti baálẹ̀, àwọn olóyè onípò gíga àti àwọn gómìnà, ti gbìmọ̀ pọ̀ láti fìdí ìlànà àgbékalẹ̀ ọba múlẹ̀+ àti láti mú kí àṣẹ ìkàléèwọ̀ kan rinlẹ̀, pé ẹnì yòówù tí ó bá ṣe ìtọrọ lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí ènìyàn èyíkéyìí láàárín ọgbọ̀n ọjọ́ bí kò ṣe lọ́wọ́ rẹ, ọba ni kí a sọ sínú ihò kìnnìún.+  Wàyí o, ọba, fìdí ìlànà àgbékalẹ̀ náà múlẹ̀, kí o sì fọwọ́ sí ìwé náà,+ nítorí kí a má bàa yí i padà, gẹ́gẹ́ bí òfin àwọn ará Mídíà àti àwọn ará Páṣíà,+ èyí tí a kì í wọ́gi lé.”+  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Dáríúsì Ọba fúnra rẹ̀ fọwọ́ sí ìwé náà àti àṣẹ ìkàléèwọ̀ náà.+ 10  Ṣùgbọ́n gbàrà tí Dáníẹ́lì mọ̀ pé a ti fọwọ́ sí ìwé náà, ó wọnú ilé rẹ̀ lọ, fèrèsé ìyẹ̀wù òrùlé rẹ̀ wà ní ṣíṣí fún un síhà Jerúsálẹ́mù,+ àní ní ìgbà mẹ́ta lójúmọ́,+ ó ń kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó ń gbàdúrà,+ ó sì ń bu ìyìn níwájú Ọlọ́run rẹ̀,+ gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe déédéé ṣáájú èyí.+ 11  Ní àkókò yẹn, àwọn abarapá ọkùnrin náà rọ́ gìrìgìrì wọlé, wọ́n sì rí i tí Dáníẹ́lì ń ṣe ìtọrọ, tí ó sì ń fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere níwájú Ọlọ́run rẹ̀.+ 12  Nígbà náà ni wọ́n wá, wọ́n sì sọ níwájú ọba nípa àṣẹ ìkàléèwọ̀ ọba pé: “Àṣẹ ìkàléèwọ̀ kan kò ha wà tí o fọwọ́ sí pé ènìyàn èyíkéyìí tí ó bá ṣe ìtọrọ lọ́dọ̀ ọlọ́run tàbí ènìyàn èyíkéyìí láàárín ọgbọ̀n ọjọ́ bí kò ṣe lọ́dọ̀ rẹ, ọba ni kí a sọ sínú ihò kìnnìún?”+ Ọba dáhùn, pé: “Ọ̀ràn náà fìdí múlẹ̀ dáadáa gẹ́gẹ́ bí òfin àwọn ará Mídíà àti àwọn ará Páṣíà, èyí tí a kì í wọ́gi lé.”+ 13  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí níwájú ọba pé: “Dáníẹ́lì,+ tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìgbèkùn Júdà,+ kò fi ọ́ pè rárá, ọba, bẹ́ẹ̀ sì ni àṣẹ ìkàléèwọ̀ tí o fọwọ́ sí, ṣùgbọ́n ìgbà mẹ́ta lójúmọ́ ni ó ń ṣe ìtọrọ.”+ 14  Nítorí náà, gbàrà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, kò dùn mọ́ ọn nínú rárá,+ ó sì gbé èrò inú rẹ̀ síhà ọ̀dọ̀ Dáníẹ́lì láti gbà á sílẹ̀;+ àti títí wíwọ̀ oòrùn, ó ń bá a nìṣó nínú ìlàkàkà láti dá a nídè. 15  Níkẹyìn, àwọn abarapá ọkùnrin náà wọlé bí ọ̀pọ̀ ènìyàn tọ ọba lọ, wọ́n sì wí fún ọba pé: “Ọba, ṣàkíyèsí pé òfin àwọn ará Mídíà àti àwọn ará Páṣíà ni pé àṣẹ ìkàléèwọ̀+ tàbí ìlànà àgbékalẹ̀ èyíkéyìí tí ọba bá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ yí padà.”+ 16  Nítorí náà, ọba fúnra rẹ̀ pàṣẹ, wọ́n sì mú Dáníẹ́lì wá, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò kìnnìún.+ Ọba dáhùn, ó sì wí fún Dáníẹ́lì pé: “Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn láìyẹsẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò gbà ọ́ sílẹ̀.”+ 17  Wọ́n sì gbé òkúta kan wá, wọ́n sì yí i dí ẹnu ihò náà, ọba sì fi èdìdì òrùka àmì-àṣẹ rẹ̀ àti ti òrùka àmì-àṣẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn sé e, kí a má bàa yí nǹkan kan padà nínú ọ̀ràn Dáníẹ́lì.+ 18  Ní àkókò yẹn, ọba lọ sí ààfin rẹ̀, ó sì gbààwẹ̀ ní òru náà,+ wọn kò sì mú ohun èlò ìkọrin kankan wá síwájú rẹ̀, oorun rẹ̀ gan-an sì dá lójú rẹ̀.+ 19  Níkẹyìn, nígbà tí ọ̀yẹ̀ là, ọba fúnra rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dìde ní ojúmọmọ, ní kánjúkánjú, ó lọ sí ihò kìnnìún náà ní tààràtà. 20  Bí ó sì ti sún mọ́ ihò náà, ó fi ohùn ìbànújẹ́ ké jáde àní sí Dáníẹ́lì. Ọba sọ̀rọ̀, ó sì wí fún Dáníẹ́lì pé: “Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn láìyẹsẹ̀+ ha lè gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kìnnìún bí?”+ 21  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáníẹ́lì fúnra rẹ̀ sọ fún ọba, pé: “Kí ọba kí ó pẹ́ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin. 22  Ọlọ́run mi+ rán áńgẹ́lì rẹ̀,+ ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà,+ wọn kò sì run mí, níwọ̀n bí a ti rí mi ní ọlọ́wọ́ mímọ́ níwájú rẹ̀;+ àti níwájú rẹ pẹ̀lú, ọba, èmi kò gbé ìgbésẹ̀ aṣenilọ́ṣẹ́ kankan.”+ 23  Nígbà náà ni ọba yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,+ ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n gbé Dáníẹ́lì jáde kúrò nínú ihò náà. A sì gbé Dáníẹ́lì jáde kúrò nínú ihò náà, kò sì sí ọṣẹ́ kankan rárá lára rẹ̀, nítorí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀.+ 24  Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú àwọn abarapá ọkùnrin tí ó fẹ̀sùn kan Dáníẹ́lì+ wá, wọ́n sì sọ wọ́n sínú ihò kìnnìún,+ àwọn ọmọ wọn àti àwọn aya wọn;+ wọn kò sì tíì dé ìsàlẹ̀ ihò náà kí àwọn kìnnìún náà tó kápá wọn, gbogbo egungun wọn ni wọ́n sì fọ́ túútúú.+ 25  Nígbà náà ni Dáríúsì Ọba fúnra rẹ̀ kọ̀wé sí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti ahọ́n tí ń gbé gbogbo ilẹ̀ ayé pé:+ “Kí àlàáfíà yín di púpọ̀ gidigidi!+ 26  Láti ọ̀dọ̀ mi ni àṣẹ ìtọ́ni kan ti jáde+ pé, ní gbogbo àgbègbè ìṣàkóso ìjọba mi, kí àwọn ènìyàn máa wárìrì, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run Dáníẹ́lì.+ Nítorí pé òun ni Ọlọ́run alààyè àti Ẹni tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ ìjọba rẹ̀+ jẹ́ ọ̀kan tí a kì yóò run,+ àgbègbè ìṣàkóso rẹ̀ sì wà títí láé.+ 27  Ó ń gbani sílẹ̀, ó ń dáni nídè,+ ó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu ní ọ̀run+ àti lórí ilẹ̀ ayé,+ nítorí ó ti gba Dáníẹ́lì sílẹ̀ kúrò ní àtẹ́sẹ̀ àwọn kìnnìún.” 28  Ní ti Dáníẹ́lì yìí, ó ń ní aásìkí nínú ìjọba Dáríúsì+ àti nínú ìjọba Kírúsì ará Páṣíà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé